Nígbà táwọn ará ní ẹ̀ka ọ́fíìsì gbọ́ pé wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ. Arákùnrin Ronald Jacka sọ pé: “A yára kó àwọn àkọ́sílẹ̀ ìsọfúnni nípa iṣẹ́ wa àti owó tí à ń ná ní ẹ̀ka kúrò ní ọ́fíìsì lọ́ sí àwọn ilé tí ìjọba kò lè fura sí, títí kan àwọn páálí tí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kún inú wọn. Lẹ́yin ìyẹn, a kó kúrò a wá ń lo ibì kan tó fara sin gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka ọ́fíìsì, a sì ta ilé tá à ń lò tẹ́lẹ̀ láìjẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀.”

Síbẹ̀, àwọn ará wa ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ láìfòyà. Ó ṣe tán, ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti ń fara da àdánwò kí ìjọba tó fòfin de iṣẹ́ wa, torí náà, wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà bíi ti àtẹ̀yìnwá. Àmọ́, ọ̀rọ̀ tó ṣẹlẹ̀ náà bá àwọn ará wa kan lábo. Ìbẹ̀rù mú kí àwọn alàgbà kan buwọ́ lùwé pé àwọn ò ní wàásù mọ́. Ṣe làwọn míì tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí i ka orúkọ àwọn ará tó wà ní ìjọ fáwọn aláṣẹ. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wá rán àwọn arákùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn sáwọn ìjọ kí wọ́n lè gbé àwọn ará ró kí wọ́n sì ran àwọn tó fà sẹ́yìn lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, Arákùnrin John Booth tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí wá sí Indonéṣíà, ó sì gbà àwọn ará níyànjú bíi bàbá sọ́mọ. Ó dájú pé ìmọ̀ràn yẹn bọ́ sákòókò.

Ó ṣe kedere pé Jèhófà tó jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn Ńlá ń fún àwọn èèyàn rẹ̀ lókun ó sì ń tù wọ́n nínú. (Ìsík. 34:15) Ńṣe làwọn alàgbà túbọ̀ fi kún ìsapá wọn láti mú kí àwọn ará tún àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà ṣe, àwọn akéde sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wàásù. (Mát. 10:16) Ọ̀pọ̀ ará ló ra Bíbélì tó bóde mu lọ́dọ̀ àwọn Indonesian Bible Society, wọ́n sì ń pín in fáwọn èèyàn, wọ́n á tún fìyẹn dọ́gbọ́n wàásù fún wọn. Àwọn míì ya ibi tí orúkọ àti àdírẹ́sì ètò Ọlọ́run wà nínú àwọn ìwé wa, wọ́n sì ń pín in fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ láti kà wọ́n. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà dá ọgbọ́n oríṣiríṣi láti máa wàásù, wọ́n á múra bí ẹni  tí ń tajà láti ojúlé dé ojúlé, bí àwọn tó ṣáájú wọn ti ṣe nígbà tí orílẹ̀-èdè Japan wá kógun ja orílẹ̀-èdè Indonéṣíà.

Margarete àti Norbert Häusler

Lọ́dún 1977, Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn tún gba ọ̀nà míì yọ síwa. Wọ́n kọ̀ wọn ò fún àwọn míṣọ́nnárì níwèé àṣẹ láti gbè nílùú mọ́. Torí náà, ètò Ọlọ́run rán àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní Indonéṣíà lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè míì. * Norbert Häusler tó jẹ́ míṣọ́nnárì tí òun àti Margarete ìyàwó rẹ̀ sìn ní ìlú Manado ní North Sulawesi sọ pé: “Ńṣe làwọn ará tẹ̀ lé wa dé pápákọ̀ òfuurufú láti kí wa pé ó dìgbóṣe. Bá a ṣe fẹ́ wọnú ọkọ̀ òfurufú, a bojú wẹ̀yìn a sì rí omilẹgbẹ àwọn èèyàn tó ń juwọ́  sí wa, tí wọ́n ń sọ pé: ‘Ẹ ṣé o. Ẹ kú àdúrótì wa o.’ Ńṣe lá bú sẹ́kún nígbà tá a wọnú ọkọ̀ òfurufú.”

Wàhálà Ṣẹlẹ̀ Ní Sumba

Bí ìròyìn ṣe ń tàn ka gbogbo erékùṣù pé wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, bẹ́ẹ̀ làwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó wà lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà pa ẹnu pọ̀ láti sọ fún àwọn ọmọ ìjọ wọn pé kí wọ́n máa ṣòfófó fún ìjọba tí wọ́n bá rí Ẹlẹ́rìí èyíkéyìí tó ń wàásù. Bí ìjọba ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn ará wa ní ọ̀pọ̀ erékùṣù nìyẹn tí wọ́n sì ń lù wọ́n lẹ́nu gbọ́rọ̀.

Ní àgbègbè Waingapu tó wà ní erékùṣù Sumba, ọ̀gá ológun tó wà níbẹ̀ sọ pé káwọn arákùnrin mẹ́tàlélógún [23] wá rí òun ní bárékè àwọn ológun tó wà ní erékùṣù náà, ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n fọwọ́ síwèé pé àwọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí mọ́. Torí pé àwọn ará náà kọ̀, ọ̀gá náà sọ fún wọn pé kí wọ́n máa lọ sílé, kí wọ́n sì pa dà wá sí bárékè lọ́jọ́ kejì. Ìrìn ọ̀hún ò sì kéré, kìlómítà mẹ́rìnlá ni àlọ àti àbọ̀, ẹsẹ̀ làwọn ará náà sì fi ń rìn ín.

Nígbà táwọn arákùnrin náà débẹ̀ lọ́jọ́ kejì, wọ́n ní kí wọ́n máa wọlé lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, ó sì pàṣẹ fún wọn pé kí wọ́n fọwọ́ síwèé náà. Bí ẹnì kan bá sọ pé òun ò fọwọ́ síwèé, ṣe làwọn sójà á bẹ̀rẹ̀ sí í fi igi ẹlẹ́gùn-ún lù ẹni ọ̀hún bíi kíkú bíi yíyè. Àwọn sójà yìí gba ọ̀rọ̀ náà sórí débi pé wọ́n a lu onítọ̀hún títí ó fi máa dákú. Bẹ́ẹ̀ àwọn arákùnrin tó kù ń dúró dé tọ́ọ̀nù tiwọn. Níkẹyìn, arákùnrin kan tó ń jẹ́ Mone Kele sọ pé òun máa fọwọ́ síwèé ní tòun. Inú àwọn ará yòókù bà jẹ́, àmọ́ inú ọ̀gá ológun náà dùn. Ṣé ẹ mọ ohun tí arákùnrin Mone kọ síwèé? Ó ní: “Mo pinnu pé títí ayé ni màá ṣì máa jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà!” Nígbà tí sójà náà rí ohun tó kọ, pẹ̀lú ìbínú ló fi na Mone, ọsibítù ló ti lajú, àmọ́ Mone kò fi Jèhófà sílẹ̀.

Odindi ọjọ́ mọ́kànlá [11] gbáko ni ọ̀gá ológun yìí fi ń fínná mọ́ àwọn ará kí wọ́n ṣáà lè sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn. Ó tiẹ̀ ní kí wọ́n dúró sínú oòrùn tó ń jóni lára látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Ó ní kí wọ́n  máa rákòòrò fún ọ̀pọ̀ máìlì. Ó tún di ẹrù tó wúwo lé wọn lórí, ó sì ní kí wọ́n máa gbé e sáré fún ọ̀pọ̀ wákàtí. Nígbà tó yá, ó de ọ̀bẹ ṣómúṣómú mọ́ ẹnu ìbọn rẹ̀, ó sì gbé e síbi ọ̀fun wọn, ó ní kí wọ́n bẹ́rí fún àsíá, síbẹ̀ àwọn ará wa kò yẹhùn. Ni ọ̀gá náà bá tún ní káwọn gòdògódó lu àwọn ará wa ní àlùbolẹ̀.

Ojoojúmọ́ làwọn ará wa máa ń fẹsẹ̀ rìn lọ sí bárékè náà, wọ́n á máa ronú irú ọwọ́ táwọn èèyàn náà tún máa yọ. Bí wọ́n ṣe ń rìn lọ lójú ọ̀nà, wọ́n máa ń gbàdúrà pa pọ̀, wọ́n sì máa ń fún ara wọn níṣìírí pé káwọn ṣe ọkàn akin. Lálaalẹ́ tí wọ́n bá sì ń pa dà lọ sílé, tàwọn ti ọgbẹ́ tó ń ṣẹ̀jẹ̀ lára, wọ́n máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé àwọn kò sẹ́ ìgbàgbọ́ àwọn.

Nígbà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì gbọ́ ohun tí ojú àwọn ará ń rí, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n tẹ wáyà ránṣẹ́ sí ọ̀gá ológún tó wà ní àgbègbè Waingapu, wọ́n jẹ́ kó mọ̀ pé ohun tó ń ṣe kù díẹ̀ káàtó. Yàtọ̀ sí òun, wọ́n tún tẹ wáyà ránṣẹ́ sí àwọn ọ̀gá àgbà ológun tó wà ní Timor àti ní Bali, wọ́n sì tún fi í ránṣẹ́ sí ọ̀gá pátápátá tó wà ní Jakarta títí kan àwọn léèkànléèkàn nínú ìjọba. Ohun tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣe yìí ba ọ̀gá ológun náà lẹ́rù, pé gbogbo ayé lo ti wá mọ̀ nípa ìwà aburú tí òun ń hù yìí, ló bá jáwọ́ nínú ìwà ìkà tó ń hù sáwọn ará.

“Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà Dà Bí Ìṣó”

Láwọn ọdún mélòó kan lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n fojú àwọn ará wa rí màbo ní orílẹ̀-èdè Indonéṣíà, wọ́n fi àwọn kan sẹ́wọ̀n, wọ́n lù wọ́n lẹnu gbọ́rọ̀, wọ́n sì lu wọn bí ẹni lu bàrà. Míṣọ́nnárì kan tó ń jẹ́ Bill Perrie sọ pé: “Nílùú kan, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ni ìjọba gbá àwọn eyín iwájú wọn yọ. Tí wọ́n bá rí arákùnrin tí eyín rẹ̀ pé, pẹ̀lú àwàdà ni wọ́n á béèrè  lọ́wọ́ rẹ̀ pé: ‘Ṣé ṣẹ̀ṣẹ̀dé ni ẹ́ ni? Àbí o ti ń yọ́lẹ̀ dà?’ Láìka bí wọ́n ṣe ṣenúnibíni sáwọn ará tó, wọn ò fìgbà kankan rẹ̀wẹ̀sì nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.”

“Àwọn àkókò tí mo lò lẹ́wọ̀n jẹ́ kí n túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì mú kí n lè máa fi àwọn ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì ṣèwà hù”

Láàárín ọdún mẹ́tàlá [13], àwọn ará mẹ́tàléláàádọ̀rún [93] ni wọ́n jù sẹ́wọ̀n, ẹni tí tiẹ̀ kéré jù ni oṣù méjì, àwọn míì sì lo tó ọdún mẹ́rin. Wọ́n kúkú sọ pé adánilóró fi agbára kọ́ni ni, ńṣe làwọn ará wa túbọ̀ dúró láìyẹsẹ̀ nínú ìjọsìn Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí arákùnrin Musa Rade lo oṣù mẹ́jọ lẹ́wọ̀n, ó ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ará tó wà lágbègbè rẹ̀, ó sì fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n máa wàásù nìṣó. Ó ní, “Àwọn àkókò tí mo lò lẹ́wọ̀n jẹ́ kí n túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì mú kí n lè máa fi àwọn ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì ṣèwà hù.” Ọ̀rọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣáà ń ya àwọn èèyàn lẹ́nu, ṣe ni wọ́n sọ pé: “Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí ṣáá, ńṣe lẹ dà bí ìṣó. Bí wọ́n ṣe ń gbá hámà mọ́ ọn yín bẹ́ẹ̀ lẹ̀ ń lágbára sí i tẹ́ ẹ sì ń gbilẹ̀.”

Àwọn àkéde ń lọ wàásù ní ìlú Ambon tó wà ní Maluku

^ ìpínrọ̀ 1 Àwọn míṣọ́nnárì kan ò kúrò lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà. Bí àpẹẹrẹ, Arákùnrin Peter Vanderhaegen àti Len Davis ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì, wọ́n sì ti dàgbà tó láti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́. Ẹlòmíì ni Arábìnrin Marian Tambunan tó fẹ́ ọmọ ilẹ̀ Indonéṣíà. Torí àwọn ìdí yìí, ìjọba gbà kí àwọn mẹ́ta yìí dúró sí Indonéṣíà. Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí sì fi ìtara wàásù, Jèhófà sì bù kún iṣẹ́ wọn gan-an ní gbogbo àsìkò tí ìjọba fòfin de iṣẹ́ wa.