Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016

 INDONÉṢÍÀ

Ó Mọyì Ọrọ̀ Tẹ̀mí

Thio Seng Bie

Ó Mọyì Ọrọ̀ Tẹ̀mí
  • WỌ́N BÍ I NÍ 1906

  • ṢÈRÌBỌMI NÍ 1937

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Alàgbà tó fi ìṣòtítọ́ fara da ìjà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà.—Gẹ́gẹ́ bí Thio Sioe Nio ọmọ rẹ̀ ṣe sọ ọ́.

RÒGBÒDÌYÀN kan ṣẹlẹ̀ ní West Java ní May 1963. Àwọn èèyàn yarí pé àwọn ò fẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ṣáínà kankan nílùú mọ́. Ìlú Sukabumi ni wàhálà náà pọ̀ sí jù, ibẹ̀ sì ni ìdílé wa ń gbé tá a ní àwọn ọkọ̀ akẹ́rù tó ń ná ọ̀nà. Lọ́jọ́ kan, ṣe ni èrò rẹpẹtẹ rọ́ gìrìgìrì dé, títí kan àwọn ará àdúgbò wa, tí wọ́n sì fi agbára jálẹ̀kùn wọnú ilé wa. Ẹ̀rù bà wá gan-an, la bá ká gúlútú sí kọ́nà kan nínú ilé wa, a sì ń wò báwọn ọ̀bàyéjẹ́ yìí ṣe ń ba àwọn nǹkan wa jẹ́ tí wọ́n sì kó àwọn ẹrù wa lọ.

Nígbà tí wọ́n lọ tán, àwọn míì lára àwọn aládùúgbò wa wá láti tù wá nínú. Ilẹ̀ẹ́lẹ̀ nínú pálọ̀ ni bàbá mi jókòó sí pẹ̀lú wọn. Ibẹ̀ ni bàámi ti tajú kán rí Bíbélì rẹ̀ láàárín àwọn ẹrù táwọn èèyàn náà bà jẹ́. Bàbá mi ka ibi kan fún àwọn alábàárò náà, pé Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé irú àwọn nǹkan yìí máa ṣẹlẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó ṣàlàyé ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa tó ṣe fáráyé.

Bàbá mi ò nífẹ̀ẹ́ sí kéèyàn máa kó ọ̀rọ̀ ayé yìí jọ. Ìgbà gbogbo ló máa ń sọ fún wá pé: “Àwọn nǹkan tó jẹ́ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run ni kẹ́ ẹ máa fi síwájú.” Ọpẹ́lọpẹ́ àpẹẹrẹ rere tí bàámi mi fi lélẹ̀, àwa ọmọ rẹ̀ mẹ́fà la di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Yàtọ̀ sáwa ọmọ, màámi, àwọn ìbátan wa, bàámi àgbà tó ti lé láàádọ́rùn-ún [90] ọdún àtàwọn aládùúgbò wa náà tún di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.