Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Ẹ̀yin Ará Wa Ọ̀wọ́n:

Wòlíì Aísáyà fi ìrẹ̀lẹ̀ sọ pé gbogbo àṣeyọrí tàbí aásìkí èyíkéyìí tí ìjọba Júdà bá gbádùn, ó jẹ́ nítorí ìbùkún Jèhófà. Bó ṣe wà ní Aísáyà 26:12, wòlíì náà sọ pé: “Jèhófà, . . . gbogbo iṣẹ́ wa ni o ti ṣe fún wa.” Àwa náà gbà pẹ̀lú wòlíì yẹn nígbà tá a ronú lórí gbogbo iṣẹ́ ribiribi tẹ́ ẹ ti gbéṣe lọ́dùn iṣẹ́ ìsìn tó kọjá. Láìsí tàbí ṣùgbọ́n, Jèhófà ń ṣe ‘àwọn ohun àgbàyanu tí a kò tíì ṣe rí!’ (Ẹ́kís. 34:10) Ìwọ náà ronú nípa àwọn ìbùkún tó ti rọ̀jò sórí wa.

Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn ń lo Ìkànnì wa jw.org, lọ́nà tó gbéṣẹ́ gan-an. Ní báyìí, ìkànnì yìí wà ní èyí tó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [600] ède lọ, àwọn èèyàn sì le ka tàbí wa ìtẹ̀jáde wa lédè tó ju ọgọ́rùn-ún méje àtààbọ̀ [750] lọ. Ǹjẹ́ ìkànnì yìí ti ran àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́wọ́? Gbé àpẹẹrẹ yìí yẹ̀ wò: Ẹ̀sìn ti sú tọkọtaya kan torí ìwà àgàbàgebè tó kún inú ìsìn. Níbi tí wọ́n ti ń wá ìtọ́sọ́nà, wọ́n rí ìkànnì wa, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn àpilẹ̀kọ tó wà níbẹ̀, wọ́n sì ń wo àwọn fídíò pẹ̀lú. Nígbà tó yá, wọ́n wa ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ jáde, wọ́n sì ń kà á pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn méjì tí wọ́n lé lọ́mọ ọdún méjìlá. Kódà, ohun tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ láàárọ̀ ọjọ́ kan nìyẹn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi wàásù dọ́dọ̀ wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí náà wá rí i pé àwọn ohun tí ìdílé yẹn ń kọ́ lórí ìkànnì náà ti tún ayé wọn ṣe  gan-an. Wọ́n jáwọ́ nínú lílo ère, ṣíṣe àwọn ayẹyẹ tí kò bá ìwé mímọ́ mu àti wíwo àwọn fíìmù tí ò dáa, wọ́n tún yọ àwọn yẹtí tí wọ́n ki bọ ara kítikìti, wọ́n sì pa àwọn ohun tí wọ́n fín sí ara wọn rẹ́. Ẹ wo adúrú àtúnṣe tí wọ́n ṣe káwọn Ẹlẹ́rìí tiẹ̀ tó pàdé wọn rárá! Nígbà tí à ń kọ ìwé yìí lọ́wọ́, àwọn tọkọtaya yìí àti ọ̀kan nínú àwọn ọmọ wọn ti di akéde, tọkọtaya náà sì ń múra àtiṣèrìbọmi láìpẹ́.

A tún gba ọ̀pọ̀ lẹ́tà ìdúpẹ́ fún ohun àrànṣe ńlá kan tí Jèhófà tún ń lò báyìí, ìyẹn Ètò Orí Tẹlifíṣọ̀n JW. Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé a ti ń gbé ètò yìí jáde ni èdè tó lé ní àádọ́rin [70] báyìí, àwọn èdè míì sì máa kún un láìpẹ́. Ọ̀pọ̀ ìdílé ló máa ń fi àkókó Ìjọsìn Ìdílé wọn wo ètò yìí. Ìmọ́rírì mú kí arákùnrin kan sọ pé: “Ṣe ni ètò Jèhófà túbọ̀ ń gbèrú sí i, ọkàn wa sì balẹ̀ pé ìgbà yìí gan-an la wá sún mọ́ oríléeṣẹ́ wa!”

Gbogbo wa la mọ̀ pé ohun pàtàkì ni àpéjọ àgbègbè jẹ́ sí àwọn èèyàn Jèhófà, tọdún iṣẹ́ ìsìn 2015 náà ò sì gbẹ́yìn rárá. Bí àpẹẹrẹ, ní àpéjọ àgbègbè 2015, ó tó fídíò àti àwòrán méjìlélógójì [42] tá a wò, a sì tún gbádùn fídíò orin aládùn níbẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àárọ̀ àti ọ̀sán ọjọ́ kọ̀ọ̀kan. Arákùnrin kan kíyè sí nǹkan kan nípa àpéjọ náà pé: “Ṣe ló dà bíi pé kò sẹ́ni tó fẹ́ dìde lórí ìjókòó rẹ̀ torí wọn ò fẹ́ kí nǹkan kan fo àwọn ru nínú ìtólẹ́ṣẹẹsẹ náà.” Míṣọ́nnárì kan tiẹ̀ sọ pé: “Àwọn fídíò tá a wò ní àpéjọ àgbègbè tó kọjá yìí jẹ́ kí òtítọ́ àti Ìjọba Ọlọ́run túbọ̀ ṣe kedere sí mi gan-an.”

Ìbùkún míì tí Jèhófà fún wa lọ́dún tó kọjá ni àwọn orin tuntun tó jáde. Tọkọtaya kan sọ pé: “Àwọn orin  yìí jẹ́ kó dá bíi pé Jèhófà gbá wa mọ́ra. Wọ́n ń mú ọkàn wa fúyẹ́ nínú gbogbo ìṣoro wa.” Àpẹ́jọ yìí rán wa létí pé akọ iṣẹ́ làwọn ará wa tí wọ́n ń yọ̀ǹda láti máa kọrin fún Watchtower ń ṣe láti wá sí oríléeṣẹ́ kí wọ́n lè kọ àwọn orin ìyìn sí Jèhófà fún ìgbádùn wa!

A rọ gbogbo yín pé kẹ́ ẹ ṣe bíi Jèhófà, ẹ fìfẹ́ gba àwọn tó ń pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà wọlé

Ṣé ìjọ tiyín náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn ohun tá a fi ń pàtẹ àwọn ìwé wa níbi tí èrò pọ̀ sí? Ẹ ò rí i pé ọ̀nà ìwàásù yẹn ń méso jáde gan-an! Ọ̀nà ìwàásù yìí ti jẹ́ ká lè pàdé àwọn èèyàn tí kò ṣeé ṣe fún wa láti bá nílé, pàápàá àwọn tó ń gbé láwọn ilé tí wọ́n mọ ògiri ràgàjì yí ká, àtàwọn ará wa míì tí wọ́n ti di aláìṣiṣẹ́ mọ́. Ní January 2015, ọkùnrin kan lórílẹ̀-èdè South Korea wá síbi tá a pàtẹ́ ìwé wa sí. Ó ní lẹ́nu àìpẹ́ yìí, òun ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa Ọlọ́run. Ká má fọ̀rọ̀ gùn, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí. Lóṣù February, ó lọ sí ìpàdé fúngbà àkọ́kọ́, ó sì jáwọ́ nínú sìgá mímú lóṣù March. Ní April, ó ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní South Korea, ó sì ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn rẹ̀ sí Jèhófà. Èyí wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àìmọye ìrírí tá a ti rí gbà lóríléeṣẹ́ wa níbí.

Àdúrà wa ni pé kí àwọn ohun tá a gbọ́ àti ìwé tó jáde ní àpéjọ yẹn ta ọ̀pọ̀ jí pàápàá àwọn tó ti fìgbà kan rí jẹ́ olùjọsìn Jèhófà, kí wọ́n lè pa dà wá sábẹ́ ààbò Jèhófà kí ọjọ́ tó lọ! A rọ gbogbo yín pé kẹ́ ẹ ṣe bíi Jèhófà, ẹ fìfẹ́ gba àwọn tó ń pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà wọlé.Ìsík. 34:16.

Láìsí tàbí ṣùgbọ́n, Jèhófà ti bù kún wa jìngbìnì lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá yìí. Kí wá ni ká tún máa retí? Ẹ jẹ́ ká máa wo ohun tí Jèhófà tún máa ṣe. Àmọ́ ní  báyìí ná, á fẹ́ kẹ́ ẹ mọ̀ pé àwa tá a wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí nífẹ̀ẹ́ gbogbo yín dénú, a sì ń gbàdúrà fún yín láìdabọ̀.

Ire o,

Àwa Arákùnrin yín,

Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà