Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà

A Lè Jí Dìde Kúrò Nínú Ikú!

A Lè Jí Dìde Kúrò Nínú Ikú!

A Lè Jí Dìde Kúrò Nínú Ikú!

BÍ A bá kú, ǹjẹ́ Ọlọ́run á fẹ́ láti jí wa dìde, ìyẹn ni pé kí ó mú wa padà wà láàyè?— Jóòbù ẹni rere gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ń fẹ́ láti mú wa padà wà láàyè. Nítorí náà, nígbà tí Jóòbù rò pé òun fẹ́ kú, ó sọ fún Ọlọ́run pé: “Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn.” Jóòbù sọ pé Jèhófà Ọlọ́run yóò ṣe àfẹ́rí, tàbí pé yóò wù ú gan-an, láti jí òun dìde.—Jóòbù 14:14, 15.

Jésù, máa ń ṣe bíi ti Bàbá rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run, gẹ́lẹ́. Jésù fẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́. Nígbà tí ọkùnrin kan tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ sọ fún un pé, “bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́,” Jésù dáhùn pé: “Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀.” Ó sì wo àrùn ẹ̀tẹ̀ ọkùnrin náà sàn kúrò lára rẹ̀.—Máàkù 1:40-42.

Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun fẹ́ràn àwọn ọmọ kéékèèké?

Jésù ti kọ́ bí a ṣe ń fẹ́ràn àwọn ọmọdé lọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀. Láyé àtijọ́, ẹ̀ẹ̀mejì ni Jèhófà lo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti jí ọmọ kékeré dìde. Èlíjà bẹ Jèhófà pé kí ó jí ọmọ obìnrin kan tó tọ́jú Èlíjà dáadáa. Jèhófà sì jí i dìde lóòótọ́. Jèhófà sì tún lo Èlíṣà ìránṣẹ́ rẹ̀ láti jí ọmọkùnrin  kékeré kan dìde.—1 Àwọn Ọba 17:17-24; 2 Àwọn Ọba 4:32-37.

Ǹjẹ́ kò dùn mọ́ wa gan-an láti mọ̀ pé Jèhófà fẹ́ràn wa gidigidi?— Kì í ṣe kìkì ìgbà tí a bá wà láàyè nìkan ló ń ronú nípa wa. Ó tún máa ń rántí wa pẹ̀lú tí a bá kú. Jésù sọ pé bí àwọn tí Bàbá wa ọ̀run fẹ́ràn bá kú pàápàá, ó máa ń kà wọ́n sí ẹni tó wà láàyè! (Lúùkù 20:38) Bíbélì sọ pé ‘kì í ṣe ikú tàbí ìyè tàbí àwọn ohun tí ó wà níhìn-ín tàbí àwọn ohun tí ń bọ̀ ni yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.’—Róòmù 8:38, 39.

Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó fi hàn pé Jèhófà ń ṣàníyàn nípa àwọn ọmọdé. Ìwọ yóò rántí pé Jésù wá àyè láti bá àwọn ọmọdé sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ o mọ̀ pé Ọlọ́run fún Jésù ní agbára láti mú àwọn ọmọdé tó ti kú padà wà láàyè?— Jẹ́ kí á sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí Jésù jí ọmọ ọdún méjìlá kan dìde, ìyẹn ọmọ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jáírù.

Jáírù àti aya rẹ̀ àti ọmọ kan ṣoṣo tí wọ́n bí jọ ń gbé ní ẹ̀bá Òkun Gálílì. Lọ́jọ́ kan, ọmọbìnrin yìí ṣàìsàn gan-an, Jáírù sì rí i pé yóò kú. Jáírù wá rántí Jésù, ẹni pàtàkì kan tí ó ti gbọ́ pé ó lè mú àwọn èèyàn lára dá. Nítorí náà, Jáírù wá Jésù lọ. Ó rí Jésù létí Òkun Gálílì, tí ó ń kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́.

Jáírù la àárín èrò kọjá, ó sì lọ kúnlẹ̀ síwájú Jésù. Ó sọ fún Jésù pé: ‘Ọmọbìnrin mi kékeré ń ṣàìsàn gan-an. Ẹ jọ̀ọ́ ṣé ẹ lè wá bá mi wò ó sàn? Ẹ jọ̀ọ́, mo bẹ̀ yín, ẹ wá.’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ Jésù bá Jáírù lọ. Àwùjọ tó wà lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá náà tẹ̀ lé wọn lọ pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí wọ́n rìn díẹ̀ síwájú, àwọn ọkùnrin kan wá láti ilé Jáírù, wọ́n sọ fún un pé: ‘Ọmọbìnrin rẹ ti kú! Èé ṣe tí o tún fi ń yọ olùkọ́ lẹ́nu?’

Ọ̀rọ̀ yìí ta sí Jésù létí bí àwọn ọkùnrin náà ṣe ń sọ ọ́. Ó mọ̀ pé ó dun Jáírù gan-an pé ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo yìí ti kú. Nítorí náà, Jésù  sọ fún un pé: ‘Má bẹ̀rù. Sáà ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ara ọmọbìnrin rẹ yóò sì yá.’ Wọ́n ń lọ, títí wọ́n fi dé ilé Jáírù. Àwọn ọ̀rẹ́ ìdílé wọn ń sunkún níbẹ̀. Inú wọn bà jẹ́ pé ọmọ kékeré tí wọ́n fẹ́ràn yìí ti kú. Ṣùgbọ́n Jésù sọ fún wọn pé: ‘Ẹ dákẹ́, ẹ má sunkún mọ́. Ọmọ náà kò kú, ó kàn ń sùn ni.’

Nígbà tí Jésù sọ èyí, àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí rẹ́rìn-ín, nítorí wọ́n mọ̀ pé ọmọbìnrin náà ti kú. Nígbà náà, kí ni ìdí tí o rò pé Jésù fi sọ pé ó ń sùn?— Ẹ̀kọ́ wo ni o rò pé ó fẹ́ kọ́ àwọn èèyàn?— Ó fẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ikú dà bí oorun tí èèyàn sùn wọra. Ó fẹ́ kọ́ wọn pé nípa agbára Ọlọ́run, òun lè mú kí ẹni tó ti kú padà wà láàyè gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rọrùn fún wa láti jí ẹni tó ń sùn.

Ẹ̀kọ́ wo ni a rí kọ́ látinú jíjí tí Jésù jí ọmọ Jáírù dìde?

Jésù mú kí gbogbo èèyàn jáde kúrò nínú ilé yẹn, àyàfi Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù pẹ̀lú ìyá àti bàbá ọmọbìnrin náà. Ó wá wọ ibi tí ọmọ kékeré náà wà. Ó di ọwọ́ rẹ̀ mú, ó ní: ‘Ọmọbìnrin, dìde!’ Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó dìde ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn! Bàbá àti ìyá ọmọbìnrin náà wá bẹ̀rẹ̀ sí yọ ayọ̀ ńlá.—Máàkù 5:21-24, 35-43; Lúùkù 8:40-42, 49-56.

Wàyí o, ronú nípa èyí. Níwọ̀n bí Jésù ti lè mú ọmọbìnrin yìí wà  láàyè padà, ǹjẹ́ ó lè ṣe ohun kan náà fún àwọn ẹlòmíràn?— Ǹjẹ́ o rò pé yóò ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́?— Bẹ́ẹ̀ ni o, yóò ṣe bẹ́ẹ̀. Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [mi], wọn yóò sì jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29.

Ǹjẹ́ o rò pé Jésù ń fẹ́ láti jí àwọn èèyàn dìde?— Àpẹẹrẹ mìíràn nínú Bíbélì dáhùn ìbéèrè yẹn fún wa. Ohun kan tí ó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan ní ẹ̀bá ìlú Náínì fi hàn bí ó ṣe máa ń rí lára Jésù tí àwọn èèyàn bá ń ṣọ̀fọ̀ òkú.

Obìnrin kan wà láàárín èrò tó ń tẹ̀ lé òkú ọmọkùnrin rẹ̀ bí wọ́n ṣe ń jáde kúrò nínú ìlú Náínì láti lọ sìnkú rẹ̀. Kò tíì pẹ́ púpọ̀ tí ọkọ rẹ̀ kú, ọmọ kan ṣoṣo tí ó bí sì tún wá kú nísinsìnyí. Áà, ó mà dùn ún gan-an o! Ọ̀pọ̀ àwọn ará Náínì ló ń tẹ̀ lé wọn bí wọ́n ṣe ń gbé òkú ọmọ rẹ̀ jáde nínú ìlú náà. Obìnrin náà ń sunkún, àwọn èèyàn náà ò sì lè ṣe ohunkóhun láti tù ú nínú.

Ní ọjọ́ yìí, ó ṣẹlẹ̀ pé Jésù àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ń lọ́ sí ọ̀nà ìlú Náínì. Ní ẹ̀bá ẹnubodè ìlú náà, wọ́n pàdé èrò tó ń lọ sin òkú ọmọ obìnrin náà. Nígbà tí Jésù rí obìnrin tí ó ń sunkún náà, àánú rẹ̀ ṣe é gan-an. Ìbànújẹ́ ńlá tó bá obìnrin náà dun Jésù gan-an. Ó fẹ́ láti ràn án lọ́wọ́.

Nítorí náà, ó fi ohùn pẹ̀lẹ́ sọ̀rọ̀ fún obìnrin náà pẹ̀lú ìdánilójú, èyí tó mú kí obìnrin yìí fetí sí i, ó sọ pé: ‘Má sunkún mọ́.’ Bí ó ṣe sọ̀rọ̀ àti ìṣesí rẹ̀ mú kí gbogbo èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí wò ó pé kí ló fẹ́ ṣe. Bí Jésù ṣe kọjá sí ibi tí òkú náà wà, ó dájú pé àwọn èèyàn yóò máa ronú ohun tó fẹ́ ṣe. Jésù sọ̀rọ̀, ó pàṣẹ pé: “Ọ̀dọ́kùnrin, mo wí fún ọ, Dìde!” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ọmọ náà dìde nílẹ̀, ó sì jókòó! Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀.—Lúùkù 7:11-17.

Ṣáà fojú inú wo bó ṣe máa rí lára obìnrin náà! Báwo ló ṣe máa  rí lára tìrẹ bí èèyàn rẹ kan tó ti kú bá tún jí dìde padà?— Ǹjẹ́ èyí kò fi hàn pé Jésù fẹ́ràn àwọn èèyàn ní tòótọ́ àti pé ó ń fẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́?— Ṣáà ro bí ó ṣe máa rí nínú ayé tuntun Ọlọ́run nígbà tí a óò máa kí àwọn tó jíǹde káàbọ̀ sí ayé padà!—2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4.

Kí ni jíjí tí Jésù jí ọmọ kan ṣoṣo tí obìnrin yìí bí dìde fi hàn?

Ní àkókò náà, a óò rí àwọn tí a mọ̀ lára àwọn tó jíǹde, títí kan àwọn ọmọdé. A óò dá wọn mọ̀ gẹ́lẹ́ bí Jáírù ṣe mọ ọmọbìnrin rẹ̀ nígbà tí Jésù jí i dìde. Àwọn mìíràn yóò jẹ́ ara àwọn tó ti kú ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún tàbí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò ní gbàgbé wọn rárá bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kú tipẹ́tipẹ́.

Ǹjẹ́ kò dùn mọ́ni gidigidi láti mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Ọmọ rẹ̀ fẹ́ràn wa tó báyìí?— Kì í ṣe ìwọ̀nba ọdún mélòó kan péré ni wọ́n fẹ́ kí á fi wà láàyè o, wọ́n fẹ́ kí á máa gbé títí láé ni!

Ní ti ohun àgbàyanu tí Bíbélì sọ pé yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn òkú, jọ̀wọ́ ka Aísáyà 25:8; Ìṣe 24:15; àti 1 Kọ́ríńtì 15:20-22.