Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016

 INDONÉṢÍÀ

Lábẹ́ Àjàgà Ìjọba Ilẹ̀ Japan

Lábẹ́ Àjàgà Ìjọba Ilẹ̀ Japan

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1942, àwọn àkòtagìrì ẹgbẹ́ ọmọ ogun Japan wá kógun ja orílẹ̀-èdè Indonéṣíà, wọ́n sì gbàjọba mọ́ wọn lọ́wọ́. Ìjọba ológun yìí fojú àwọn ará wa rí màbo, wọ́n fipá mú wọn ṣe iṣẹ́ àgbára. Wọ́n lè ní káwọn kan la ọ̀nà, tàbí kí wọ́n kó gọ́tà. Wọ́n fi àwọn míì sáwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n tó dọ̀tí gan-an, wọ́n tún dá wọn lóró torí wọn kò lọ́wọ́ sí ogun. Ó kéré tán, àwọn ará mẹ́ta ló kú sẹ́wọ̀n.

Johanna Harp àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjì pẹ̀lú Beth Godenze tó jẹ́ ọ̀rẹ́ ìdílé wọn (láàárín)

Arábìnrin Johanna Harp tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Netherlands àti àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́ta tí ò tíì pé ogún ọdún ló  ṣèrànwọ́ láti tú ìwé Salvation àti àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ láti Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Dutch nígbà ogun yẹn. * Abúlé kan tó wà ní àdádó ní East Java ni wọ́n ń gbé, èyí ni kò jẹ́ kí wọ́n rí wọn fi sẹ́wọ̀n fún odindi ọdún méjì àkọ́kọ́ tí ogun fi jà. Àwọn ìwé tí wọ́n tú ni àwọn ará dà kọ tí wọ́n sì ń pín ní bòókẹ́lẹ́ fáwọn Ẹlẹ́rìí tó wà káàkiri Java.

Ìwọ̀nba àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọn ò sí lẹ́wọ̀n máa ń ṣe ìpàdé ní àwùjọ kéékèèké, wọ́n sì ń fọgbọ́n wàásù. Josephine Elias (tó ń jẹ́ Tan tẹ́lẹ̀) wà lára wọn, ó ní: “Gbogbo ọ̀nà ni mo máa ń wá láti wàásù láìjẹ́-bí-àṣà. Máà gbé ọpọ́n ayò dání lọ sí ilé àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí àwọn èèyàn lè rò pé mo kàn ń tayò ni.” Ńṣe ni Felix Tan àti ìyàwó rẹ̀ tó ń jẹ́ Bola máa ń ṣe bí ẹni ń ta ọṣẹ tí wọ́n bá ń wàásù láti ilé-dé-ilé. Wọ́n sọ pé: “Àwọn òǹrorò sójà tá a ń pè ní Kempeitai máa ń fi àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ṣọ́ wa kiri. Kí wọ́n má bàa fura sí wa, a máa ń yí ìgbà tí a ń lọ wo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa pa dà. Mẹ́fà lára wọn tẹ̀ síwájú, wọ́n sì ṣèrìbọmi nígbà ogun náà.”

Ìyapa Ṣẹlẹ̀ Ní Ìlú Jakarta

Ẹnu wàhálà ogun yìí làwọn ara ṣì wà tí ìdánwò ìgbàgbọ́ míì tún fi yọjú. Àwọn aláṣẹ Japan sọ pé gbogbo àwọn tó wá láti ilẹ̀ òkèèrè gbọ́dọ̀ gba káàdì ìdánimọ̀ pé àwọn ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti wà lábẹ́ ìdarí Ìjọba Japan. Èyí wá mú kí àwọn ará máa béèrè pé ṣé ó tọ́ káwọn gba káàdì yìí àbí kò tọ́?

Josephine Elias pẹ̀lú arákùnrin rẹ̀ tó ń jẹ́ Felix

Arákùnrin Felix Tan sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Àwọn ará ní Jakarta sọ fún àwa tá a wà ní Sukabami pé ká má buwọ́ lu káàdì yìí. Àwa wá béèrè lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ bóyá a lè yí ọ̀rọ̀ inú káàdì náà pa dà, kí ibi tó sọ pe ‘Ẹni tó buwọ́ lu ìwé yìí jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun fara mọ́’ ẹgbẹ́ ológun ilẹ̀ Japan, yí  pa dà di ‘Ẹni tó buwọ́ lu ìwé yìí ṣèlérí pé òun kò ní ṣe ìdíwọ́ fún’ ẹgbẹ́ ológun ilẹ̀ Japan. Sí ìyàlẹ́nu wa, ìjọba gbà pé kà yí àwọn ọ̀rọ̀ náà pa dà, bí gbogbo wa ṣe gba káàdì nìyẹn. Nígbà táwọn ará ní Jakarta gbọ́ ohun tá a ṣe, ńṣe ni wọ́n pè wá ní apẹ̀yìndà, wọn ò sì bá wa ṣe mọ́.”

Ó bani nínú jẹ́ pé nígbà tí ọwọ́ ba àwọn ará Jakarta tó ń rin kinkin mọ́ òfin yìí, ọ̀pọ̀ wọn ló sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn. Arákùnrin kan láti Jakarta tó mú ìdúró rẹ̀ wà ní ẹ̀wọ̀n kan náà pẹ̀lú Arákùnrin André Elias. André sọ pe: “Mo bá a fèrò wérò nípa bóyá kéèyàn forúkọ sílẹ̀ fún káàdì tàbí kó máà ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbà tó yá, òun náà ní èrò tó tọ́. Ó dùn-ún pé òun pa àwa ará ní Sukabomi tì, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì. Àwa méjèèjì jọ gbé ara wa ro lẹ́yìn ìgbà náà, àmọ́ arákùnrin yìí kú sẹ́wọ̀n torí ipò nǹkan le gan-an ní ọgbà ẹ̀wọ̀n náà.”

Merdeka!

Bí ogun ṣe parí lọ́dún 1945, ara àwọn ará ti wà lọ́nà láti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù. Arákùnrin kan tí wọ́n tì mọ́lé tí wọ́n  sì dá lóró lẹ́wọ̀n kọ lẹ́tà sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Ọsirélíà pé: “Mo jìyà púpọ̀ lẹ́wọ̀n fún ọdún mẹ́rin gbáko, àmọ́ èmi tún rèé lónìí. Mo dúpẹ́ pé mi ò sẹ́ ìgbàgbọ́ mi, mi ò sì gbàgbé àwọn ará nínú gbogbo wàhálà mi. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ránṣẹ́ sí mi.”

Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn ìwé ìròyìn tá à ń retí dé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ ló kọ́kọ́ dé, ìgbá tó yá, èyí tó pọ̀ dé. Àwọn akéde mẹ́wàá kan tí wọ́n wà ní Jakarta bẹ̀rẹ̀ sí í tú àwọn ìwé wa sí èdè Indonesian.

Ní August 17, 1945, àwọn òléwájú nínú ọ̀rọ̀ òmìnira ilẹ̀ Indonéṣíà kéde pé orílẹ̀-èdè Indonéṣíà ti di òmìnira, ni èyí bá tún hú wàhálà ọdún mẹ́rin míì sílẹ̀ torí àwọn èèyàn fẹ́ gbara wọn sílẹ̀ lábẹ́ àjàgà àwọn Dutch, ìyẹn ìjọba ilẹ̀ Netherlands. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn kú sí i, ó sì lé ní mílíọ̀nù méje èèyàn tí ó rílé gbé mọ́.

Ní gbogbo ìgbà tí wàhálà yìí ń lọ lọ́wọ́, àwọn ará ń wàásù láti ilé-dé-ilé. Arábìnrin Josephine Elias sọ pé: “Wọ́n fẹ́ fipá mú wa pariwo ‘Merdeka,’ tó túmọ̀ sí ‘Òmìnira,’ ṣùgbọ́n a sọ fún wọn pé àwa kì í dá sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú.” Lọ́dún 1949, àwọn Dutch dá ìjọba tó ti wà lọ́wọ́ wọn látọdúnmọ́dún pa dà fun Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti Ìjọba Àpapọ̀ Indonéṣíà, tá à ń pè ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira Indonéṣíà báyìí. *

Nígbà tó fi máa di ọdún 1950, àwọn ará ní Indonéṣíà ti fara da wàhálà fún ohun tí ó tó ọdún mẹ́wàá. Síbẹ̀, iṣẹ́ ńlá ń bẹ níwájú, báwo ni wọ́n á ṣe wàásù fún àìmọye mílíọ̀nù èèyàn tó ń gbé ní Indonéṣíà? Tá a bá fi ojú èèyàn wò ó, ó dà bí àlá. Àmọ́, àwọn ará fi ìgbàgbọ́ tẹ̀ síwájú, wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé yóò “rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Mát. 9:38) Jèhófà sì ṣe bẹ́ẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 2 Lẹ́yin tí ogun parí, èyí tó kéré jù nínú àwọn ọmọ Arábìnrin Harp, ìyẹn Hermine (Mimi), lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, ó sì pa dà ṣe míṣọ́nnárì ní Indonéṣíà.

^ ìpínrọ̀ 3 Àwọn Dutch ṣì ṣàkóso agbègbè West Papua (tó ń jẹ́ West New Guinea nígbà yẹn) títí di ọdún 1962.