Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016

 INDONÉṢÍÀ

Iṣẹ́ Náà Gbòòrò dé Ìlà Oòrùn

Iṣẹ́ Náà Gbòòrò dé Ìlà Oòrùn

Lọ́dún 1953, wọ́n sọ Arákùnrin Peter Vanderhaegan di alábòójútó àyíká ní orílẹ̀-èdè Indonéṣíà. Gbogbo orílẹ̀-èdè náà ni àyíká tó ń bẹ̀ wò, ó fẹ̀ tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún lé ní ọgọ́rùn-ún [5,100] kìlómítà láti ìlà oòrùn sí ìwọ̀ oòrùn àti ẹgbẹ̀rún kan lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [1,800] kìlómítà láti àríwá sí gúúsù. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń ní àwọn ìrírí tó báni lẹ́rù gan-an lẹ́nu ìrìn-àjò náà.

Arákùnrin Peter Vanderhaegen

Ní ọdún 1954, Arákùnrin Vanderhaegan rin ìrìn-àjo lọ sí àpá ìlà-oòrùn Indonéṣíà táwọn onísìn pọ̀ sí lóríṣiríṣi. Ó dé àwọn erékùṣú Bali táwọn ẹlẹ́sìn Hindu pọ̀ sí àti erékùṣù Lombok àti Sumbawa níbi táwọn Mùsùlùmí ti pọ̀ gan-an. Ó tún dé ìlú Flores táwọn èèyàn ibẹ̀ jẹ́ Kátólíìkì,  ó sì ṣiṣẹ́ wọ ìlú Sumba, Alot àti Timor táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì míì pọ̀ sí. Ọkọ̀ ojú omi hẹ́gẹhẹ̀gẹ kan báyìí ló fi rin ìrìn-àjò náà, ó sì ń wàásù ní àwọn erékùṣú kéékèèké tí wọ́n gbà kọjá títí tó fi dé Kupang tó jẹ́ olú ìlú Timor. Arákùnrin Vanderhaegan sọ pé: “Ọ̀sẹ̀ méjì ni mo fi wàásù ní Timor. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣe ni òjò ń rọ̀ gan-an, gbogbo ìwé mi ni mo pín tán, àwọn mẹ́rinlélọ́gbọ̀n [34] gba àsansílẹ̀ ìwé ìròyìn, mo sì bẹ̀rẹ̀ ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe pa dà lọ láti máa bá àwọn èèyàn náà kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì dá ìjọ sílẹ̀ ní Kupang. Láti Kupang, ìhìn-rere náà gbòòrò dé àwọn erékùṣù tó wà nítòsí bí erékùṣù Rotè, Alor, Sumba àti Flores.

Nígbà táwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì tó wà ní Kupang rí i pé àwọn ọmọ ìjọ wọn ń fetí sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, inú bí wọn. Lára àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni bàbá àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Thomas Tubulau tó jẹ́ alápá kan tó ń ṣiṣẹ́ ayọ́, garawa àti bàsíà. Àlùfáà àgbà ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó sì pàṣẹ fún un pé kó gbọ́dọ̀ bá àwọn Ẹlẹ́rìí kẹ́kọ̀ọ́ mọ́, kò sì gbọ́dọ̀ sọ ohun tó ń kọ́ fáwọn èèyàn, àti pé bí kò bá jáwọ́ ẹ̀mí lè lọ sí i. Tìgboyàtìgboyà ni Thomas fèsì pé: “Kò sí Kristẹni tòótọ́ kan tó máa sọ nǹkan tó o sọ yẹn, mi ò tún tẹ ṣọ́ọ̀ṣì rẹ mọ́ látòní lọ.” Thomas di akéde tó ń fi ìtara wàásù, ọmọbìnrin rẹ̀ náà sì di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.

Àwọn olórí ẹ̀sìn ní Timor pinnu pé àwọn gbọ́dọ̀ rẹ́yin àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Torí náà, lọ́dún 1961, wọ́n fúngun mọ́ Ilé Iṣẹ́ Ètó Ẹ̀sìn àtàwọn sójà tó ń darí ìlú náà pé kí wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Nígbà tọ́rọ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ará yí bí wọ́n ṣe ń wàásù pa dà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù fáwọn èèyàn níbi ọjà, fáwọn tó wá pọnmi létí kànga, fáwọn apẹja ní etídò àti fáwọn tó wá síbi itẹ́ òkú. Lẹ́yìn oṣù kan, ìjọba ológun dẹwọ́ lórí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì kéde lórí rédíò pé gbogbo èèyàn tó wà ní Timor ló lẹ́tọ̀ọ́ àtiṣe ẹ̀sìn yóòwù tí  wọ́n bá fẹ́. Àmọ́, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ẹ̀sìn sọ pé òfin ṣì de ìwàásù ilé-dé-ilé, la bá ní kí wọ́n kọ ohun tí wọ́n sọ sílẹ̀, àmọ́ wọ́n ò ṣe bẹ́ẹ̀. Báwọn ará ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láti ilé dé ilé nìyẹn, tí ẹnikẹ́ni kò sì dí wọn lọ́wọ́.

Nígbà tó di ọdún 1962, Piet àti Nell de Jager pẹ̀lú Hans àti Susie van Vuure tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì dé sí ìlú Papua. Àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sáwọn náà. Kódà, àwọn mẹ́ta tó jẹ́ àlùfáà àgbà wá bá àwọn míṣọ́nnárì náà pé wọn ò gbọ́dọ̀ wàásù níbẹ̀ mọ́, pé kí wọ́n gba ibòmíì lọ. Ní wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í parọ́ mọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé à ń dá wàhálà sílẹ̀ fún ìjọba, bí wọ́n ti ń sọ bẹ́ẹ̀ fáwọn ọmọ ìjọ wọn náà ni wọ́n ń gbé e jáde nínú ìwé ìròyìn àti lórí rédíò. Wọ́n pàrọwà fún àwọn ọmọ ìjọ wọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn míṣọ́nnárì pé wọn ò gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ mọ́, wọ́n halẹ̀ mọ́ àwọn míì, wọ́n sì fún àwọn míì lówó kí wọ́n bàa lè ṣíwọ́ ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́. Wọ́n tún lọ bá àwọn baálẹ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn ará wa wàásù ní abúlé wọn.

Àmọ́ ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ nígbà tí baálẹ̀ kan pe àwọn míṣọ́nnárì náà pé kí wọ́n wá bá àwọn èèyàn abúlé òun sọ̀rọ̀. Arákùnrin Hans ròyìn pé: “Lẹ́yìn tí baálẹ̀ yìí pe àwọn ará abúlé jọ, èmi àti Piet sọ àsọyé ṣókí méjì láti ṣàlàyé iṣẹ́ wa. Àwọn ìyàwó wa sì ṣe àṣefihàn bí a ṣe ń wàásù fún àwọn èèyàn láti ilé dé ilé. Baálẹ̀ àtàwọn ará abúlé náà gbádùn ọ̀rọ̀ wa, wọ́n sì fún wa láyè láti máa bá iṣẹ́ wa lọ láìsí ìdíwọ́.”

Léraléra ni irú àwọn nǹkan báyìí ń ṣẹlẹ̀. Àwọn Mùsùlùmí ò fi bẹ́ẹ̀ ta ko iṣẹ́ ìwáásù wa, àfi àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ló ń ṣàtakò ṣáá. Bọ́rọ̀ sì ṣe rí títí dòní nìyẹn.

‘Wọ́n Fà Wá Lọ Síwájú Àwọn Gómìnà . . . Láti Ṣe Ẹ̀rí’

Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Wọn yóò fà yín lọ síwájú àwọn gómìnà àti àwọn ọba nítorí mi, láti ṣe ẹ̀rí  fún wọn àti fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mát. 10:18) Àìmọye ìgbà ni ọ̀rọ̀ yìí ti ṣẹ ní Indonéṣíà.

Ní ọdún 1960, gbajúgbajà ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn tó jẹ́ ará Dutch kan tẹ ìwé kan tó ti pe àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní wòlíì èké. Ìwé yìí ló wá di ohun táwọn àlùfáà bẹ̀rẹ̀ sí í lò láti gbógun ti àwa Ẹlẹ́rìí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn olórí ìsìn kọ̀wé sí Ilé Iṣẹ́ Ètò Ẹ̀sìn pé àwọn Ẹlẹ́rìí ń “da orí àwọn ọmọ ìjọ àwọn rú.” Nígbà táwọn aláṣẹ pè wá láti wá sọ tẹnu wa, àwọn ará lo àǹfààní yẹn láti jẹ́ káwọn èèyàn náà mọ ìdí ọ̀rọ̀ yẹn gan-an, wọ́n sì tún jẹ́rìí fún wọn. Ọ̀kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba yẹn wá sọ pé: “Ẹ wò ó, ẹ jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣe iṣẹ́ wọn, ó ṣe tán, ṣe làwọn ọmọ ìjọ wọ̀nyẹn ń sùn tẹ́lẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí sì ń ta wọ́n jí.”

Níbi tí wọ́n ti ń já ẹrù ìwé Párádísè, lọ́dún 1963

 Nígbà tó di ọdún 1964, àwùjọ àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì tún gbé ọ̀rọ̀ yìí lọ sílé ìgbìmọ̀ aṣòfin, wọ́n ní káwọn tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn àtohun tó ń lọ́ nílùú gbọ́ sọ́rọ̀ náà kí wọ́n sì fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹ̀ka ọ́fíìsì bá sọ pé kí wọ́n gba àwọn láyè láti wá gbèjà ara àwọn níwájú ìgbìmọ̀ náà. Arákùnrin Tagor Hutasoit sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ náà, ó ní: “Fún nǹkan bí wàkátì kan la fi wà níwájú ìgbìmọ̀ náà tá à ń ṣàlàyé báa ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀kan lára àwọn olóṣèlú tó jẹ́ oníṣọ́ọ̀ṣì wà níbẹ̀, ó sì fẹ̀sùn kàn wá pé à ń dá wàhálà ẹ̀sìn sílẹ̀ ní Papua. Mùsùlùmí làwọn tó pọ̀ jù nínú ìgbìmọ̀ náà, wọ́n sì lóye àlàyé wa dáadáa, wọn ò fi igbá kan bọ̀kan nínú. Wọ́n sọ fún wa pé: ‘Òfin ilẹ̀ yìí fàyè gba òmìnira ẹ̀sìn, torí náà, ẹ máa bá iṣẹ́ ìwàásù yín lọ.’ ” Lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ yìí, òṣìṣẹ́ ìjọba kan tó jẹ́ ọ̀gá àgbà ní Papua kéde pé: “Ìjọba tuntun yìí gba àwọn èèyàn láyè láti ṣe ẹ̀sìn tí wọ́n bá fẹ́, ì báà jẹ́ ẹ̀sìn tuntun tàbí ti àtijọ́.”