Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà

Inú Bíbélì ni ìmọ̀ràn tó dáa jù láyé wà. Àwọn ọmọ á kọ́ ohun tí Bàbá wọn ọ̀run sọ, kì í ṣe ohun tí èèyàn lásán sọ.

Ohun Tó Yẹ Kí Àwọn Òbí Ṣe fún Àwọn Ọmọ Wọn

Bí a ṣe ṣe ìwé yìí á jẹ́ kí àwọn ọmọdé sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn lórí àwọn kókó pàtàkì kan fún àwọn tó ń ka ìwé náà fún wọn.

Ohun Tó Mú Kí Jésù Jẹ́ Olùkọ́ Ńlá

Irú àwọn nǹkan wo ni Jésù fi kọ́ni? Ibo sì ni ohun tó fi kọ́ni ti wá?

Lẹ́tà Kan Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Tó Fẹ́ràn Wa

Inú ìwé kan tó ṣeyebíye ju gbogbo ìwé lọ ni lẹ́tà yìí wà.

Ẹni Tí Ó Dá Ohun Gbogbo

Ta ló dá àwọn ẹyẹ, tó sì kọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń kọrin? Tá ló dá àwọn koríko? Tá ló dá ẹ?

Ọlọ́run Ní Orúkọ Kan

Gbogbo wa la ní orúkọ. Ṣé o mọ orúkọ Ọlọ́run? Kí ló dé tí orúkọ rẹ̀ fi ṣe pàtàkì?

“Èyí Ni Ọmọ Mi”

Kí ló mú kí Jésù yàtọ̀ lẹ́dàá?

Olùkọ́ Ńlá Náà Sin Àwọn Ẹlòmíràn

Ṣé inú rẹ máa ń dùn tí àwọn èèyàn bá ṣe ohun tó dáa sí ẹ? Inú gbogbo wa ló máa ń dùn, Olùkọ́ Ńlá náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀.

Ìgbọràn Ń Dáàbò Bò Ọ́

Àwọn ọmọdé lè kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn àgbà. Tí Ọlọ́run bá sọ pé ká ṣe ohun kan, kó dá wa lójú pé ohun tó dáa jù nìyẹn.

Àwọn Kan Wà Nípò Tó Ga Ju Tiwa Lọ

Ẹni rere ni àwọn kan lára wọn, ẹni búburú sì ni àwọn míì.

A Gbọ́dọ̀ Kọ Ìdẹwò

Kí lo máa ṣe tí ẹnì kan bá ní kó o ṣe ohun tí kò tọ́?

Agbára Jésù Ju Ti Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Lọ

Kò yẹ ká máa bẹ̀rù àwọn ẹ̀mí èṣù, àmọ́ ó yẹ ká ṣọ́ra kí wọ́n má bàa ṣì wá lọ́nà.

Ìrànlọ́wọ́ Látọ̀dọ̀ Àwọn Áńgẹ́lì Ọlọ́run

Àwọn áńgẹ́lì Jèhófà máa ń ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń sìn ín lọ́wọ́.

Jésù Kọ́ Wa Bí A Ó Ṣe Máa Gbàdúrà

Tọ̀sántòru lo lè bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, á sì gbọ́ ẹ.

Àwọn Tó Di Ọmọ Ẹ̀yìn Jésù

Irú èèyàn wo ni wọ́n?

Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Dárí Jini

Jésù sọ ìtàn kan tó máa jẹ́ kó yé wa.

Ẹ̀kọ́ Nípa Jíjẹ́ Onínúure

Kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìtàn ará Samáríà tó jẹ́ onínúure.

Kí Ni Ó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ?

Báwo la ṣe lè ní ọ̀rọ̀ sọ́dọ̀ Ọlọ́run?

Bí A Ṣe Lè Ní Ayọ̀

Olùkọ́ Ńlá náà jẹ́ ká mọ àṣírí pàtàkì kan.

Ǹjẹ́ O Máa Ń Rántí Láti Dúpẹ́?

O lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá.

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Jà?

Kí ló yẹ kí o ṣe tí wàhálà bá ṣẹlẹ̀?

Ǹjẹ́ O Máa Ń Fẹ́ Jẹ́ Ẹni Àkọ́kọ́ Nígbà Gbogbo?

Kí ni Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tí wọ́n ń jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí?

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Fọ́nnu?

Jésù sọ ìtàn Farisí kan àti agbowó orí kan.

Ìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Máa Purọ́

Wo ohun tí Jèhófà ṣe fún Ananíà àti Sàfírà.

Ìdí Tí Àwọn Èèyàn Fi Ń Ṣàìsàn

Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tí àwọn èèyàn ò ní ṣàìsàn mọ́?

Má Ṣe Di Olè!

Wo àpẹẹrẹ àwọn mẹ́rin tí wọ́n mú ohun tí kì í ṣe tiwọn.

Ǹjẹ́ Àwọn Tó Ń Ṣe Ohun Búburú Lè Yí Padà?

Àpẹẹrẹ Sọ́ọ̀lù àti ti aṣẹ́wó kan jẹ́ ká mọ ìdáhùn.

Ìdí Tó Fi Nira Láti Máa Ṣe Rere

Kí ni àwọn èèyàn burúkú ṣe máa ṣe tó ò bá ṣe ohun tí wọ́n sọ?

Ta Ni Ọlọ́run Rẹ?

Oríṣiríṣi ọlọ́run ni àwọn èèyàn máa ń sìn. Kí ló yẹ kó o ṣe? Àwọn ọ̀dọ́ Hébérù mẹ́ta jẹ́ ká mọ ìdáhùn.

Bí A Ṣe Lè Mọ Ẹni Tó Yẹ Kí Á Ṣègbọràn Sí

“Ẹ san àwọn ohun ti Késárì padà fún Késárì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”

Ǹjẹ́ Gbogbo Àpèjẹ Ni Inú Ọlọ́run Dùn Sí?

Ṣé o mọ̀ pé Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn àpèjẹ mélòó kan? A lè mọ ojú tí Ọlọ́run fi wò wọ́n.

Ìrànlọ́wọ́ Láti Borí Ìbẹ̀rù

Olùkọ́ Ńlá náà ò sọ pé ó máa rọrùn láti sin Jèhófà, àmọ́ ohun tá a lè ṣe wà ká lè ní ìgboyà, ká sì rí ìrànwọ́.

Ibi Tí A Ti Lè Rí Ìtùnú Gbà

Kí ni kó o ṣe tí inú rẹ bá bà jẹ́ tàbí tó o dá wà?

Bí Ọlọ́run Ṣe Dáàbò Bo Jésù

Kọ́ nípa bí Jèhófà ṣe dáàbò bo àwọn tó fẹ́ pa Jésù nígbà tó wà ní ọmọdé.

Jésù Lè Dáàbò Bò Wá

Nígbà tó wà láyé, ó jẹ́ ká mọ bí òun ṣe lè dáàbò bo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òun.

Kí Ni Yóò Ṣẹlẹ̀ Bí A Bá Kú?

Ṣé ó yẹ kó o máa bẹ̀rù ikú tàbí kó o máa bẹ̀rù àwọn òkú?

A Lè Jí Dìde Kúrò Nínú Ikú!

Ọlọ́run fún Jésù lágbára láti jí àwọn èèyàn dìde, títí kan àwọn ọmọdé.

Àwọn Wo Ni A Óò Jí Dìde? Ibo Ni Wọn Yóò Máa Gbé?

Kí ni Jésù sọ nípa àwọn ìbéèrè yìí?

Bí A Ṣe Lè Rántí Jèhófà àti Ọmọ Rẹ̀

Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ọ̀nà pàtàkì kan tí wọ́n lè gbà máa rántí ohun tí Jèhófà àti Jésù ṣe fún wa.

Ìdí Tó Fi Yẹ Kí Á Fẹ́ràn Jésù

Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ pípé lélẹ̀ ká lè ní ìyè àìnípẹ̀kun!

Ọlọ́run Rántí Ọmọ Rẹ̀

Ọlọ́run jí Jésù dìde.

Bí A Ṣe Lè Mú Inú Ọlọ́run Dùn

Òwe inú Bíbélì kan sọ pé: “Ọmọ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀.”

Àwọn Ọmọdé Tó Mú Inú Ọlọ́run Dùn

Irú àwọn nǹkan wo lo lè ṣe láti mú inú Ọlọ́run dùn?

Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Ṣiṣẹ́

Tí èèyàn bá ń ṣiṣẹ́, ó máa ń jẹ́ kí ara àti ọpọlọ ṣiṣẹ́ dáadáa. Kọ́ bí o ṣe lè gbádùn iṣẹ́.

Àwọn Wo Ni Arákùnrin àti Arábìnrin Wa?

Ṣé a lè ka àwọn tí kì í ṣe ọmọ ìyá, ọmọ bàbá wa mọ́ wọn?

Ó Yẹ Kí Àwọn Ọ̀rẹ́ Wa Fẹ́ràn Ọlọ́run

“Kí a má ṣì yín lọ́nà. Ẹgbẹ́ búburú a máa ba ìwà rere jẹ́.”

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run? Bí A Ṣe Lè Fi Hàn Pé À Ń Fẹ́ Ẹ

Nígbà tí Jésù bá bẹ̀rẹ̀ sí í darí gbogbo ohun tó wà láyé, ó máa ṣe àwọn àyípadà ńlá kan.

Omi Pa Ayé kan Run—Ǹjẹ́ Irú Ẹ̀ Tún Lè Ṣẹlẹ̀ Mọ́?

Àwọn olódodo á máa gbé ayé títí láé.

Bí A Ṣe Lè Mọ̀ Pé Amágẹ́dọ́nì Ti Sún Mọ́lé

Àwọn àmì tó fi hàn bẹ́ẹ̀ pọ̀ ní àyíká wa.

Ayé Tuntun Ọlọ́run, Ayé Àlàáfíà—Ìwọ Lè Wà Níbẹ̀

Kí lo gbọ́dọ̀ ṣe láti gbádùn rẹ̀ títí láé?