Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORÍ 48

Ayé Tuntun Ọlọ́run, Ayé Àlàáfíà—Ìwọ Lè Wà Níbẹ̀

Ayé Tuntun Ọlọ́run, Ayé Àlàáfíà—Ìwọ Lè Wà Níbẹ̀

ỌLỌ́RUN dá Ádámù àti Éfà sínú ọgbà Édẹ́nì. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣàìgbọràn tí wọ́n sì kú, Ọlọ́run mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn ọmọ wọn, títí kan àwa lónìí, láti lè wà láàyè nínú Párádísè. Bíbélì ṣèlérí pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa [wà láàyè] títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa “ọ̀run tuntun” àti “ilẹ̀ ayé tuntun.” (Aísáyà 65:17; 2 Pétérù 3:13) Ìjọba àwọn èèyàn ló para pọ̀ jẹ́ “ọ̀run” tó wà nísinsìnyí, ṣùgbọ́n, Jésù Kristi àti àwọn tí yóò bá a ṣàkóso ní ọ̀run ni yóò para pọ̀ jẹ́ “ọ̀run tuntun.” Nígbà tí ọ̀run tuntun yìí, tí í ṣe ìjọba òdodo, ìjọba àlàáfíà, látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bá ń ṣàkóso gbogbo ilẹ̀ ayé nǹkan á mà dára gan-an o!

Kí wá ni “ilẹ̀ ayé tuntun” náà?— Ilẹ̀ ayé tuntun yìí yóò jẹ́ àwọn èèyàn rere tó fẹ́ràn Jèhófà. Ṣé o rí i, tí Bíbélì bá mẹ́nu kan “ilẹ̀ ayé” nígbà mìíràn, àwọn èèyàn tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé ló túmọ̀ sí, kì í ṣe erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 11:1; Sáàmù 66:4; 96:1) Nítorí náà, orí ilẹ̀ ayé wa níbí ni àwọn èèyàn tó para pọ̀ jẹ́ ayé tuntun yóò máa gbé.

Ayé ti àwọn èèyàn búburú ìsinsìnyí kò ní sí mọ́ ní ìgbà yẹn. Rántí pé Ìkún Omi ìgbà ayé Nóà pa ayé àwọn èèyàn búburú kan run. Gẹ́gẹ́ bí a sì ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, Amágẹ́dọ́nì yóò pa ayé búburú ìsinsìnyí run pẹ̀lú. Nísinsìnyí, jẹ́ kí a wo bí ayé yóò ṣe rí nínú ayé tuntun Ọlọ́run lẹ́yìn Amágẹ́dọ́nì.

Ǹjẹ́ o fẹ́ wà láàyè títí láé nínú Párádísè, ayé tuntun Ọlọ́run, ayé àlàáfíà?— Kò sí dókítà kankan tó lè mú kí á wà láàyè títí láé. Kò  sí oògùn kankan tí a lè lò tó lè dènà ikú. Ohun kan ṣoṣo tí a lè ṣe tí a fi lè wà láàyè títí láé ni pé kí á sún mọ́ Ọlọ́run. Olùkọ́ Ńlá náà sì kọ́ wa bí a ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run.

Jẹ́ kí á gbé Bíbélì wa kí á ṣí i sí Jòhánù orí kẹtàdínlógún [17] ẹsẹ ìkẹta. A rí ọ̀rọ̀ Olùkọ́ Ńlá náà níbẹ̀, pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”

Nítorí náà, kí ni Jésù sọ pé a ní láti ṣe kí á lè wà láàyè títí láé?— Àkọ́kọ́, a ní láti gba ìmọ̀ Jèhófà, Bàbá wa ọ̀run sínú, àti ìmọ̀ Ọmọ rẹ̀ tó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ fún wa. Èyí túmọ̀ sí pé a ní láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìwé yìí, Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà, ń ràn wá lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ṣùgbọ́n báwo ni kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà yóò ṣe mú kí á wà láàyè títí láé?— Ṣé o rí i, gẹ́gẹ́ bí a ṣe nílò oúnjẹ lójoojúmọ́ náà ni a ṣe gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà lójoojúmọ́. Bíbélì sọ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.’—Mátíù 4:4.

A tún ní láti gba ìmọ̀ nípa Jésù Kristi sínú pẹ̀lú nítorí pé ńṣe ni Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ wá kí ó wá mú ẹ̀ṣẹ̀ wa kúrò. Bíbélì sọ pé: “Kò sí ìgbàlà kankan nínú ẹnikẹ́ni mìíràn.” Bíbélì sì tún sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Ìṣe 4:12; Jòhánù 3:36) Wàyí o, kí ni ó túmọ̀ sì láti “lo ìgbàgbọ́” nínú Jésù?— Ó túmọ̀ sí pé kí á gba Jésù gbọ́ tọkàntọkàn, kí a sì mọ̀ pé láìsí i, kò lè ṣeé ṣe fún wa láti wà láàyè títí láé. Ǹjẹ́ a gba ìyẹn gbọ́?— Bí a bá gbà á gbọ́, a óò máa bá a lọ láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá náà lójoojúmọ́, a óò sì máa ṣe ohun tó sọ fún wa pé kí á ṣe.

Ọ̀nà dáadáa kan tí o lè gbà máa kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá náà ni pé kí o máa ka ìwé yìí léraléra, kí o máa wo gbogbo àwọn àwòrán  inú rẹ̀ kí o sì máa ronú lé wọn lórí. Máa gbìyànjú láti dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà níbi àwọn àwòrán náà. Bákan náà, kí ìwọ àti ìyá tàbí bàbá rẹ jùmọ̀ ka ìwé yìí pọ̀. Bí kò bá sí àwọn òbí rẹ níbi tí o wà, kí ìwọ àti àgbàlagbà mìíràn jùmọ̀ kà á, kí ìwọ àti àwọn ọmọdé mìíràn sì tún jùmọ̀ máa kà á pẹ̀lú. Ǹjẹ́ kò ní dára gan-an bí o bá lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá náà, kí wọ́n sì mọ ohun tí wọ́n lè ṣe láti wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun Ọlọ́run?—

Bíbélì sọ fún wa pé: “Ayé ń kọjá lọ.” Ṣùgbọ́n Bíbélì tún ṣàlàyé ohun tí a lè ṣe láti wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:17) Nítorí náà, báwo ni a ṣe lè wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun Ọlọ́run?— A lè wà láàyè níbẹ̀ tí a bá ń gba ìmọ̀ Jèhófà àti Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n sínú. Ṣùgbọ́n a tún ní láti máa fi ohun tí a bá kọ́ sílò pẹ̀lú. Ǹjẹ́ kí ẹ̀kọ́ tí o kọ́ nínú ìwé yìí ràn ọ́ lọ́wọ́ láti máa gba ìmọ̀ Jèhófà sínú àti láti máa fi ohun tí o kọ́ sílò.