• WỌ́N BÍ I NÍ 1915

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1940

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Aṣáájú-ọ̀nà tó fi ìgboyà di ìṣòtítọ́ rẹ̀ mú láìka pé àwọn aláṣẹ halẹ̀ mọ́ ọn tí wọ́n sì fọ̀rọ̀ lọ́ ọ nífun.

NÍGBÀ Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn sójà wá mú Arákùnrin Elias àti Josephine ìyàwó rẹ̀ lọ àgọ́ wọn tó le jù tí wọ́n ń pè ní Kempeitai, tó wà lágbègbè Sukabumi ní West Java. André ni wọ́n kọ́kọ́ fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò. Ṣe ni wọ́n ń rọ̀jò ìbéèrè lù ú lọ́tùn-ún lósì láti pin ín lẹ́mìí kó lè juwọ́ sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n bíi pé: “Ta làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Ṣe amí ni yín ni àbí ẹgbẹ́ ọlọ̀tẹ̀ síjọba Japan?”

Arákùnrin André dáhùn pé: “Ìránṣẹ́ Ọlọ́run Olódùmarè ni wá, àwa kò sí nídìí aburú kankan.” Lójijì ni ọ̀gá ológun náà fa idà yọ, ó gbé e sókè, ó ní: “O jẹ́ jẹ́wọ́ kí n tó pa ẹ́ dà nù.”

André mọ́kàn, ó gbórí lé tábìlì iwájú rẹ̀, ó sì ń finú gbàdúrà. Kò pẹ́ ni gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ bú sẹ́rìn-ín. Ọ̀gá náà wá sọ fún André pé: “Ọkùnrin ni ẹ́, o láyà!” Ló bá tún bọ́ sọ́dọ̀ Josephine ìyàwó André. Ó da ìbéèrè bo òun náà, àmọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó sọ kò yàtọ̀ sí ohun tí ọkọ rẹ̀ sọ.  Níkẹyìn, ọ̀gá náà sọ pé: “Ẹ kóra yín kúrò ńbí. Àṣé ẹ ò tiẹ̀ jẹ́ nǹkan kan!”

Ọ̀pọ̀ oṣù lẹ́yìn náà, “àwọn èké arákùnrin” kan lọ rojọ́ mọ́ André, ni wọ́n bá tún mú un lọ tì mọ́lé. (2 Kọ́r. 11:26) Ebi hàn án léèmọ̀ nínú àtìmọ́lé, àwọn èérún oúnjẹ tó rí ṣàjẹ nílẹ̀ẹ́lẹ̀ ló fi gbéra fún ọ̀pọ̀ oṣù. Síbẹ̀, àwọn wọ́dà kò rí nǹkan kan tí wọ́n lè ṣe láti yẹ ìgbàgbọ́ André. Nígbà kan tí Josephine wá bẹ̀ ẹ́ wò lẹ́wọ̀n, André yọjú níbi irin ẹ̀wọ̀n rẹ̀, ó sì sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí i létí pé: “Fọkàn balẹ̀ aya mi, wọn ì bàa pa mí tàbí dá mi sílẹ̀, ti Jèhófà ni màá ṣe. Ó lè jẹ́ òkú mi ni wọ́n á gbé jáde kúrò níbí o, àmọ́ pé kí n sẹ́ Jèhófà torí kí wọ́n lè dá mi sílẹ̀, ká má rí i!”

Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà lẹ́wọ̀n, André gbèjà ìgbàgbọ́ rẹ̀ nílé ẹjọ́ gíga ti Jakarta, wọ́n sì dá a sílẹ̀ lómìnira.

Nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ọdún lẹ́yìn náà, ìjọba ilẹ̀ Indonéṣíà tún fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ni agbẹjọ́rò agbègbè Manado tó wà ní North Sulawesi bá pe André wá sí ọ́fíìsì rẹ̀ ó sì sọ fún un pé: “Ṣé o mọ̀ pé ìjọba ti fòfin de ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ yìí?”

André dáhùn pé: “Mo mọ̀ bẹ́ẹ̀.”

Agbẹjọ́rò náà ní, “Ṣé o ti wá múra tán láti yí ẹ̀sìn rẹ pa dà báyìí?”

André kọjú sí ọ̀gá náà, ó fọwọ́ sọ̀yà, ó sì fìgboyà sọ pé: “Bí iná ń jó bí ìjì ń já, mi ò ní fi Jèhófà sílẹ̀ láé.”

Agbẹjọ́rò náà ní kí André máa lọ, látìgbà náà ni kò ti dà á láàmú mọ́.

Lọ́dún 2000, André kú ní ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́rin [85], lẹ́yìn tó ti fìtara ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún nǹkan bí ọgọ́ta [60] ọdún.