• WỌ́N BÍ I NÍ 1928

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1941

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó jẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ka Indonéṣíà fún ohun tó lé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25].

LÁÀÁRỌ̀ kùtùkùtù October 1 ọdún 1965, àwọn kan lára Ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì Ilẹ̀ Indonéṣíà (PKI) tó fẹ́ fipá gbàjọba pa mẹ́fà lára àwọn ọ̀gágun orílẹ̀-èdè náà. Kíá ni ìjọba ti gbé àwọn ọmọ ogun dìde sáwọn tó ṣọṣẹ́ náà, wọ́n sì fìjà pẹẹ́ta. Ogun náà gbóná débi pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500,000] ọmọ ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì ló ṣòfò ẹ̀mí nínú “ìjà àjàkú-akátá” náà.

Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ọ̀gá ológun kan ta mí lólobó pé orúkọ mi wà lára àwọn olórí ẹ̀sìn táwọn ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì ń gbèrò láti pa. Ó tiẹ̀ ní kí n wá lọ wo sàréè tí wọ́n gbẹ́ sílẹ̀ fún mi. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, àmọ́ mo ní kó má ṣèyọnu. Ìlú ń gbóná nígbà yẹn, mi ò sì fẹ́ káwọn èèyàn rí mi pẹ̀lú ọ̀gágun yìí, kí wọ́n wá máa rò pé mò ń lọ́wọ́ nínú ìṣèlú.