Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016

Ìjọ Surabaya, 1954

 INDONÉṢÍÀ

Àwọn Míṣọ́nnárì Láti Gílíádì Dé

Àwọn Míṣọ́nnárì Láti Gílíádì Dé

Ní July 1951, ìjọ kékeré tó wà ní ìlú Jakarta kóra jọ láti ki Arákùnrin Peter Vanderhaegen káàbọ̀. Òun ni míṣọ́nnárì àkọ́kọ́ tó máa wá láti Gílíádì sí Indonéṣíà. Ìgbà tí ọdún yẹn fi máa parí, míṣọ́nnárì mẹ́tàlá ló ti dé láti Ọsirélíà, Jámánì àti Netherlands. Èyí mú kí iye àwọn akéde tó wà ní orílẹ̀-èdè Indonéṣíà fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì.

Arábìnrin Fredrika Renskers tó wá láti ilẹ̀ Netherlands sọ pé: “Tẹ́lẹ̀, mo rò pé tí mo bá ń wàásù láti ilé dé ilé, ṣe ni màá máa fi ọwọ́ ṣàpèjúwe káwọn èèyàn tó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Àmọ́, nígbà tí mo rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn ará ibẹ̀ ń sọ èdè Dutch, mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi Dutch bá wọn sọ̀rọ̀.” Arákùnrin Ronald Jacka tó wá láti Ọsirélíà sọ pe: “Àwọn kan lára wa máa ń lo káàdì tá a kọ ọ̀rọ̀ ìwàásù ṣókí sí lédè Indonesian. Kí n tó kan ilẹ̀kùn ilé kan, màá wo káàdì náà kí ń lè há ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sórí.”

Bí àwọn míṣọ́nnárì yìí ṣe ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù mú kí iye àwọn akéde gbèrú, tó fi jẹ́ pé láàárín ọdún kan péré akéde mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34] di mọ́kànléláàádọ́rùn-ún [91]! Ní September 1, 1951, ètò Ọlọ́run ṣí ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower Society sí ilé Arákùnrin André Elias ní Central Jakarta, wọ́n sì ní kí Arákùnrin Ronald Jacka jẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ka.

Ìhìn Rere De Àwọn Ìpínlẹ̀ Tuntun

Ní November 1951, wọ́n gbé Arákùnrin Peter Vanderhaegen lọ sí Manado ní North Sulawesi níbi tí Theo Ratu àti ìyàwó rẹ̀ ti dá àwùjọ kékeré kan sílẹ̀. Àwọn èèyàn ìlú yìí gbà pé Kristẹni làwọn, wọ́n sì fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an. Àìmọye èèyàn ló máa ń ní káwọn Ẹlẹ́rìí wọlé, kí wọ́n wá ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì fún àwọn. Níbẹ̀rẹ̀, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan lè máa bá ẹni mẹ́wàá sọ̀rọ̀. Àmọ́ tó bá fi máa tó ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún,  àwọn èèyàn náà á ti tó àádọ́ta [50], kó tó tó wákàtí kan, àwọn èèyàn náà á ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún méjì [200]. Ìyẹn á wá gba pé kí wọ́n wá ibi tó tẹ́jú níta láti jókòó.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1952, Arákùnrin Albert Maltby àti ìyàwó rẹ̀ Jean fi ilé tí wọ́n ń gbé ṣe ilé àwọn míṣọ́nnárì. Ìlú Surabaya ní East Java ni ilé náà wà, ìlú yìí ló sì tóbi ṣìkejì ní orílẹ̀-èdè Indonéṣíà. Kò pẹ́ tí àwọn arábìnrin mẹ́fà táwọn náà jẹ́ míṣọ́nnárì dara pọ̀ mọ́ wọn. Orúkọ àwọn arábìnrin náà ni Gertrud Ott, Fredrika Renskers, Susie àti Marian Stoove, Eveline Platte àti Mimi Harp. Ọ̀kan lára wọn, ìyẹn Fredrika Renskers sọ pé: “Mùsùlùmí ni àwọn tó pọ̀ jù nílùú náà, àmọ́  wọn ò ní ká má bá àwọn sọ ọ̀rọ̀ Bíbélì, ara wọn sì yá mọ́ọ̀yàn. Ó jọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn lara wọn ti wà lọ́nà láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, torí bẹ́ẹ̀, kò nira rárá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láàárín ọdún mẹ́ta péré, ìjọ Surabaya ti ní akéde márùndínlọ́gọ́rin [75].”

Ilé àwọn míṣọ́nnárì ní Jakarta

Láàárín àkòkò yẹn, ọkùnrin Mùsùlùmí kan tó ń jẹ́ Azis tó wá láti ìlú Padang ní West Sumatra kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fí ìsì pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́ láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Láàárín ọdún 1931 sí 1939 ló ti kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn aṣáájú-ọ̀nà kan tó wá láti Ọsirélíà. Àmọ́, nígbà tí rògbòdìyàn ogun ilẹ̀ Japan bẹ́ sílẹ̀ ni kò gbúròó àwọn aṣáájú-ọ̀nà náà mọ́. Lọ́jọ́ kan, ó rí ọ̀kan lára ìwé pẹlẹbẹ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe. Ó wá sọ pé: “Nígbà tí mo rí àdírẹ́sì ẹ̀ka ọ́fí ìsì Jakarta tó wà níbẹ̀, inú mi dùn, ṣe lò dà bíi pé eéwo mi tú.” Kíá ni ẹ̀ka ọ́fí ìsì rán alábòójútó àyíká kan tó ń jẹ́ Frans van Vliet sí Padang. Ìgbà tí Frans débẹ̀ ló rí i pé Azis ti wàásù fun aládùúgbò rẹ̀ kan tó ń jẹ́ Nazar Ris. Òṣìṣẹ́ ìjọba kan tó ń wá ẹni tó máa kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Nazar Ris. Bó ṣe di pé àwọn méjèèjì àti ìdílé wọn di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn o. Nígbà tó yá, arákùnrin Azis di alàgbà, Arákùnrin Nazar Ris sì di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ rẹ̀ ló tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, tí wọ́n ń ṣe dáadáa nínú ètò Ọlọ́run.

Frans van Vliet àti àbúrò rẹ̀ obìnrin tó ń jẹ́ Nel

Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí Arákùnrin Frans van Vliet ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ arákùnrin kan tó ti di aláìṣiṣẹ́mọ́. Ọmọ ilẹ̀ Netherlands ni arákùnrin yìí, òun ló ń ṣàtúnṣe ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń fọ epo rọ̀bì kan tí ogun bà jẹ́ nílùú Balikpapan ní East Kalimantan. Arákùnrin Frans àti arákùnrin yìí jọ lọ wàásù, ó sì rọ̀ ọ́ pé kó máa kọ́ àwọn tó fi ìfẹ́ hàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí arákùnrin yìí tó pa dà sí Netherlands, ó ti dá àwùjọ kékeré kan sílẹ̀ ní Balikpapan.

Nígbà tó yá, arábìnrin kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣèrìbọmi ṣí lọ sí ìlú Banjarmasin ní South Kalimantan. Titi Koetin lorúkọ rẹ̀. Titi wàásù fún àwọn ìbátan rẹ̀ tó ń gbé nílùú Dayak, ó sì kọ́ ọ̀pọ̀ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Lára wọn kó pa dà sí àwọn abúlé wọn ní ẹ̀yìn odi Kalimantan, wọ́n sì dá àwọn àwùjọ sílẹ̀. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, àwọn àwùjọ náà di àwọn ìjọ ńlá.

 A Ń Tẹ Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ ní Èdè Indonesian

Bí iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe ń tàn kálẹ̀ sí i làwọn ará ń nílò àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lédè Indonesian tó pọ̀ sí i. Ní ọdún 1951, wọ́n tú ìwé náà “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ” sí èdè Indonesian, àmọ́ nígbà tó yá, ìjọba ṣàtúnṣe sí bí wọ́n ṣe ń kọ a, b, d wọn sílẹ̀, èyí sì mú kó pọn dandan fún ẹ̀ka ọ́fíìsì láti tún ìwé náà ṣe. * Nígbà tí ìwé náà máa jáde lákọ̀tun, ńṣe làwọn èèyàn Indonéṣíà tí wọ́n fẹ́ràn àtimáa kàwé gbajó.

Ní 1953, ẹ̀ka ọ́fíìsì tẹ ẹ̀dà àádọ́ta-lérúgba [250] Ile-Iṣọ Na ní èdè Indonesian, ìyẹn sì ni ìgbà àkọ́kọ́ tá a máa tẹ ìwé ìròyìn náà jáde nílẹ̀ Indonéṣíà láti nǹkan bí ọdún méjìlá. Ojú ìwé méjìlá [12] ni ìwé ìròyìn tá a dà kọ yìí ní, àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ nìkan ló sì wà níbẹ̀ nígbà tá a kọ́kọ́ tẹ̀ ẹ́ jáde. Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, ó di olójú-ewé mẹ́rìndínlógún [16], ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé kan sì ń bá wa tẹ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] lóṣooṣù.

Ọdún 1957 la bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ Ji! jáde lédè Indonesian. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, iye tá à ń tẹ̀ jáde lóṣooṣù ti tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá  [10,000]. Nígbà tí bébà ìtẹ̀wé wọ́n, àwọn ará ní láti gbàwé àṣẹ kí wọ́n lè máa kó bébà ìtẹ̀wé wọlé láti ilẹ̀ òkèèrè. Òṣìṣẹ́ ìjọba tó bá wa ṣe ìwé àṣẹ wa sọ pé: “Lójú tèmi, Menara Pengawal (Ile-Iṣọ Na) jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé ìròyìn tó dáa jù lọ ní Indonéṣíà. Màá ṣe gbogbo ohun tó yẹ kẹ́ ẹ lè rí ìwé àṣẹ gbà láti tẹ ìwé yin tuntun jáde.”

^ ìpínrọ̀ 1 Lẹ́yìn ọdún 1945, ó ti di ẹ̀ẹ̀mejì ti ìjọba ti ṣàtúnṣe sí bí wọ́n ṣe ń kọ a, b, d èdè Indonesian torí wọ́n kò fẹ́ máa lo a, b, d èdè Dutch tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀.