Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Wọ́n ń wàásù ní ọjà kan ní Jakarta

 INDONÉṢÍÀ

Iṣẹ́ Wa Ń Tẹ̀ Síwájú

Iṣẹ́ Wa Ń Tẹ̀ Síwájú

Nígbà táwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì gbọ́ pé wọ́n ti fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lómìnira láti máa jọ́sìn bá a ṣe fẹ́, orí wọn gbóná, àfi bíi pé iná jó wọn. Àwọn àlùfáà tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje [700] wá láti ṣọ́ọ̀ṣì méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pẹ̀lú àwọn bàbá ìjọ àti ìyá ìjọ wọn, wọ́n kóra jọ láti ṣèpàdé ní Jakarta pé àwọn fẹ́ kí ìjọba tún fòfin de iṣẹ́ wa. Àmọ́, ìjọba sọ pé kò sí ohun tó jọ ọ́.

Bí ìròyìn ṣe ń tàn kiri pé wọn ò fòfin de iṣẹ́ wa mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn ń kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì pé ká fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ránṣẹ́ sáwọn tàbí ká wá kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní ọdún 2003, àwọn tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi ju ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì [42,000], bẹ́ẹ̀ àwọn akéde tó wà ní Indonéṣíà ò tó ìdajì iye yẹn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá [10,000] èèyàn tó wá sí àpéjọ tá a ṣe ní Jakarta, títí kan ọ̀gá àgbà kan tó wà ní Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn. Ó ya ọ̀gá yìí lẹ́nu gan-an nígbà tó rí i pé tọmọdétàgbà ló ń ṣí Bíbélì wọn tí wọ́n sì ń ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n bá pè. Ó sọ fáwọn ará pé òun máa rí i pé òun mú èrò òdì táwọn èèyàn ní nípa àwà Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò.

Lẹ́yìn tí ìjọba mú ìfòfindè náà kúrò, àwọn míṣọ́nnárì tún láǹfààní láti pa dà wọ Indonéṣíà. Àwọn tó kọ́kọ́ pa dà ni Josef Neuhardt àti ìyàwó rẹ̀ Herawati * (láti Solomon Islands), Esa Tarhonen àti ìyàwó rẹ̀ Wilhelmina (láti Taiwan), Rainer Teichmann àti ìyàwó rẹ̀ Felomena (láti Taiwan), àti Bill Perrie àti ìyàwó rẹ̀ Nena (láti Japan). Ètò Ọlọ́run tún rán àwọn míṣọ́nnárì tuntun láti Gílíádì sí North Sumatra, Kalimantan, North Sulawesi àti àwọn ìgbèríko míì.

“Inú mi máa ń dùn láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà kí wọ́n lè túbọ̀ mọ bá a ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ àti bá a ṣe ń sọ àsọyé tó tani jí.”—Julianus Benig

 Nígbà tó di ọdún 2005, ẹ̀ka ọfíìsì ṣètò pé ká bẹ̀rẹ̀ méjì lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run. Arákùnrin Julianus Benig tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ (tá a ń pè ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run báyìí) sọ pé: “Inú mi máa ń dùn láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà kí wọ́n lè túbọ̀ mọ bá a ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ àti bá a ṣe ń sọ àsọyé tó tani jí, èyí táá mú kí wọ́n túbọ̀ wúlò fún ètò Ọlọ́run.” Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí ló ti di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn míì sì ti di alábòójútó àyíká. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn arákùnrin tó wá sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alábòójútó Arìnrìn-Àjò * tá a kọ́kọ́ ṣe ló jẹ́ pé àsìkò tí wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa la ti kọ́kọ́ dá wọn lẹ́kọ̀ọ́. Àmọ́, ilé ẹ̀kọ́ tuntun yìí ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ wọn lẹ́yìn tí wọ́n mú ìfòfindè kúrò. Arákùnrin Ponco Pracoyo wà lára àwọn tó lọ sí kíláàsì àkọ́kọ́ yẹn, ó sọ pé: “Ilé ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ kí n túbọ̀ máa gba tẹni rò kí n sì túbọ̀ máa fọwọ́ gidi mú iṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká. Ilé ẹ̀kọ́ náà tuni lára, ó sì tún tani jí.”

 Àìní Kan Tó Jẹ́ Kánjúkánjú

Ní gbogbo ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] tí wọ́n fi fòfin de iṣẹ́ wa, ilé àdáni lọ̀pọ̀ ìjọ ní orílẹ̀-èdè Indonéṣíà ti máa ń pàdé láti jọ́sìn. Ìwọ̀nba làwọn ìjọ tó lè dá kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó sì ṣòro gan-an kéèyàn tó lè rí ìwé àṣẹ gbà láti kọ́ ilé ìjọsìn. Torí pé àwọn ìjọ ń pọ̀ sí i, ẹ̀ka ọ́fíìsì ya ọ́fíìsì kan sọ́tọ̀ láti máa bójú tó ọ̀rọ̀ kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, ìyẹn Àwọn Tó Ń Ṣètìlẹ́yìn fún Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba (ní báyìí, à ń pè é ní Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ ní Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Kọ̀ọ̀kan).

Erékùṣù Nias ní North Sumatra wà lára ibi tí wọ́n kọ́kọ́ lọ láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun. Arákùnrin Haogo’aro Gea, tó ti pẹ́ ní ìjọ Gunungsitoli sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára wọn, ó ní: “Nígbà tá a gbọ́ pé a máa tó ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, ṣe là ń jó tá à ń yọ̀. Ẹ̀ka ọ́fíìsì rán àwọn méje tó yọ̀ǹda láti máa kọ́lé pé kí wọ́n wá bójú tó ìkọ́lé náà. Ọdún 2011 la parí rẹ̀.” Arákùnrin Faonasökhi Laoli tó wà lára ìgbìmọ̀ ìkọ́lé ní erékùṣù yẹn sọ pé: “Inú àwọn ilé àdáni kéékèèké la ti máa ń ṣèpàdé tẹ́lẹ̀, àwọn aráàlú sì máa ń fi ojú gbáàtúù wo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, gbàrà tá a parí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa ni nǹkan ti yí pa dà. Eré ni àwàdà ni, àwa tá à ń péjọ sípàdé ti kúrò ní ogún [20] a ti di ogójì [40]. Láàárín ọdún kan tá a parí Gbọ̀ngàn náà, àwọn tó ń wá sípàdé ti lé ni ọgọ́rùn-ún [100]! Tẹ̀gàn ni hẹ̀, ilé ìjọsìn wa ló dára jù ní gbogbo erékùṣù yẹn, ńṣe làwọn èèyàn ń bẹ́rí fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

Gbọ̀ngàn Ìjọba ní Bandung

Lọ́dún 2006, àwọn ará tó wà ní ìlú Bandung ní West Java bẹ̀rẹ̀ sí í wá ilẹ̀ tá a lè fi kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba, àkọ́kọ́ irú rẹ̀ nílùú náà. Arákùnrin Singap Panjaitan tó jẹ́ ọ̀kan lára ìgbìmọ̀ ìkọ́lé sọ pé: “Odindi ọdún kan la fi wá ilẹ̀ tó bójú mu ká tó rí. Yàtọ̀ síyẹn, kí ìjọba tó lè fún wa ní ìwé àṣẹ láti kọ́lé náà, a nílò ọgọ́ta [60] èèyàn ládùúgbò, tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí tó  máa fọwọ́ sí i pé ká kọ́ ilé ìjọsìn wa. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ nígbà tá a rí mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [76] lára àwọn aládùúgbò tó fọwọ́ sí iṣẹ́ ìkọ́lé náà, títí kan obìnrin kan tó lẹ́nu nílùú àmọ tí kì í fẹ́ rí wa sójú tẹ́lẹ̀. Nígbà tá a parí ilé náà, a pé àwọn aládùúgbò pé kí wọ́n wá wò ó, kódà a pé káńsẹ́lọ̀ àgbègbè Bandung. Káńsẹ́lọ̀ náà sọ pé: ‘Ká sòótọ́, ilé ìjọsìn yìí kò láfiwé. Ó mọ́ tónítóní, ó sì dùn ún wò, ṣe ló yẹ káwọn oníṣọ́ọ̀ṣì yòókù wá kẹ́kọ̀ọ́ lára yín.’” Wọ́n ya Gbọ̀ngàn Ìjọba alájà méjì yìí sí mímọ́ ni ọdún 2010.

Láti ọdún 2001 wá, a ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó ju ọgọ́rùn-ún [100] lọ ní Indonéṣíà, àmọ́ a ṣì nílò èyí tó pọ̀ sí i.

^ ìpínrọ̀ 3 Ìtàn ìgbésí ayé arábìnrin Herawati Neuhardt wà nínú Ji! April 2011

^ ìpínrọ̀ 1 Tá a ń pè ní Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alábòójútó Àyíká Àtàwọn Ìyàwó Wọn báyìí.