Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016

Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Semarang, Java (ní nǹkan bí ọdún 1937)

 INDONÉṢÍÀ

Ibí Yìí Gan-an ni Màá ti Bẹ̀rẹ̀

Ibí Yìí Gan-an ni Màá ti Bẹ̀rẹ̀

Lọ́jọ́ kan, arákùnrin Alexander MacGillivray tó jẹ́ ìránṣẹ́ ẹ̀ka ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà wà nínú ọ́fíìsì rẹ̀, ó ń ronú lórí ọ̀rọ̀ kan tó ń dà á láàmú. Látọjọ́ bíi mélòó kan ló ti ń wá ohun tó máa ṣe, ní báyìí, ó dà bíi pé ó ti rí ohun tó fẹ́ ṣe sí i. Ó pinnu pé òun máa bá Frank Rice sọ̀rọ̀.

Akínkanjú aṣáájú-ọ̀nà ni arákùnrin Frank, ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n [28] sì ni. Ọ̀sẹ̀ mélòó kan ṣáájú ọjọ́ yẹn ni Frank dé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ìgbà tó wà lọ́dọ̀ọ́ ló kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kété lẹ́yìn náà ló bẹ̀rẹ̀ aṣáájú-ọ̀nà. Ohun tó lé ní ọdún mẹ́wàá ló sì fi wàásù káàkiri orílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Lára àwọn ohun tó fi rin ìrìn àjò náà ni ẹṣin, kẹ̀kẹ́, alùpùpù àti ọkọ̀ àfiṣelé. Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan tó lò ní Bẹ́tẹ́lì, ara rẹ̀ ti wà lọ́nà láti tún kọjá sí ìpínlẹ̀ ìwàásù míì.

Arákùnrin MacGillivray pe Frank sínú ọ́fíìsì rẹ̀, ó sì fi àwòrán àwọn erékùṣù tó wà ní àríwá orílẹ̀-èdè Ọsirélíà hàn án. Ó wá ní: “Frank, ǹjẹ́ o mọ̀ pé kò sí arákùnrin kankan ní gbogbo ibi tó ń wò yìí? Ṣé wàá lọ wàásù níbẹ̀?”

Bí Frank ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í wo àwòrán ilẹ̀ náà, ó rí àwọn erékùṣù tó so kọ́ra tí wọ́n dà bíi péálì lójú Òkun Íńdíà. Tẹ́lẹ̀, àwọn erékùṣù yìí ni wọ́n ń pè ní Netherlands East Indies tá a wá mọ̀ sí Indonéṣíà báyìí. * Ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn tó ń gbébẹ̀ ni kò tíì gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ni Frank bá nawọ́ sí Batavia, ìyẹn Jakarta, tó jẹ́ olú ìlú náà, ó sì sọ pé, “Ibí yìí gan-an ni màá ti bẹ̀rẹ̀.”

 Iṣẹ́ Ìwàásù Dé Java

Lọ́dún 1931, Frank Rice dé sí ìlú Jakarta, èyí to wà ní erékùṣù Java. Èrò tó wà nílùú náà kọjá bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n dà bí omi. Ni Frank bá gba yàrá kan síbi tí kò jìnnà sí ìgboro ìlú náà, ó sì kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kún inú rẹ̀ bámúbámú, èyí ya onílé rẹ̀ lẹ́nu gan-an.

Frank Rice àti Clem Deschamp ní Jakarta

Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àárò ilé bẹ̀rẹ̀ sí í sọ Frank, ó ní: “Mi ò rẹ́ni fojú jọ, ṣe lo dà bíi pé mo dá wà. Àwọn èèyàn ń lọ wọ́n ń bọ̀ nínú kóòtù àti àkẹtẹ̀ wọn nígbà ti èmi wọ àkànpọ̀ ẹ̀wù bá a ṣe ń wọ̀ ọ́ ní Ọsirélíà. Mi ò gbọ́ ‘á’ nínú èdè Dutch tàbí Indonesian. Torí náà, mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ mi sọ́nà, mo mọ̀ pé kò sí bó ṣe burú tó màá rẹ́nì kan to gbọ́  Gẹ̀ẹ́sì lágbègbè táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́. Mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù níbẹ̀, ó sì yà mí lẹ́nu pé ó yọrí sí rere.”

Nítorí èdè Dutch ni èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ará Jakarta máa ń sọ, Frank bá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ èdè náà títí tó fi gbọ́ táátààtá tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi wàásù láti ilé-dé-ilé. Ó tún kọ́ èdè Indonesian títí tó fi mọ̀ ọ́n. Frank sọ pé: “Ìṣòro tí mo ní ni pé kò sí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kankan ní èdè yìí, àmọ́ Jèhófà darí mi sí olùkọ́ kan tó gbọ́ èdè náà tó sì fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó gbà láti bá mi tú ìwé Where Are the Dead? sí èdè Indonesian. Yàtọ̀ síyẹn, ó tú àwọn ìwé míì, èyí sì mú káwọn tó ń sọ Indonesian bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Ní November 1931, aṣáájú-ọ̀nà méjì míì láti Ọsirélíà tún dé sí Jakarta. Orúkọ wọn ni Clem Deschamp, ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] àti Bill Hunter ẹni ọdún mọ́kàndínlógún [19]. Clem àti Bill gbé ọkọ̀ kan wá láti Ọsirélíà, tí wọ́n pè ní ilé àwọn aṣáájú-ọ̀nà torí pé ọkọ̀ yìí náà ni wọ́n fi ṣe ilé. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọkọ̀ àfiṣelé tó kọ́kọ́ dé Indonéṣíà. Gbàrà táwọn aṣáájú-ọ̀nà náà kọ́ gbólóhùn bíi mélòó kan nínú èdè Dutch ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù káàkiri àwọn ìlú ńlá tó wà ní Java.

Charles Harris fi kẹ̀kẹ́ àti ọkọ̀ àfiṣelé wàásù

Aṣáájú-ọ̀nà míì tó tọ ipasẹ̀ Clem àti Bill ni Charles Harris. Ọsirélíà lòun náà ti wá, akínkanjú ni, kì í sì fiṣẹ́ ṣeré rárá. Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1935, Charles wàásù káàkiri ìlú Java, bó ṣe ń lo ọkọ̀ àfiṣelé náà ló tún ń gun kẹ̀kẹ́ kó lè rí i pé òun dé ibi gbogbo. Ó sì fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní èdè tí wọ́n gbọ́, bí èdè Lárúbáwá, Chinese, Dutch, Gẹ̀ẹ́sì àti Indonesian. Láàárín ọdún mélòó kan péré, ó fún àwọn èèyàn ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún [17,000].

Iye ìwé tí Charles pín kiri mú káwọn èèyàn gbà pé ọ̀rọ̀ náà kọjá wọ́n-ní wọ́n-pé. Ọ̀gá kan lára àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ní Jakarta béèrè lọ́wọ́ Clem Deschamp pé, “Èèyàn yín mélòó ló ń wàásù ní East Java?”

Arákùnrin Deschamp dáhùn pé: “Ẹnì kan péré ni sà.”

 Ọ̀gá náà jágbe mọ́ ọn, ó ní: “Ọmọ àná lo pè mí ni! Ìwọ náà wolẹ̀ kó o wo ẹnu ọkọ́, bóyá ni ibì kan wà lágbègbè yẹn tí ìwé yín ò tíì dé, o wá ń sọ fún mi pé ẹnì kan péré, mo mọ̀ pé àwọn èèyàn yín tó wà níbẹ̀ yẹn ò ní ṣeé kà.”

Tẹ̀gàn ni hẹ̀, àwọn aṣáájú-ọ̀nà ìgbà yẹn ṣe gudugudu méje láti rí i pé ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn. Arákùnrin Bill Hunter tiẹ̀ sọ pé: “Gbogbo erékùṣù náà la kárí láti ìkángun dé ìkángun, bóyá la bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ lẹ́ẹ̀mejì.” Bí àwọn aṣáájú-ọ̀nà yìí ṣe ń bá ìwàásù wọn lọ ni wọ́n ń fọ́n  irúgbìn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run káàkiri ilẹ̀ náà, èyí sì méso jáde lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.Oníw. 11:6; 1 Kọ́r. 3:6.

Ìhìn Rere Dé Sumatra

Ní nǹkan bí ọdún 1936, àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó wà ní Java jíròrò bí wọ́n ṣe fẹ́ mú ìhìn rere dé ìlú Sumatra tó jẹ́ erékùṣù kẹfà tó fẹ̀ jù láyé. Erékùṣù yìí ní àwọn ìlú ńlá, oko ọ̀gbìn tó fẹ̀, irà àtàwọn igbó ńlá.

Lẹ́yìn ìjíròrò wọn, wọ́n pinnu pé káwọn rán Frank Rice lọ wàásù ní erékùṣù yìí. Ni gbogbo wọn bá dá owó táṣẹ́rẹ́ ọwọ́ wọn jọ fún un láti fi wọkọ̀. Ká to ṣẹ́jú pẹ́, Frank ti gúnlẹ̀ sí Medan, ìyẹn ìlú kan tó wà ni North Sumatra, gbogbo ohun to gbé kò ju báàgì méjì tó fi ń wàásù àti ogójì [40] páálí to kún fún ìwé ìròyìn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba owó ló wà lọwọ́ rẹ̀, Frank ò mikàn, ó mọ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú òun. Bó ṣe tara bọ iṣẹ́ nìyẹn, ó gbà pé Jèhófà máa pèsè ohun tí òun nílò láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà yọrí.—Mát. 6:33.

Ní ọ̀sẹ̀ tí Frank lò kẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwáásù nílùú Medan, ó pàdé bàbá àgbàlagbà kan tó ń sọ èdè Dutch. Bàbá yìí ṣe ọ̀yàyà sí Frank, ó sì pè é kó wá mu kọfí. Ibi ti wọ́n ti ń mu kọfí lọ́wọ́ ni Frank ti sọ fún un pé òun nílò mọ́tò tí òun fi lè wàásù kárí erékùṣù Sumatra. Ni bàbá ba nawọ́ sí mọ́tò kan tó ti dẹnu kọlẹ̀ tó wà nínú ọgbà ó ní, “Bó o bá lè tún un ṣe, màá gbé e fún ẹ, àmọ́ wàá san ọgọ́rùn-ún owó guilders.” *

Frank fèsì pé: “Ibo ni kí ń ti rí adúrú owó yẹn!”.

Bàbá náà wo Frank títí, ló ba ní: “O sì ni o fẹ́ wàásù dé gbogbo Sumatra?”

Frank dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni bàbá.”

Bàbá wá fèsì pé: “Ó dáa, bó o bá lè tún mọ́tò yìí ṣe, o lè máa gbé e lọ, ọjọ́ tí àyè owó ẹ̀ bá yọ, kó o mú un wá.”

 Frank tún mọ́tò náà ṣe títí tó fi ṣiṣẹ́. Ó pa dà ròyìn pé: “Bí mo ṣe kówèé kúnnú mọ́tò nìyẹn, mo rọ epo kún inú táǹkì rẹ̀, pẹ̀lú ọkàn ìgbàgbọ́, mo finá sọ́kọ̀, mo bá gbéra, ó di Sumatra.”

Henry Cockman pẹ̀lú Jean àti Clem Deschamp ní Sumatra lọ́dún 1940

Nígbà tó fi máa pé ọdún kan, Frank ti wàásù káàkiri erékùṣù Sumatra. Ló bá ṣẹ́rí pa dà sí Jakarta. Nígbà tó dé ọ̀hún, ó tá mọ́tò náà ní ọgọ́rùn-ún [100] guilders, ó sì fi owó náà ránṣẹ́ sí bàbá ọjọ́sí nílùú Medan.

Ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn náà, Frank gba lẹ́tà kan láti Ọsirélíà pé kó lọ sí ìpínlẹ̀ míì láti lọ wàásù. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Frank gbéra tó sì forí lé Indochina (tá a wá mọ̀ sí Cambodia, Laos àti Vietnam lónìí).

^ ìpínrọ̀ 4 Wọ́n tún ń pè é ní Dutch East Indies nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ọdún ṣáájú ìgbà yẹn ni àwọn ẹ̀yà Dutch dé síbẹ̀, wọ́n jẹ gàba lé àwọn ará ibẹ̀ lórí, bí wọn ṣe gba òwò àwọn èròjà amóúnjẹ-ta-sánsán mọ́ wọn lọ́wọ́ nìyẹn. Orúkọ tí àwọn ìlú yìí ń jẹ́ lónìí la máa lò jálẹ̀ ìwé yìí.

^ ìpínrọ̀ 3 Tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún kan [1,100] dọ́là owó ilẹ̀ Amẹ́ríkà.