ỌMỌ wo lo rò pé ó mú inú Jèhófà dùn jù lọ lórí ilẹ̀ ayé yìí?— Jésù Ọmọ rẹ̀ ni. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Jésù ṣe tó mú inú Bàbá rẹ̀ ní ọ̀run dùn.

Àwọn ará ilé Jésù ń gbé ní ibì kan tó jẹ́ ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí Jerúsálẹ́mù níbi tí tẹ́ńpìlì ẹlẹ́wà tá a kọ́ fún ìjọsìn Jèhófà wà. Jésù pe tẹ́ńpìlì náà ní “ilé Baba mi.” Òun àti àwọn ará ilé rẹ̀ máa ń lọ síbẹ̀ lọ́dọọdún láti lọ ṣe àjọ Ìrékọjá.

Ní ọdún kan, nígbà tí Jésù jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá, àwọn ará ilé rẹ̀ ń padà lọ sílé láti ibi àjọ Ìrékọjá. Ìgbà tí wọ́n dúró níbì kan tí wọ́n máa sùn ní alẹ́ ni wọ́n tó rí i pé Jésù kò sí láàárín àwọn ìbátan àti ọ̀rẹ́ wọn. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Màríà àti Jósẹ́fù padà sí Jerúsálẹ́mù láti lọ wá Jésù. Ibo lo rò pé ó wà?—

Inú tẹ́ńpìlì ni wọ́n ti rí Jésù. Ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn olùkọ́ni ó sì ń bi wọ́n ní àwọn ìbéèrè. Bí àwọn pẹ̀lú bá sì bi í ní ìbéèrè, òun náà á fún wọn ní ìdáhùn. Ẹnu sì yà wọ́n sí ìdáhùn dáadáa tó ń fún wọn. Ṣé o wá rí ìdí tí inú Ọlọ́run fi dùn sí Ọmọ rẹ̀?—

Nígbà tí Màríà àti Jósẹ́fù rí Jésù níkẹyìn, ọkàn wọ́n balẹ̀. Ṣùgbọ́n Jésù ò tiẹ̀ dààmú rárá ní tiẹ̀. Ó mọ̀ pé tẹ́ńpìlì jẹ́ ibi tó dára láti wà. Nítorí náà ó bi wọ́n pé: “Ṣé ẹ kò mọ̀ pé èmi gbọ́dọ̀ wà nínú ilé Baba mi ni?” Ó mọ̀ pé ilé Ọlọ́run ni tẹ́ńpìlì jẹ́, ó sì dùn mọ́ ọn láti wà níbẹ̀.

Lẹ́yìn náà, Màríà àti Jósẹ́fù mú Jésù, ọmọ ọdún méjìlá, padà lọ sílé wọn ní Násárétì. Irú ìwà wo ni o rò pé Jésù ń hù sí àwọn òbí  rẹ̀?— Ó dára, Bíbélì sọ pé “ó sì ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́ wọn.” Kí ni o rò pé ìyẹn túmọ̀ sí?— Ó túmọ̀ sí pé ó ń ṣègbọràn sí wọn. Ó ń ṣe ohun tí àwọn òbí rẹ̀ bá ní kó ṣe, títí kan pé kí ó lọ máa fa omi látinú kànga wá sílé.—Lúùkù 2:41-52.

Nígbà tí Jésù wà ní ọmọdé, báwo ló ṣe mú inú Ọlọ́run dùn?

Nítorí náà, ronú nípa èyí: Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù, ó ṣègbọràn sí àwọn òbí rẹ̀ aláìpé. Ǹjẹ́ èyí mú inú Ọlọ́run dùn?— Dájúdájú ó mú inú rẹ̀ dùn o, nítorí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún àwọn ọmọdé pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín.” (Éfésù 6:1) Ìwọ pẹ̀lú yóò mú inú Ọlọ́run dùn bí o bá ṣègbọràn sí àwọn òbí rẹ gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe.

Ọ̀nà mìíràn tí o tún lè gbà mú inú Ọlọ́run dùn ni pé kí o máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fún àwọn èèyàn. Wàyí o, àwọn èèyàn kan lè sọ pé ìyẹn kì í ṣe ohun tó yẹ kí àwọn ọmọdé máa ṣe. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn èèyàn gbìyànjú láti pa àwọn ọmọdé lẹ́nu mọ́ pé kí wọ́n má sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, Jésù sọ pé: ‘Ṣé ẹ kò tíì kà á nínú Ìwé Mímọ́ rí ni pé, “Ọlọ́run yóò mú kí ìyìn máa jáde wá láti  ẹnu àwọn ọmọ kéékèèké”?’ (Mátíù 21:16) Nítorí náà, ó dájú pé tí a bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ látinú ọkàn wá, gbogbo wa ló lè máa sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà fún àwọn èèyàn, kí á sọ fún wọn bí ó ṣe jẹ́ Ọlọ́run ìyanu tó. Tí a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a óò máa mú inú Ọlọ́run dùn.

Ibo ni a ti lè kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run tí a óò máa sọ fún àwọn èèyàn?— A lè kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ látinú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa tí à ń ṣe nílé. Àmọ́, a óò kọ́ ẹ̀kọ́ tó pọ̀ jù lọ níbi tí àwọn èèyàn Ọlọ́run ti ń pàdé pọ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́. Ṣùgbọ́n báwo la ṣe lè mọ àwọn tó jẹ́ èèyàn rẹ̀?—

Ó dára, kí ni àwọn èèyàn máa ń ṣe níbi ìpàdé wọn? Ṣé ohun tó wà nínú Bíbélì ni wọ́n ń kọ́ni ní ti gidi? Ǹjẹ́ wọ́n máa ń kà á kí wọ́n sì jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Ọ̀nà tí a gbà ń fetí sí Ọlọ́run nìyẹn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?— Àti pé nínú àwọn ìpàdé Kristẹni, a óò retí pé kí á máa gbọ́ ohun tí Ọlọ́run sọ, àbí?— Ṣùgbọ́n tí àwọn èèyàn kan bá wá sọ pé kì í ṣe dandan ni pé kí á máa ṣe gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ pé ká ṣe ńkọ́? Ṣé ìwọ yóò gbà pé èèyàn Ọlọ́run ni irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀?—

Ohun kan tó tún yẹ kí o ronú lé lórí rèé. Bíbélì sọ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò jẹ́ “àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀.” (Ìṣe 15:14) Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run, a lè béèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn bóyá Jèhófà ni Ọlọ́run wọn. Bí wọ́n bá sọ pé rárá, a ó mọ̀ nígbà náà pé wọn kì í ṣe èèyàn Jèhófà. Àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò sì tún máa sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ẹlòmíràn. Wọn yóò sì fi hàn pé àwọn fẹ́ràn Ọlọ́run nípa pípa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.—1 Jòhánù 5:3.

Bí o bá mọ àwọn èèyàn tó ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí, àwọn ni kí o lọ dára pọ̀ mọ́ láti máa bá wọn ṣe ìjọsìn. Kí o fetí sílẹ̀ dáadáa ní àwọn ìpàdé yìí kí o sì dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n bá ń béèrè. Ohun tí Jésù ṣe nìyẹn nígbà tí ó wà ní ilé Ọlọ́run. Bí o bá ṣe nǹkan wọ̀nyí, ìwọ yóò mú inú Ọlọ́run dùn, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe.

 Ǹjẹ́ o lè sọ àwọn ọmọdé mìíràn tí Bíbélì mẹ́nu kàn pé ó mú inú Ọlọ́run dùn?— Tímótì jẹ́ àpẹẹrẹ dáadáa kan. Bàbá rẹ̀ kì í ṣe ẹni tó gba Jèhófà gbọ́. Ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ Yùníìsì gba Jèhófà gbọ́, ìyá rẹ̀ àgbà, Lọ́ìsì, sì gbà á gbọ́ pẹ̀lú. Tímótì fetí sí wọn, ó sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá Tímótì kì í ṣe onígbàgbọ́, kí ni Tímótì fẹ́ láti ṣe?

Nígbà tí Tímótì dàgbà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wá sí ìlú ibi tí ó ń gbé. Ó wá ṣàkíyèsí pé Tímótì ń fẹ́ láti sin Jèhófà gan-an. Nítorí náà, ó ní kí Tímótì bá òun lọ láti túbọ̀ sin Ọlọ́run dáadáa sí i. Ní gbogbo ibi tí wọ́n rìnrìn àjò lọ, wọ́n ń sọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ nípa Jésù fún àwọn èèyàn.—Ìṣe 16:1-5; 2 Tímótì 1:5; 3:14, 15.

Ṣùgbọ́n ṣé ọkùnrin nìkan ni àpẹẹrẹ àwọn ọmọdé tó wà nínú Bíbélì tí wọ́n mú inú Ọlọ́run dùn ni?— Rárá o. Wo àpẹẹrẹ ọ̀dọ́mọbìnrin ọmọ Ísírẹ́lì kan tó mú inú Ọlọ́run dùn. Nígbà ayè rẹ̀, ọ̀tá ni orílẹ̀-èdè Síríà àti ti Ísírẹ́lì. Lọ́jọ́ kan, àwọn ará Síríà bá Ísírẹ́lì jà, wọ́n sì mú ọ̀dọ́mọbìnrin náà lẹ́rú. Wọ́n wá mú ọ̀dọ́mọbìnrin  náà lọ sílè ọ̀gá àwọn ọmọ ogun kan tó ń jẹ́ Náámánì. Nígbà tó débẹ̀ ó di ìránṣẹ́ aya Náámánì.

Báwo ni ọmọbìnrin Ísírẹ́lì yìí ṣe mú inú Ọlọ́run dùn?

Wàyí o, Náámánì ní àrùn kan tó ń jẹ́ àrùn ẹ̀tẹ̀. Kò sí dókítà kankan tó lè wò ó sàn. Ṣùgbọ́n, ọ̀dọ́mọbìnrin tó wá láti Ísírẹ́lì yìí gbà gbọ́ pé ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ pàtàkì tí Ọlọ́run ní, ìyẹn wòlíì kan, lè ran Náámánì lọ́wọ́. Àmọ́ ṣá o, Náámánì àti aya rẹ̀ kì í sin Jèhófà. Ǹjẹ́ ó yẹ kí ọmọbìnrin yìí sọ ohun tó mọ̀ fún wọn? Tó bá jẹ́ ìwọ ni, kí ni ìwọ ì bá ṣe?—

Láìfọ̀rọ̀gùn, ọ̀dọ́mọbìnrin yìí sọ pé: ‘Ká ní Náámánì lè lọ sọ́dọ̀ wòlíì Jèhófà tó wà ní Ísírẹ́lì ni, ì bá wo Náámánì sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀ o.’ Náámánì fetí sí ọ̀rọ̀ ọmọbìnrin yìí, ó sì lọ sọ́dọ̀ wòlíì Jèhófà náà. Nígbà tó sì ṣe ohun tí wòlíì náà sọ pé kí ó ṣe, ara rẹ̀ yá. Èyí mú kí Náámánì di olùjọsìn Ọlọ́run tòótọ́.—2 Àwọn Ọba 5:1-15.

Ṣé ìwọ yóò fẹ́ láti ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti ohun tí Jèhófà lè ṣe, bíi ti ọ̀dọ́mọbìnrin náà?— Ta ni o mọ̀ pé o lè ràn lọ́wọ́?— Lóòótọ́, wọ́n lè kọ́kọ́ rò pé àwọn ò nílò ìránlọ́wọ́. Ṣùgbọ́n o lè sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun rere tí Jèhófà ṣe fún wọn. Ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n fetí sílẹ̀. Mọ̀ dájú pé èyí yóò mú inú Ọlọ́run dùn.

Ọ̀rọ̀ ìyànjú síwájú sí i fún àwọn ọmọdé pé kí wọ́n ní inú dídùn sí sísin Ọlọ́run, wà nínú Sáàmù 122:1; 148:12, 13; Oníwàásù 12:1; 1 Tímótì 4:12; àti Hébérù 10:23-25.