• WỌ́N BÍ I NÍ 1927

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1962

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ọ̀gá ọlọ́pàá ni tẹ́lẹ̀ kó tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe fún ohun tó lé ní àádọ́ta [50] ọdún.

LỌ́DÚN 1964, ètò Ọlọ́run rán mi lọ ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ní ìjọ kékeré kan tó wà ní Manokwari nílùú West Papua. Ojú ń pọ́n àwọn ará tó wà níjọ yẹn torí àwọn olórí ẹ̀sìn ibẹ̀ ń fínná mọ́ wọn gan an. Kò pẹ́ tí mo dé sílùú náà ni àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan já wọlé mi.

Ó ń sọ̀rọ̀ fitafita pé: “Wòó, màá wó ilé yìí kanlẹ̀, máà sí rí i pé kò sí Ajẹ́rìí Jèhófà kankan nílùú Manokwari ńbí.”

Torí pé mo ti ṣe iṣẹ́ ọlọ́pàá rí, gìràgìrà rẹ̀ ò dẹ́rù bà mí. Dípò kí n bú mọ́ ọn, ṣe ni mo fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá a sọ̀rọ̀, ló bá yí pa dà, ó sì lọ wọ́ọ́rọ́wọ́.1 Pét. 3:15.

Nígbà yẹn, akéde mẹ́jọ péré ló wà ní gbogbo Manokwari. Àmọ́ lónìí, ìyẹn lẹ́yìn àádọ́ta [50] ọdún, ìjọ méje ló wà níbẹ̀ báyìí. Àwọn tó wá sí àpéjọ àgbègbè tá a ṣe níbẹ̀ lọ́dún 2014 sì ju ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún méjì [1,200] lọ. Tí ń bá wo gbogbo ohun tí Jèhófà ti mu ká gbéṣe ní ibi àdádó yìí, inú mi máa ń dùn gan-an.