BÍ ÒWÒ epo rọ̀bì ṣe wọ́pọ̀ lóde òní ni òwò àwọn èròjà amóúnjẹ-ta-sánsán ṣe gbayé kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, owó gọbọi làwọn ará Yúróòpù fi ń ra àwọn èròjà yìí, àwọn bí èròjà nutmeg àti òdòdó olóòórùn dídùn tí wọ́n ń pè ní cloves. Erékùṣù Spice Islands ni wọ́n sì ti máa ń rí àwọn èròjà náà, (erékùṣù yẹn la wá mọ̀ sí ẹkùn ìpínlẹ̀ Maluku àti North Maluku báyìí lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà).

Àwọn olùṣèwádìí bíi Christopher Columbus, Vasco da Gama, Ferdinand Magellan, Samuel de Champlain àti Henry Hudson wá ọ̀nà láti dé erékùṣù Spice Islands. Ohun tí wọ́n sì wá lọ ni àwọn èròjà amóúnjẹ-ta-sánsán ti Indonéṣíà. Ìrìn àjò yẹn ló jẹ́ kí ẹ̀dà èèyàn wá mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí ilẹ̀ ayé wa ṣe rí fún ìgbà àkọ́kọ́.