Ṣé o rò pé . . .

  • ìwé tí wọ́n fi ọgbọ́n èèyàn kọ ni?

  • àbí ìwé ìtàn àti àròsọ?

  • àbí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

 OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.”—2 Tímótì 3:16, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ BÍBÉLÌ YẸN LÈ ṢE FÚN Ẹ

Wàá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè pàtàkì nípa ìgbésí ayé.Òwe 2:1-5.

Wàá rí ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbára lé tó máa wúlò fún ẹ lójoojúmọ́.Sáàmù 119:105.

Wàá ní ìrètí tó dájú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.Róòmù 15:4.

 ǸJẸ́ A LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?

Bẹ́ẹ̀ ni. Mẹ́ta lára ìdí tó fi yẹ ká gba ọ̀rọ̀ Bíbélì gbọ́ rèé:

  • Ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ bára mu látòkè délẹ̀. Nǹkan bí ogójì [40] èèyàn ló kọ Bíbélì. Nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ [1,600] ọdún ni wọ́n sì fi kọ ọ́. Ọ̀pọ̀ nínú wọn kò rí ara wọn rí. Àmọ́ gbogbo ohun tó wà nínú àwọn ìwé tí wọ́n kọ bára mu, ẹṣin ọ̀rọ̀ kan náà ló sì dá lé!

  • Òtítọ́ ni ìtàn inú rẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó máa ń kọ ìtàn nínú ayé kì í fẹ́ sọ nípa àṣìṣe àwọn èèyàn wọn. Àmọ́ àwọn tó kọ Bíbélì kò fi ọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nípa àṣìṣe tí wọ́n ṣe àtèyí tàwọn èèyàn wọn ṣe.—2 Kíróníkà 36:15, 16; Sáàmù 51:1-4.

  • Àsọtẹ́lẹ̀ inú rẹ̀ ṣeé gbára lé. Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìparun ìlú Bábílónì àtijọ́ ní nǹkan bí igba [200] ọdún ṣáájú kó tó wáyé. (Aísáyà 13:17-22) Yàtọ̀ sí pé ó sọ bí wọ́n ṣe máa pa ìlú náà run, ó tún sọ orúkọ ọ̀gá ológun tó máa pa ìlú náà run!—Aísáyà 45:1-3.

    Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ míì nínú Bíbélì ló tún ṣẹ láìkù síbì kan. Ṣebí irú ìwé tá a retí pé kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ náà nìyẹn?—2 Pétérù 1:21.

 RÒ Ó WÒ NÁ

Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè mú kí ayé rẹ dára sí i?

Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé AÍSÁYÀ 48:17, 18 àti 2 TÍMÓTÌ 3:16, 17.