Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016

 INDONÉṢÍÀ

“Jèhófà Bù Kún Wa Ju Bá A Ṣe Rò Lọ!”

Angeragō Hia

“Jèhófà Bù Kún Wa Ju Bá A Ṣe Rò Lọ!”
  • WỌ́N BÍ I NÍ 1957

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1997

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó pa dà sí abúlé wọn tó wà ládàádó ní erékùṣù Nias, ó sì dá ìjọ kan sílẹ̀.

LỌ́DÚN 2013, a rí ìròyìn amóríyá kan gbà ní ìjọ wa kékeré tó wà nílùú Tugala Oyo, pé wọ́n ń bọ̀ wá kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun fún wa! Àwọn aláṣẹ àdúgbò fàyè gba iṣẹ́ náà, ọgọ́ta [60] àwọn aládùúgbò wa ló fọwọ́ sí i kí iṣẹ́ náà bàa lè di ṣíṣe. Ọ̀kan lára wọn tiẹ̀ sọ pé: “Bó bá jẹ́ igba [200] èèyàn lẹ̀ ń wá pé kó fọwọ́ sí i, ẹ máa rí.”

Àwọn méjì lára àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó máa ń yọ̀ǹda ara wọn láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wà lárọ̀ọ́wọ́tó, àwọn ló sì bá wa mójú tó bí iṣẹ́ náà ṣe ń lọ. A dúpẹ́ pé ní November 2014, iṣẹ́ náà parí. A ò tiẹ̀ lálàá ẹ̀ rí pé ìjọ wa náà máa ní irú ibi ìjọsìn to dára báyìí. Ká sòótọ́, Jèhófà bù kún wa ju bá a ṣe rò lọ!