Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORÍ 13

Àwọn Tó Di Ọmọ Ẹ̀yìn Jésù

Àwọn Tó Di Ọmọ Ẹ̀yìn Jésù

Ta lẹni yìí, báwo ló sì ṣe di ọmọ ẹ̀yìn Jésù?

TA NI ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ṣe dáadáa jù lọ tó tíì gbé orí ilẹ̀ ayé rí?— O gbà á, Jésù Kristi ni. Ǹjẹ́ o rò pé a lè dà bíi Jésù?— Bíbélì sọ fún wa pé ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa kí á lè máa tẹ̀ lé e. Ó sì sọ pé kí á wá di ọmọ ẹ̀yìn òun.

Ǹjẹ́ o mọ ohun tí a ó máa ṣe tí a bá jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù?— Ohun tí a ó máa ṣe pọ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n ìyẹn nìkan kọ́ la ó máa ṣe o. A tún ní láti gba ohun tó sọ gbọ́ tọkàntọkàn. Bí a bá sì ti gbà á gbọ́, a ó máa ṣe ohun tó sọ pé ká máa ṣe.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sọ pé àwọn gba Jésù gbọ́. Ǹjẹ́ o rò pé gbogbo wọn ló jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní tòótọ́?— Rárá o, àwọn tó pọ̀ jù lọ nínú wọn ni kì í ṣe ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Wọ́n lè máa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì o. Ṣùgbọ́n púpọ̀ nínú wọn ni kò tíì wá àyè láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Jésù fi kọ́ni. Ní tòótọ́, kìkì àwọn tó bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù ni ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀.

Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù nígbà tó jẹ́ ènìyàn lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀kan nínú àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù ni Fílípì. Fílípì lọ sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ Nàtáníẹ́lì (tó tún ń jẹ́ Bátólómíù), ẹni tí o rí tó jókòó sídìí igi nínú àwòrán yìí. Nígbà tí Nàtáníẹ́lì dé ọ̀dọ̀ Jésù, Jésù sọ pé: ‘Wò ó, olóòótọ́ gidi ni ẹni tó dé yìí o, ọmọ Ísírẹ́lì àtàtà ni.’ Èyí ya Nàtáníẹ́lì lẹ́nu, ó wá béèrè pé: ‘Báwo ni o ṣe mọ̀ mí?’

Àwọn wo ni Jésù ń pè níbí kí wọ́n wá di ọmọ ẹ̀yìn òun??

Jésù sọ pé: ‘Kí Fílípì tó pè ọ́, nígbà tí ìwọ wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ ni mo ti rí ọ.’ Ó ya Nàtáníẹ́lì lẹ́nu pé Jésù  mọ ibi tí òun wà gẹ́lẹ́, nítorí náà Nàtáníẹ́lì sọ pé: “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run, ìwọ ni Ọba Ísírẹ́lì.”—Jòhánù 1:49.

Júdásì Ísíkáríótù, Júdásì (tí wọ́n tún ń pè ní Tádéọ́sì), Símónì

Àwọn kan ti kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọjọ́ kan sẹ́yìn kí Fílípì àti Nàtáníẹ́lì tó di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Àwọn ni Áńdérù àti Pétérù ẹ̀gbọ́n rẹ̀, àti Jòhánù pẹ̀lú, ó ṣeé ṣe kí Jákọ́bù ẹ̀gbọ́n Jòhánù náà wà lára wọn. (Jòhánù 1:35-51) Àmọ́ àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí kàn dúró ti Jésù fún ìgbà díẹ̀ ni, wọ́n sì tún padà síbi iṣẹ́ apẹja tí wọ́n ń ṣe. Ṣùgbọ́n lọ́jọ́ kan, bí Jésù ṣe ń rìn ní etí Òkun Gálílì, ó rí Pétérù àti Áńdérù bí wọ́n ṣe ń da àwọ̀n wọn sínú òkun láti pa ẹja. Jésù wá pè wọ́n ó ní: “Ẹ máa tọ̀ mí lẹ́yìn.”

Jákọ́bù (ọmọ Álífíọ́sì), Tọ́másì, Mátíù

Bí Jésù ṣe rìn síwájú díẹ̀, ó rí Jákọ́bù àti Jòhánù. Wọ́n wà pẹ̀lú bàbá wọn nínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n ń tún àwọ̀n tí wọ́n fi ń pa ẹja ṣe. Jésù pè wọ́n, ó ní kí àwọn náà máa tẹ̀ lé òun. Tó bá jẹ́ pé ìwọ ni  Jésù pè bí ó ṣe pè wọ́n yìí, kí lo máa ṣe? Ǹjẹ́ wàá tẹ̀ lé e lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀?— Gbogbo wọn mọ Jésù dáadáa. Wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run ló rán an wá. Nítorí náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n fi iṣẹ́ apẹja tí wọ́n ń ṣe sílẹ̀ tí wọ́n sì tẹ̀ lé Jésù.—Mátíù 4:18-22.

Nàtáníẹ́lì, Fílípì, Jòhánù

Nígbà tí àwọn èèyàn wọ̀nyí di ọmọlẹ́yìn Jésù, ṣé ó wá túmọ̀ sí pé gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń ṣe ohun tó dára?— Rárá o. O lè rántí pé, nígbà kan, àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí tiẹ̀ ń bá ara wọn jiyàn nípa ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ láàárín wọn. Ṣùgbọ́n wọ́n fetí sílẹ̀ sí Jésù, wọ́n kì í ṣe agídí, wọ́n máa ń jáwọ́ nínú ìwà tí kò dára. Bí àwa náà kì í bá ṣe agídí, tí à ń jáwọ́ nínú ìwà tí kò dára, àwa náà lè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù.

Jákọ́bù (arákùnrin Jòhánù), Áńdérù, Pétérù

Onírúurú èèyàn ni Jésù pè kí wọ́n wá di ọmọ ẹ̀yìn òun. Nígbà kan, ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ kan tọ Jésù wá, ó sì bi í nípa bí èèyàn ṣe lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. Nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin ọlọ́rọ̀ náà sọ pé òun ti ń pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́ látìgbà èwe òun wá, Jésù sọ fún un pé: “Wá di ọmọlẹ́yìn mi.” Ǹjẹ́ o mọ ohun tó ṣẹlẹ̀?—

Nígbà tí ọkùnrin náà gbọ́ pé jíjẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe pàtàkì ju pé kéèyàn jẹ́ ọlọ́rọ̀ lọ, inú rẹ̀ kò dùn rárá. Nítorí náà kò di ọmọ ẹ̀yìn Jésù, nítorí pé ó fẹ́ràn owó rẹ̀ ju bí ó ṣe fẹ́ràn Ọlọ́run lọ.—Lúùkù 18:18-25.

Jésù wàásù fún ohun tó tó ọdún kan àti ààbọ̀ kó tó wá yan àwọn méjìlá nínú ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó fi wọ́n ṣe àpọ́sítélì. Àwọn àpọ́sítélì ni àwọn èèyàn tí Jésù rán pé kí wọ́n lọ ṣe iṣẹ́ pàtàkì kan. Ǹjẹ́ o mọ orúkọ wọn?— Jẹ́ ká gbìyànjú láti mọ orúkọ tí wọ́n ń jẹ́. Wo àwòrán wọn níhìn-ín, kí o sì wò ó bóyá wàá lè sọ orúkọ wọn. Lẹ́yìn náà, wá sọ orúkọ wọn lórí.

Ta ni àwọn obìnrin yìí tó ń ran Jésù lọ́wọ́ nígbà tó lọ wàásù?

Nígbà tó yá, ọ̀kan nínú àwọn àpọ́sítélì méjìlá náà di èèyàn burúkú. Orúkọ rẹ̀ ni Júdásì Ísíkáríótù. Lẹ́yìn náà, wọ́n yan ọmọ ẹ̀yìn  mìíràn láti di àpọ́sítélì. Ǹjẹ́ o mọ orúkọ rẹ̀?— Mátíásì ni. Lẹ́yìn ìyẹn, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà náà di àpọ́sítélì, ṣùgbọ́n wọn kì í ṣe ara àwọn tó jẹ́ àpọ́sítélì méjìlá o.—Ìṣe 1:23-26; 14:14.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe kà á ní Orí 1 nínú ìwé yìí, Jésù fẹ́ràn àwọn ọmọdé. Kí ló mú kó fẹ́ràn wọn?— Ó jẹ́ nítorí pé ó mọ̀ pé àwọn ọmọdé náà lè di ọmọ ẹ̀yìn. Àní àwọn ọmọdé tiẹ̀ lè sọ̀rọ̀ lọ́nà tí àwọn àgbàlagbà pàápàá yóò fi fetí sílẹ̀, tí wọn yóò sì fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i nípa Olùkọ́ Ńlá náà.

Ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin di ọmọ ẹ̀yìn Jésù pẹ̀lú. Àwọn kan lára wọn máa ń tẹ̀ lé e lọ sí àwọn ìlú mìíràn láti wàásù. Ara àwọn tó tẹ̀  lé e ni Màríà Magidalénì, Jòánà àti Sùsánà. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa bá a se oúnjẹ kí wọ́n sì máa bá a fọ aṣọ.—Lúùkù 8:1-3.

Ǹjẹ́ o fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù?— Rántí o, pé tá a bá kàn sọ ọ́ lẹ́nu pé a jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ìyẹn ò sọ wá di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rárá. A ní láti máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní gbogbo ibi tí a bá wà. Kì í ṣe ìgbà tí a bá lọ sí ìpàdé Kristẹni nìkan la ó máa hùwà rere. Ǹjẹ́ o lè sọ àwọn ibi tó ti ṣe pàtàkì pé ká máa hùwà rere nítorí pé a jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù?—

Bẹ́ẹ̀ ni, a gbọ́dọ̀ máa hùwà rere ní ilé wa. Ṣùgbọ́n ó tún yẹ kí o máa hùwà rere ní ilé ìwé pẹ̀lú. Ohun tó yẹ kí ìwọ àti èmi máa rántí ni pé, tí a bá fẹ́ jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní tòótọ́, a gbọ́dọ̀ máa hùwà rere bíi tirẹ̀ láti àárọ̀ títí di alẹ́, ká sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́ ní gbogbo ibi tá a bá wà.

Ibo ló ti ṣe pàtàkì pé ká máa hùwà gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Jésù?

Wàyí o, ẹ jùmọ̀ ka ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, nínú Mátíù 28:19, 20; Lúùkù 6:13-16; Jòhánù 8:31, 32; àti 1 Pétérù 2:21.