Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016

 INDONÉṢÍÀ

Èèyàn Bíi Sárà

Titi Koetin

Èèyàn Bíi Sárà
  • WỌ́N BÍ I NÍ 1928

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1957

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Arábìnrin kan tó fi ọgbọ́n kọ́ ọkọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láìka àtakò sí.—Gẹ́gẹ́ bí Mario Koetin ọmọ rẹ̀ ṣe sọ ọ́.

ÌYÁ MI jẹ́ ọlọ́yàyà, ó fẹ́ràn àwọn èèyàn, ó sì gbádùn kó máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Gertrud Ott tó ṣe míṣọ́nnárì ní ìlú Manado tó wà ní North Sulawesi ló wàásù fún ìyá mi, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ìyá mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì títí tó fi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bàbá mi ní tiẹ̀ jẹ́ gbajúgbàjà òṣìṣẹ́ ní báǹkì, ìgbà tó yá, wọ́n di ọ̀gá àgbà níléeṣẹ́ àjọ ìdókòwò tó wà ní Jakarta, ìyẹn Jakarta Stock Exchange. Bàbá mi ò gba ti ẹ̀sìn ajẹ́rìí tí ìyá mi ń ṣe, wọ́n sì ta kò ó pátápátá.

Ọjọ́ kan ni bàbá mi fòté lé e pé ìya mi ò gbọdọ̀ ṣe àjẹ́rìí mọ́.

Bàbá mi fi ìbínú sọ pe: “Lónìí ni wàá mú ọ̀kan, bóyá èmi ni o tàbí ìsiń tó ń ṣe yẹn.”

Ìyá mi ronú lọ suu, ló bá fèsì lóhùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ pé: “Méjèèjì ni mo fẹ́, mo fẹ́ ọkọ mi, mo sì tún fẹ́ Jèhófà.”

Ìdáhùn yẹn múnú bàbá mi rọ̀ pẹ̀sẹ̀, wọn ò lè sọ nǹkan kan mọ́.

 Nítorí ọgbọ́n tí ìyá mi fi ń bá bàbá mi lò, inú bàbá mi bẹ̀rẹ̀ sí í yọ́ díẹ̀ díẹ̀, wọ́n sì túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ìyá mi gan-an.

Àmọ́, ohun tó wu ìyá mi jù ni pé kí òun àti bàbá mi jọ máa sin Jèhófà. Lẹ́yìn tí ìyá mi gbàdúrà kíkankíkan lórí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n rántí pe bàbá fẹ́ràn láti máa kọ́ èdè tuntun. Ní wọ́n bá kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì lédè Gẹ̀ẹ́sì sáwọn ibi kan nínú ilé. Wọ́n sọ fún Bàbá mi pé: “Mo fẹ́ kí Gẹ̀ẹ́sì mi túbọ̀ dán mọ́rán sí i.” Bàbá mi tún mọyì kéèyán máa sọ̀rọ̀ ní gbangba, torí náà ìyá mi bẹ bàbá mi pe kí wọ́n wo bàwọn ṣe ń múra iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́, bàbá mi sì gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ìyá mi tún mọ̀ pe bàbá lẹ́mìí aájò àlejò, ó sì nífẹ̀ẹ́ ìdílé rẹ̀ gan-an, wọ́n béèrè bóyá alábójútó àyíká lè wá kí wa, bàbá mi ní kò burú. Ìyá mi tún rọra bèèrè bóyá wọ́n á fẹ́ bá wa lọ sí àwọn àpéjọ wa. Bàbá mi sì gbà.

Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, lọ́wọ́ sùúrù àti ìfòyemọ̀ ìyá mi, inú bàbá mi rọlẹ̀. Nígbà tí ìdílé wa ṣí lọ sí England, bàbá mi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé, ibẹ̀ sì ni wọ́n ti di ọ̀rẹ́ Arákùnrin John Barr tó di ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọdún yẹn náà ni bàbá mi ṣe ìrìbọmi, ayọ̀ ńláǹlà lèyí sì jẹ́ fún ìyá mi. Àtìgbà náà ni ìfẹ́ àárìn àwọn méjèèjì ti lágbára sí i.

Gbogbo àwọn tó mọ ìyá mi ló máa ń ròyìn bí wọ́n ṣe jẹ́ oníwà mímọ́, tí wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn

Àwọn ọ̀rẹ́ wa kan máa ń sọ pé ìyá mi dà bíi Lìdíà torí pé wọ́n lẹ́mìí áájò àlejò. (Ìṣe 16:14, 15) Àmọ́, bíi Sárà ni mo ṣe máa ń wo ìyá mi torí bí wọ́n ṣe tinútinú fi ara wọn sábẹ́ àṣẹ ọkọ wọn. (1 Pet. 3:4-6) Ìyá mi jẹ́ oníwà mímọ́, wọ́n máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn, wọ́n sì ń hùwà rere. Kò sẹ́ni tó pàdé ìyá mi tó máa gbàgbé wọn. Ìwà ìyá mi ló sún bàbá mi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lójú tèmi, èèyàn bíi Sárà ni ìyá mi.