Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016

 INDONÉṢÍÀ

Ọ̀gá Àwọn Jàǹdùkú Di Ọmọlúwàbí

Hisar Sormin

Ọ̀gá Àwọn Jàǹdùkú Di Ọmọlúwàbí
  • WỌ́N BÍ I NÍ 1911

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1952

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ọ̀gá àwọn jàǹdùkú tó di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka.

LỌ́JỌ́ kan, Ọ̀gá Àwọn Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ pe Arákùnrin Sormin pé kó wá rí òun ní ọ́fíìsì adájọ́ àgbà ti orílẹ̀-èdè náà.

Ọ̀gá náà sọ pé: “Ọmọ ilẹ̀ Indonéṣíà ni ẹ́, àbí? Sòótọ́ fún mi, kí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà gan-an?”

Arákùnrin Sormin dáhùn pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ kí n sọ ìtàn ara mi fún un yín. Ṣé ẹ rí i, ọ̀gá àwọn jàǹdùkú ni mí tẹ́lẹ̀. Àmọ́ ní báyìí, mò ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe níbí nìyẹn, wọ́n ń sọ àwọn èèyànkéèyàn bíi tèmi di ọmọlúwàbí.”

Ọ̀gá Àwọn Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ yìí wá kéde pe: “Àìmọye ẹ̀sùn láwọn èèyàn máa fi ń kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣùgbọ́n mo mọ̀ pé ẹ̀sìn tòótọ́ lẹ̀sìn yìí nítorí ó jẹ́ kí Ọ̀gbẹ́ni Sormin yí pa dà.”

Mọ Púpọ̀ Sí I

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Báwo Ni Àlàáfíà Ṣe Máa Wà ní Ayé?

Kọ́ nípa ìlérí Ọlọ́run láti mú àlàáfíà wá sí ayé nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀.