Theodorus Ratu

Lọ́dún 1933, Arákùnrin Frank Rice ní kí Theodorus (Theo) Ratu wá máa bójú tó ibi tá à ń já ìwé ìròyìn sí ní Jakarta. Theo sọ pé: “Iṣẹ́ yẹn mú kí n fẹ́ràn ìwàásù gan-an, mo bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé Arákùnrin Rice lọ wàásù. Nígbà tó yá, mo bá Arákùnrin Bill Hunter wàásù káàkiri nílùú Java, mo sì tún bá àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi Lightbearer rin ìrìn àjò lọ sí Sumatra.” Arákùnrin Theo ni ará Indonéṣíà tó kọ́kọ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ọ̀pọ̀ ọdún ní Java, North Sulawesi àti ní Sumatra.

Ní 1934, Arákùnrin Bill Hunter fi ìwé pẹlẹbẹ Where Are the Dead? lọ ọmọ ilé-ìwé kan tó ń jẹ́ Felix Tan tó ń gbé ní Jakarta. Nígbà tí Felix pa dà sọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ nílùú Bandung ní West Java, ó fi ìwé náà han àbúrò rẹ̀ tó ń jẹ́ Dodo. Ó ya àwọn méjèèjì lẹ́nu nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ láti inú ìwé náà pé Ádámù kò ní àìleèkú ọkàn. (Jẹ́n. 2:7) Èyí mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí i. Torí náà, Felix àti Dodo wá gbogbo ilé ìtàwé tó wà lágbègbè yẹn  bóyá wọ́n á rí àwọn ìwé wa míì kà. Wọ́n sọ ohun tí wọ́n ti kọ́ nínú Bíbélì fáwọn ìdílé wọn. Nígbà tí wọ́n ka gbogbo ìwé wa tí wọ́n rí tán, wọ́n kọ̀wé sí ibi tá à ń já àwọn ìwé wa sí ní Jakarta. Inú wọn dùn nígbà tí Arákùnrin Frank Rice wá fún wọn níṣìírí tó sì tún bá wọn kó àwọn ìwé tuntun wá.

Ìdílé Tan

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí Arákùnrin Rice pa dà sí Jakarta ni Clem àti Jean Deschamp tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó wá lo ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ní Bandung. Felix ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Arákùnrin Deschamp béèrè lọ́wọ́ ìdílé mi bóyá ó wù wá láti ṣe ìrìbọmi, àwa mẹ́rin la ṣèrìbọmi nígbà náà; èmi, màámi, Dodo àti Josephine Pin Nio àbúrò mi.” * Gbogbo àwọn tó ṣe ìrìbọmi nínú ìdílé Tan yìí ló tẹ̀ lé Clem àti Jean lọ wàásù fún odindi ọjọ́ mẹ́sàn-án.  Clem kọ́ wọn bí a ṣe lè lo káàdì ìjẹ́rìí láti wàásù ní èdè mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwùjọ kékeré tó wà ní Bandung di ìjọ kan, òun sì ni ìjọ ìkejì tá a dá sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà.

Fìlà Póòpù

Nígbà táwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kíyè sí i pé iṣẹ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ síwájú, tó sì ń gbilẹ̀, ara ta wọ́n, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n á ṣe dá iṣẹ́ náà dúró. Àwọn àtàwọn alátìlẹyìn wọn bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ òdì nípa iṣẹ́ wa àti ìgbàgbọ́ wa nínú àwọn ìwé ìròyìn. Àwọn aláṣẹ Ilé Iṣẹ́ Ètò Ẹ̀sìn gbọ́ sí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì ránṣẹ́ pe Arákùnrin Frank Rice láti fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò. Àwọn ọ̀rọ̀ tí Frank Rice sọ tẹ́ wọn lọ́rùn, wọ́n sì ní ká máa ba iṣẹ́ wa lọ́ láìdáwọ́ dúró. *

Láàárín ọdún 1931 sí 1934, àwọn aláṣẹ ò dí iṣẹ́ wa lọ́wọ́, àmọ́ nǹkan yí pa dà nígbà tí ìjọba Násì gba àkóso ní àgbègbè Yúróòpù. Àwọn aláṣẹ Násì tó jẹ́ Kátólíìkì bẹ̀rẹ̀ sí í fínná mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Arákùnrin Clem Deschamp ròyìn ohun tí ojú rẹ̀ rí, ó ní: “Aṣọ́bodè kan tó jẹ́ Kátólíìkì ò jẹ́ ká kó àwọn ìwé wa wọ̀lú. Ó ní àwọn ìwé náà sọ̀rọ̀ òdì sí ìjọba Násì. Ìgbà tí mo pe Ilé iṣẹ́ Ibodè pé kí n sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn, wọ́n ní ọ̀gbẹ́ni aṣọ́bodè ọjọ́sí ti lọ sí ọlidé. Ẹlòmíì tí kí ì ṣe Kátólíìkì ló wà níbodè báyìí, ṣe ni ọkùnrin náà fi ọ̀yàyà sọ fún wa pé ká wá kó àwọn ìwé wa, ó ní: ‘Ẹ yáa tètè kó gbogbo ìwé yín kí jagunlabí tó dé.’

Arábìnrin Jean Deschamp sọ nǹkan míì tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Àwọn aláṣẹ ní ká yọ àwòrán kan tó wà nínú ìwé wa tó ń jẹ́ Enemies. Ìwé yìí ní àwòrán ejò tó ń japoró (tó ṣàpẹẹrẹ Sátánì) àti aṣẹ́wó tó ti mutí yó kẹ́ri (tó ṣàpẹẹrẹ ìsìn  èké), àwọn méjèèjì dé fìlà póòpù. * Torí a ti pinnu pé a fẹ́ pín ìwé náà, àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta jókòó sí èbúté láìka ooru tó mú gan-an, a sì ń fi yíǹkì dúdú pa àwòrán náà rẹ́ nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìwé tó wà ńlẹ̀.”

Àwòrán méjì tó wà nínú ìwé Enemies táwọn aláṣẹ ní ká mú kúrò

Bí ogun ṣe ń kóra jọ ní Yúróòpù, bẹ́ẹ̀ làwọn ìwé ìròyìn wa ń tú àṣírí ìwà àgàbàgebè àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì àti bí wọ́n ṣe ń lọ́wọ́ nínú ìṣèlú. Àwọn olórí ìsìn wá ń fínná mọ́ ìjọba kí wọ́n lè fòfin de iṣẹ́ wa. Àìmọye àwọn ìwé ìròyìn wa ni wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé.

Àmọ́ láìka gbogbo èyí sí, ṣe làwọn ará pinnu pé àwọn kò ní dáṣẹ́ dúró. Wọ́n pa dà rí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé kan gbà láti Ọsirélíà, wọ́n sì lò ó fún iṣẹ́ náà. (Ìṣe 4:20) Arábìnrin Jean Deschamp sọ ọ̀kan lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe: “Bá a bá tẹ ìwé tuntun, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ kí wọ́n lè fọwọ́ sí i. Torí náà, a máa ń tẹ ìwé tuntun  látìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀, àá sì dọ́gbọ́n pín in kiri. Tó bá wá di ìparí ọ̀sẹ̀, àá mú ẹ̀dà kan lọ sí ọ́fíìsì amòfin àgbà. Tí wọn ò bá fọwọ́ sí i, àá mirí bíi pé ó dùn wá, lẹ́yìn náà, àá sáré pa dà síbi ìtẹ̀wé ká lè tẹ ìwé tó kàn.”

Oríṣiríṣi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ làwọ́n ará tó ń pín àwọn ìwé yìí máa ń dá kí ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá má bàa tẹ̀ wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, níbi tí Arákùnrin Charles Harris ti ń wàásù lágbègbè Kediri ní East Java, ó ṣèèṣì kan ilẹ̀kùn ilé kan láìmọ̀ pé ọlọ́pàá ló ń gbébẹ̀.

Nígbà tí ọlọ́pàá ṣílẹ̀kùn tó rí i, ó ní: “Ó tiẹ̀ dáa báyìí, mo ti ń wá ẹ kiri látàárọ̀, jẹ́ kí n lọ mú ìwé ti mo kọ orúkọ àwọ́n ìwé yín tá a fòfin dé sí wá.”

Charles sọ pé: “Bí ọlọ́pàá ṣe wọlé lọ wá ìwé rẹ̀, mo sáré wo inú báàgì mi, mo sì kó àwọn ìwé tí wọ́n fòfin dè kúrò, mo rún wọn mọ́ àpò inú kóòtù mi. Bó ṣe dé, mo fún un ní àwọn ìwé pẹlẹbẹ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] tí wọn kò fòfin dè. Ó fìtìjú gbà á, ó sì fi ọrẹ ṣe ìtìlẹ́yìn. Lẹ́yìn tí mo kúrò níbẹ̀, mo fi àwọn ìwé tí mo kó pa mọ́ lọ àwọn míì tó wà ládùúgbò.”

Títẹ̀wé Lákòókò Tí Nǹkan Ò Rọgbọ

Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì le gan-an ní Yúróòpù, a ò lè kó àwọn ìwé ìròyìn wa wọ Indonéṣíà láti Netherlands mọ́. Àmọ́, ọ̀rọ̀ náà ò bá àwọn ará lábo, ṣáájú ìgbà yẹn ni wọ́n ti ṣètò bí ilé iṣẹ́ àdáni kan á ṣe máa báwọn tẹ̀wé ní Jakarta. Wọ́n tẹ ẹ̀dà Consolation (tá a mọ̀ sí Ji! báyìí) àkọ́kọ́ jáde lédè Indonesian ní January 1939, kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí wọ́n tẹ Ilé Ìṣọ́ lédè Indonesian. Nígbà tó yá, àwọn ará ra ẹ̀rọ ìtẹ̀wé kékeré kan, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àwọn ìwé ìròyìn fúnra wọn. Lọ́dún 1940, wọ́n rí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tó tóbi kan gbà láti Ọsirélíà, èyí tí wọ́n fi ń tẹ àwọn ìwé pẹlẹbẹ àti ìwé ìròyìn lédè Indonesian àti Dutch. Owó ara wọn ni wọ́n sì fi ń tẹ àwọn ìwé náà.

Nígbà tí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé àkọ́kọ́ dé sí Jakarta

 Ní July 28 ọdún 1941, ìjọba fòfin de gbogbo ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Arábìnrin Jean Deschamp sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Láàárọ̀ ọjọ́ kan tí mò ń tẹ ìwé lọ́wọ́, ṣàdédé làwọn ọlọ́pàá mẹ́ta já wọlé, àgbà òṣìṣẹ́ ìjọba ilẹ̀ Netherlands kan sì tẹ̀ lé wọn. Ó dì káká-dì-kuku nínú aṣọ oyè rẹ̀, ìmúra rẹ̀ látòkè délẹ̀ fi hàn pé ọ̀gá ńlá kan ni. Àmọ́ kò yà wá lẹ́nu láti rí wọn torí pé ọjọ́ mẹ́ta sẹ́yìn lẹnì kan ti ta wá lólobó pe wọ́n ń bọ̀ wá fòfin de àwọn ìwé wa. Ọ̀gá yìí fi ìgbéraga ka ìkéde jàn-àn-ràn jan-an-ran kan, ló bá ní ká nìṣó ní ilé ìtẹ̀wé wa kí òun lè tì í pa. Ọkọ mi dá a lóhùn pé ó ti pẹ́ jù, torí a ti ta ẹ̀rọ náà látàná!”

Inú wa dùn pé wọn kò fòfin de Bíbélì, torí náà, ṣe làwọn ará wa ń fi Bíbélì nìkan wàásù láti ilé-dé-ilé, wọn sì ń fi darí ìkẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́, nítorí ogun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ ní Éṣíà, wọ́n ní kí àwọn aṣáájú-ọ̀nà tí kì í ṣe ará Indonéṣíà pa dà sí Ọsirélíà.

^ ìpínrọ̀ 1 Nígbà tó yá, bàbá Felix àtàwọn àbúrò rẹ̀ mẹ́ta di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àbúrò rẹ̀ tó ń jẹ́ Josephine ló fẹ́ André Elias, àwọn méjèèjì sì lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ìtàn ìgbésí ayé Josephine wà nínú Jí! September 2009 lédè Gẹ̀ẹ́sì.

^ ìpínrọ̀ 1 Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì parí, ó pa dà sí Ọsirélíà, ó gbéyàwó, ó sì bímọ. Arákùnrin Rice parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lọ́dún 1986.

^ ìpínrọ̀ 3 Ohun tó wà nínú Ìṣípayá 12:9 àti 17:3-6 la gbé àwọn àwòrán náà kà.