Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà

 ORÍ 43

Àwọn Wo Ni Arákùnrin àti Arábìnrin Wa?

Àwọn Wo Ni Arákùnrin àti Arábìnrin Wa?

NÍGBÀ kan, Olùkọ́ Ńlá náà béèrè ìbéèrè kan tó yani lẹ́nu. Ìbéèrè náà ni: “Ta ni ìyá mi, ta sì ni àwọn arákùnrin mi?” (Mátíù 12:48) Ǹjẹ́ o lè dáhùn ìbéèrè yẹn?— Ó ṣeé ṣe kí o mọ̀ pé Màríà ni orúkọ ìyá Jésù. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ o mọ orúkọ àwọn arákùnrin rẹ̀?— Ǹjẹ́ ó ní àwọn arábìnrin pẹ̀lú?—

Bíbélì sọ pé orúkọ àwọn arákùnrin Jésù ni “Jákọ́bù àti Jósẹ́fù àti Símónì àti Júdásì.” Jésù sì ní àwọn arábìnrin tó wà láàyè nígbà tó ń wàásù. Níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ àkọ́bí, àbúrò rẹ̀ ni gbogbo àwọn wọ̀nyí jẹ́.—Mátíù 13:55, 56; Lúùkù 1:34, 35.

Ṣé àwọn arákùnrin Jésù jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pẹ̀lú?— Bíbélì sọ pé wọn ò kọ́kọ́ “lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.” (Jòhánù 7:5) Àmọ́ nígbà tó yá, Jákọ́bù àti Júdásì (tí wọ́n tún ń pè ní Júúdà) di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n tiẹ̀ tún kọ lára ìwé inú Bíbélì. Ǹjẹ́ o mọ àwọn ìwé tí wọ́n kọ?— Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn ni ìwé Jákọ́bù àti Júúdà.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ orúkọ àwọn àbúrò obìnrin tí Jésù ní, a mọ̀ pé ó ní tó méjì, ó kéré tán. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kí wọ́n jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ǹjẹ́ àwọn àbúrò rẹ̀ obìnrin wọ̀nyí di ọmọlẹ́yìn rẹ̀?— Bíbélì kò sọ, nítorí náà, a ò mọ̀. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ o mọ ìdí tí Jésù fi béèrè pé, “Ta ni ìyá mi, ta sì ni àwọn arákùnrin mi?”— Jẹ́ ká wò ó ná.

Jésù ń kọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ ni ẹnì kan já lu ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó sì sọ pé: ‘Ìyá rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ dúró lóde, wọ́n fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀.’ Jésù wá lo àǹfààní ìyẹn láti fi kọ́ni ní ẹ̀kọ́ pàtàkì kan, ó  béèrè ìbéèrè yíyanilẹ́nu tí a sọ ní ìṣáájú, pé: “Ta ni ìyá mi, ta sì ni àwọn arákùnrin mi?” Ó wá nawọ́ sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ó sì dáhùn ìbéèrè náà, pé: “Wò ó! Ìyá mi àti àwọn arákùnrin mi!”

Jésù wá ṣàlàyé ohun tó ní lọ́kàn, ó sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run, òun kan náà ni arákùnrin, àti arábìnrin, àti ìyá mi.” (Mátíù 12:47-50) Èyí fi hàn bí ọkàn Jésù ṣe fà mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó. Ẹ̀kọ́ tí Jésù ń kọ́ wa ni pé òun ka àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun sí arákùnrin àti arábìnrin àti ìyá òun gan-an.

Àwọn wo ni Jésù sọ pé wọ́n jẹ́ arákùnrin àti arábìnrin òun?

Ní ìgbà yẹn, àwọn arákùnrin Jésù, ìyẹn Jákọ́bù, Jósẹ́fù, Símónì àti Júdásì, kò gbà gbọ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù jẹ́. Ó ṣeé ṣe pé wọn ò tíì gbà pé òótọ́ ni ohun tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ fún ìyá wọn. (Lúùkù 1:30-33) Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti máa hùwà tí kò dára sí Jésù. Ẹnikẹ́ni tó bá ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀, kì í ṣe arákùnrin tàbí arábìnrin tòótọ́. Ǹjẹ́ o mọ ẹnikẹ́ni tó  ń hùwà tí kò dára sí arákùnrin tàbí arákùnrin rẹ̀, ìyẹn ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ̀?—

Bíbélì sọ ìtàn Ísọ̀ àti Jékọ́bù fún wa àti bí Ísọ̀ ṣe bínú débi pé ó sọ pé: “Èmi yóò pa Jékọ́bù arákùnrin mi.” Ẹ̀rù ba Rèbékà ìyá wọn débi pé ó ní kí Jékọ́bù lọ máa gbé ní ìlú tó jìnnà réré, tí Ísọ̀ kò fi lè pa á. (Jẹ́nẹ́sísì 27:41-46) Àmọ́ ṣá, ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ìwà Ísọ̀ yí padà, ó sì gbá Jékọ́bù mọ́ra, ó fẹnu kò ó lẹ́nu.—Jẹ́nẹ́sísì 33:4.

Nígbà tó yá, Jékọ́bù ní ọmọ méjìlá. Ṣùgbọ́n àwọn tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n nínú àwọn ọmọ Jékọ́bù kò fẹ́ràn Jósẹ́fù àbúrò wọn. Wọ́n ń ṣe ìlara rẹ̀ nítorí pé òun ni bàbá wọ́n fẹ́ràn jù lọ. Nítorí náà, wọ́n tà á fún àwọn olówò ẹrú tó ń kọjá lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì. Wọ́n wá sọ fún bàbá wọn pé ẹranko búburú ti pa Jósẹ́fù jẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 37:23-36) Ǹjẹ́ ìyẹn kò burú jáì?—

Nígbà tó yá, àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ronú pìwà dà wọ́n sì kẹ́dùn ohun tí wọ́n ṣe. Nítorí náà, Jósẹ́fù dárí jì wọ́n. Ǹjẹ́ o rí bí ìṣe Jósẹ́fù àti ti Jésù ṣe jọra?— Àwọn àpọ́sítélì Jésù sá lọ  nígbà tí Jésù wà nínú ìṣòro, kódà Pétérù tún sọ pé òun ò mọ Jésù rí rárá. Síbẹ̀, Jésù dárí ji gbogbo wọn gẹ́gẹ́ bí Jósẹ́fù ti ṣe.

Ẹ̀kọ́ wo ni ohun tí Kéènì fi ṣe Ébẹ́lì kọ́ wa?

Tẹ̀gbọ́n tàbúrò kan náà tún wà tí wọ́n ń jẹ́ Kéènì àti Ébẹ́lì. A lè kọ́ ẹ̀kọ́ lára àwọn náà. Ọlọ́run rí ọkàn Kéènì pé kò fẹ́ràn àbúrò rẹ̀ dénú. Nítorí náà, Ọlọ́run sọ fún Kéènì pé kí ó yí ìwà rẹ̀ padà. Ká ní pé Kéènì fẹ́ràn Ọlọ́run ní tòótọ́ ni, ì bá ṣe bí Ọlọ́run ṣe sọ fún un. Ṣùgbọ́n kò fẹ́ràn Ọlọ́run. Lọ́jọ́ kan, Kéènì sọ fún Ébẹ́lì pé: “Jẹ́ kí a kọjá lọ sínú pápá.” Ébẹ́lì sì tẹ̀ lé Kéènì lọ. Nígbà tí wọ́n jọ nìkan wà nínú pápá, Kéènì la nǹkan mọ́ àbúrò rẹ̀ tagbára-tagbára, ó sì pa á.—Jẹ́nẹ́sísì 4:2-8.

Bíbélì sọ fún wa pé ẹ̀kọ́ pàtàkì kan wà tó yẹ kí ìtàn yìí kọ́ wa. Ṣé o mọ ẹ̀kọ́ náà?— Òun rèé: ‘Èyí ni ọ̀rọ̀ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, pé: A ní láti ní ìfẹ́ ara wa; kí á má ṣe dà bí Kéènì, ẹni tí ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà.’ Nítorí náà, àwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò, tàbí arákùnrin àti arábìnrin, ní láti ní ìfẹ́ ara wọn. Wọn kò gbọ́dọ̀ dà bí Kéènì.—1 Jòhánù 3:11, 12.

Kí nìdí tí kò fi dára kí á dà bí Kéènì?— Torí pé Bíbélì sọ pé ó ‘wá láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà,’ Sátánì Èṣù. Níwọ̀n bí Kéènì ti hùwà bíi ti Èṣù, ńṣe ló dà bíi pé Èṣù gan-an ni bàbá rẹ̀.

Ǹjẹ́ o rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀gbọ́n àti àbúrò rẹ?— Bí o kò bá nífẹ̀ẹ́ wọn, a jẹ́ pé ò ń ṣe bí àwọn ọmọ ta ni o?— Bí àwọn ọmọ Èṣù. Ìwọ kò ní fẹ́ jẹ́ ọmọ Èṣù, àbí?— Nítorí náà, báwo ni o ṣe lè fi hàn pé o fẹ́ jẹ́ ọmọ Ọlọ́run?— Nípa níní ìfẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ dénúdénú ni.

Ṣùgbọ́n kí ni ìfẹ́?— Ìfẹ́ jẹ́ ẹ̀mí rere tó jinlẹ̀ nínú wa, tó máa ń mú kí a fẹ́ ṣoore fún àwọn èèyàn. À ń fi hàn pé a ní ìfẹ́ àwọn èèyàn nígbà tí inú wa bá dùn sí wọn, àti nígbà tí a bá ń ṣoore fún wọn. Àwọn wo sì ni àwọn arákùnrin wa àti arábìnrin wa tó yẹ  kí á ní ìfẹ́ wọn?— Rántí, Jésù kọ́ni pé àwọn ni àwọn Kristẹni tó para pọ̀ jẹ́ ìdílé ńlá kan ṣoṣo.

Báwo ni o ṣe lè fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ?

Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa?— Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin [tàbí arábìnrin] rẹ̀, tí òun rí, kò lè máa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí kò rí.” (1 Jòhánù 4:20) Nítorí náà, a ò kàn lè nífẹ̀ẹ́ àwọn díẹ̀ péré nínú ìdílé Kristẹni. A gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ gbogbo wọn pátá. Jésù sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Ǹjẹ́ o nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn arákùnrin àti arábìnrin?— Rántí, tí o kò bá nífẹ̀ẹ́ wọn, o kò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ní tòótọ́ nìyẹn.

Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ní tòótọ́?— Ṣé o rí i, tí a bá nífẹ̀ẹ́ wọn, a ò ní máa sá fún wọn nítorí pé a ò fẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀. A óò jẹ́ ọ̀rẹ́ gbogbo wọn. A óò máa ṣoore fún wọn nígbà gbogbo, a ó sì máa ṣàjọpín ohun tí a bá ní pẹ̀lú wọn. Bí wọ́n bá sì wá ní ìṣòro, a ó ṣèrànwọ́ fún wọn nítorí pé ìdílé ńlá kan ṣoṣo ni wá.

Nígbà tí a bá nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, kí ni èyí fi hàn?— Ó fi hàn pé a jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, Olùkọ́ Ńlá náà. Àbí ohun tí a sì fẹ́ jẹ́ kọ́ nìyẹn?—

A tún sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe lè máa fi ìfẹ́ hàn sí àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nínú Gálátíà 6:10 àti 1 Jòhánù 4:8, 21. O ò ṣe ṣí Bíbélì rẹ kí o ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyẹn?

Mọ Púpọ̀ Sí I

KỌ́ ỌMỌ RẸ

Wọ́n Kọ Ìwé Nípa Jésù

Kọ́ nípa àwọn mẹ́jọ tó kọ Bíbélì lára àwọn tó jọ gbé ayé pẹ̀lú Jésù, tí wọ́n sì kọ̀wé nípa ìgbésí ayé rẹ̀.