ORÍṢIRÍṢI àjálù ló máa ń ṣẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè Indonéṣíà, bí ìmìtìtì ilẹ̀, àwọn òkè tó yọ iná àti èéfín àti ìmìtìtì ilẹ̀ abẹ́ òkun. Àwọn àjálù yìí sì máa ń mú kí ìgbésí ayé nira fáwọn èèyàn gan-an. Nígbà tí irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí bá wáyé, àwọn èèyàn Jèhófà máa ń tètè ṣètò láti pèsè ìrànwọ́ fún àwọn tí àjálù náà bá, ní pàtàkì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi tiwọn. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 2005 ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó lágbára wáyé ní ìlú Gunungsitoli, ìyẹn ìlú tó tóbi jù ní erékùṣù Nias tó wà ní North Sumatra, ó sì sọ ìlú náà di ilẹ̀ẹ́lẹ̀! Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn ìjọ tó wà ní erékùṣù Sumatra àti ẹ̀ka ọ́fíìsì bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn nǹkan ìrànwọ́ ránṣẹ́ sáwọn ará tó wà níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé. Ètò Ọlọ́run ní kí alábòójútó àyíká tó ń bẹ àyíká náà wò àti ẹnì kan láti ẹ̀ka ọ́fíìsì lọ sí erékùṣù náà láti fún àwọn ará ní ìṣírí kí wọ́n sì fọkàn wọn balẹ̀. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Yuniman Harefa, láti Nias sọ pé: “Ìdààmú bá àwọn èèyàn tó yí wa ká, àmọ́ bí ètò Ọlọ́run ṣe yára ṣètò ìrànwọ́ fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà ò fi wá sílẹ̀.”