Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016

 INDONÉṢÍÀ

Bá A Ṣe Ń Wàásù Láyé Ọjọ́un

Bá A Ṣe Ń Wàásù Láyé Ọjọ́un

A Wàásù Lórí Rédíò

LỌ́DÚN 1933, àwọn ará ṣètò pé kí ilé iṣẹ́ ìròyìn kán ní ìlú Jakarta máa bá wa gbé àwọn àsọyé Arákùnrin Rutherford sáfẹ́fẹ́. Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n fi sọ àwọn àsọyé yìí, àmọ́ wọ́n ní kí ọkùnrin kan tó ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa bá wa ka àwọn àsọyé náà sáfẹ́fẹ́ lédè Dutch. Èyí mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí sì jẹ́ káwọn ará fi ìwé tó pọ̀ sóde.

Ọ̀kan lára àwọn àsọyé Arákùnrin Rutherford tá a gbé sáfẹ́fẹ́ ni “Àbájáde Ọdún Mímọ́ Lórí Àlàáfíà àti Aásìkí.” Àsọyé yìí sọ ojú abẹ níkòó, ó sì wọni lọ́kàn gan-an. Nígbà táwọn àlùfáà Kátólíìkì gbọ́ àsọyé yìí, orí wọn gbóná, wọn ò lè mún-un mọ́ra mọ́. * Ni wọ́n bá rán àwọn ìsọ̀ǹgbè wọn pé kí wọ́n gbé ọ̀rọ̀ Arákùnrin De Schumaker relé ẹjọ́ torí pé òun ló máa ń mú rẹ́kọ́ọ̀dù àsọyé náà wá. Wọ́n fẹ̀sùn kàn án pé ó sọ̀rọ̀ àwọn láìdáa, ó fi àwọn ṣe yẹ̀yẹ́, ó tún mú káwọn èèyàn máa fojú burúkú wo àwọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Arákùnrin De Schumaker sapá láti gbèjà ara rẹ̀ nílé ẹjọ́, wọ́n pàpà ní kó sanwó ìtanràn tó jẹ́ guilders mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25], * kó sì tún san owó ẹjọ́. Ìwé ìròyìn mẹ́ta tó gbajúmọ̀ ló ròyìn ẹjọ́ yìí, èyí sì jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú yẹn.

 Ọkọ̀ Ojú Omi Tá A Pè Ní Lightbearer

Àjọ Watch Tower ni ọkọ̀ ojú omi kan tí ó gùn tó mítà mẹ́rìndínlógún [16] tí wọ́n pè ní Lightbearer. Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí ọkọ̀ yìí lò lójú agbami láti ìlú Sydney ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, ó dé sí Jakarta ní July 15, 1935. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà onítara méje ló wà nínú ọkọ̀ náà, ara wọn sì ti wà lọ́nà láti wàásù ìhìn rere náà ní Indonéṣíà, Singapore àti Màléṣíà.

 Fún èyí tó ju ọdún méjì lọ làwọn aṣáájú-ọ̀nà tó ń lo ọkọ̀ ojú omi Lightbearer fi lọ sáwọn èbúté tó tóbi àtàwọn tó kéré tó wà káàkiri orílẹ̀-èdè Indonéṣíá, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì pín kúrò ní kèrémí. Arábìnrin Jean Deschamp ròyìn ohun tí wọ́n máa ń ṣe tí ọkọ̀ náà ba ti dé èbúté kékeré kan, ó ní: “Àá tan ẹ̀rọ giramafóònù wa, àsọyé Arákùnrin J. F. Rutherford (tó jẹ́ ààrẹ Watch Tower Society nígbà yẹn) á sì bẹ̀rẹ̀ sí í dún. Nígbà táwọn ará abúlé Malay rí ọkọ̀ gàràjì yìí, tí wọ́n tún ń gbọ́ ohùn ketekete láti inú afẹ́fẹ́, àwòyanu ni wọ́n ń wò ó torí wọn ò rírú ẹ̀ rí. Ńṣe ni wọ́n ń wo ọkọ̀ náà bíi pé ó jábọ́ látọ̀run.”

Ìgboyà táwọn arákùnrin yìí fi ń wàásù bí àwọn olórí ẹ̀sìn nínú gan-an, ni wọ́n bá sún àwọn aláṣẹ láti fòfin de ọkọ̀ Lightbearer pé kó má wá sí àwọn èbúté Indonéṣíá mọ́. Ọkọ̀ yìí pa dà sí Ọsirélíà ní December 1937. Àmọ́, ṣe lọ̀rọ̀ náà dà bí ohun tí wọ́n máa ń sọ pé bí onírèsé ò tiẹ̀ fíngbá mọ́, èyí tó ti fín sílẹ̀ kò lè pa run. Iṣẹ́ ribiribi táwọn míṣọ́nnárì yẹn ṣe kò ní kúrò nínú ìtàn Indonéṣíà láéláé.

Àwọn tó wà nínú ọkọ̀ Lightbearer

^ ìpínrọ̀ 2 Àsọyé Arákùnrin Rutherford yẹn tú àṣírí àwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì nípa bí wọ́n ṣe ń fi irọ́ kọ́ni, tí wọ́n ń lọ́wọ́ nínú ìṣèlú àti bí wọ́n ṣe gbájú mọ́ òwò ṣíṣe.

^ ìpínrọ̀ 2 Tí ó jẹ́ nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] dọ́là ti Ilẹ̀ Amẹ́ríkà.