Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 INDONÉṢÍÀ

Wọ́n Ń Fayọ̀ Polongo Orúkọ Jèhófà

Wọ́n Ń Fayọ̀ Polongo Orúkọ Jèhófà

Jálẹ̀ gbogbo ọdún tí ìjọba fi fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Indonéṣíà, àwọn ará wa hùwà ọgbọ́n, wọ́n fi ìmọ̀ràn Jésù sílò, pé “ẹ jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra gẹ́gẹ́ bí ejò, síbẹ̀ kí ẹ jẹ́ ọlọ́rùn-mímọ́ gẹ́gẹ́ bí àdàbà.” (Mát. 10:16) Àmọ́ nígbà tí ìjọba mú ìfòfindè náà kúrò, ọ̀pọ̀ àwọn ará ní láti kọ́ bí wọ́n á ṣe máa fìgboyà wàásù.Ìṣe 4:31.

Bí àpẹẹrẹ, kò mọ́ àwọn ará wa kan lára mọ́ láti máa wàásù láti ilé dé ilé, ṣe ni wọ́n kàn ń ṣe ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ní tiwọn. Àwọn míì kì í fẹ́ bá àwọn Mùsùlùmí sọ̀rọ̀. Kristẹni làwọn míì máa ń pe ará wọn fún onílé dípò kí wọ́n sọ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn, Bíbélì àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni wọ́n sì máa ń lò dípò kí wọ́n máa lo Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun * lédè Indonesian. Kì í yá àwọn kan lára láti máa fún àwọn èèyàn ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa.

Àtìgbà tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa, làṣà yẹn ti mọ́ wọn lára. Ohun míì tó tún fà á ni àṣà tó wọ́pọ̀ lọ́dọ̀ wọn. Wọ́n gbà pé á dáa kéèyàn fara mọ ohun táwọn èèyàn ń ṣe dípò téèyàn á fi máa ṣe ohun tó yàtọ̀, kéèyàn máa tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́ dípò téèyàn á fi máa sọ pé òun kò gba tiwọn. Kí wá ni ṣíṣe?

Jèhófà lo àwọn arákùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn láti fìfẹ́ fún àwọn ará nímọ̀ràn. (Éfé. 4:11, 12) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Arákùnrin Stephen Lett tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè náà, ó fún àwọn ará níṣìírí, ó sì fìfẹ́ gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n máa lo Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù dáadáa kí wọ́n lè gbé orúkọ Jèhófà ga. Míṣọ́nnárì kan tó ń jẹ́ Misja Beerens sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Lett sọ wọ̀ wá ní akínyẹmí ara. A wá rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ wá yàtọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, a ò sì tijú àtigbèjà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.”

Torí pé àwọn Mùsùlùmí tó wà ní orílẹ̀-èdè náà sábà máa ń ka àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa lédè  Indonesian fún àwọn ará ní ìtọ́ni tó ṣe wọ́n láǹfààní, pé: “Ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ yín yàtọ̀ ni pé, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ yín ẹ jẹ́ kí onílé mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà niyín. . . . A ò tijú àtijẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ìránṣẹ́ Jèhófà ni wá, a sì ti pinnu pé àá jẹ́ kí àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa mọ orúkọ Ọlọ́run àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé!” Shinsuke Kawamoto, tó ń sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Indonéṣíà sọ pé: “Ọ̀nà tí wọ́n ní ká gbà máa wàásù yìí bọ́gbọ́n mu ó sì ṣe tààràtà, torí bẹ́ẹ̀ ó gbéṣẹ́. Àwọn Mùsùlùmí tó fẹ́ mọ ẹni táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ kò níye. Wọ́n fẹ́ mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwa àtàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Ìyẹn wá mú ká lè wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn dáadáa.”

Wọ́n tún gba àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run níyànjú pé kí wọ́n túbọ̀ máa pín ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Arákùnrin Lothar Mihank, tó jẹ́ olùṣekòkáárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, ṣàlàyé pé: “Táwọn èèyàn bá máa mọ̀ wá, wọ́n á ní láti máa ka àwọn ìwé ìròyìn wa. Ńṣe ni àwọn ìwé ìròyìn tá à ń fún wọn dà bí ìgbà téèyàn bá da omi síwájú tó wá ń tẹ ilẹ̀ tútù. Ó ń mú káwọn èèyàn fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Tá a bá pín àwọn ìwé náà dáadáa, ṣe là ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa Jèhófà.”

À Ń Wàásù Níbi Tí Èrò Pọ̀ Sí

Lọ́dún 2013, ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Indonéṣíà bẹ̀rẹ̀ ọ̀nà ìwàásù tuntun méjì tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí. Àkọ́kọ́ ni àkànṣe ìwàásù láwọn ìlú tí èrò pọ̀ sí, ìkejì sì ni ìṣètò ìjọ láti máa wàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí ní ìpínlẹ̀ ìjọ. Àwọn ọ̀nà tuntun tá à ń gbà wàásù yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.

Lára àwọn ibi térò máa ń pọ̀ sí gan-an ni ilé ìtajà ńlá kan tó wà ní West Jakarta, níbi tí wọ́n ti ń ta rédíò, tẹlifíṣọ̀n, àtàwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀. Ibẹ̀ nibi àkọ́kọ́ tá a pàtẹ àwọn ìwé wa sí ká lè wàásù lákànṣe fún àwọn èèyàn tó ń lọ tó ń bọ̀. Lẹ́yìn ìyẹn làwọn ìjọ kọ̀ọ̀kan bẹ̀rẹ̀ sí í lo àwọn tábìlì àtàwọn ohun tó ṣeé gbé kiri láti pàtẹ àwọn ìwé wa ní àwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn. Lẹ́nu ọdún kan péré, ó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] àwọn tábìlì àtàwọn ohun tó ṣeé gbé kiri tá a fi ń pàtẹ àwọn ìwé wa láwọn ìlú ńláńlá jákèjádò Indonéṣíà. Kí wá ni àbájáde gbogbo ìsapá yìí?

 Arákùnrin Yusak Uniplaita, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alàgbà ní Jakarta, sọ pé: “Kó tó di pé a bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù níbi táwọn èrò pọ̀ sí, ẹgbẹ̀fà [1,200] ìwé ìròyìn ni ìjọ wa máa ń gbà lóṣù. Àmọ́, oṣù mẹ́fà lẹ́yìn tá a bẹ̀rẹ̀, ìjọ wa ń gba ẹgbẹ̀ta [6,000] ìwé ìròyìn. Ní báyìí, ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ [8,000] ìwé ìròyìn ni ìjọ wa ń gbà lóṣù. Àìmọye ìwé pẹlẹbẹ àtàwọn ìwé ńlá là ń fi sóde.” Nílùú Medan, tó wà ní North Sumatra, àwọn aṣáájú-ọ̀nà mélòó kan pàtẹ àwọn ìwé wa sórí kẹ̀kẹ́ tó ṣeé gbé kiri láwọn ibi mẹ́ta tí èrò pọ̀ sí. Ní oṣù àkọ́kọ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ márùndínlọ́gọ́fà [115] àti nǹkan bí ẹgbẹ̀sán [1,800] ìwé ìròyìn ni wọ́n fí sóde. Oṣù méjì lẹ́yìn náà, àwọn aṣáájú-ọ̀nà náà ti di ọgọ́ta, wọ́n sì ń pàtẹ ìwé síbi méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Lápapọ̀, wọ́n fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó lé ní ẹgbẹ̀fà [1,200] àti 12,400 ìwé ìròyìn sóde. Míṣọ́nnárì kan tó ń jẹ́ Jesse Clark sọ bó ṣe rí pé: “Àwọn ọ̀nà ìwàásù tuntun yìí ń mú kí ara wa yá gágá láti wàásù, ó sì tún fi hàn pé ọ̀pọ̀ èèyàn lebi òtítọ́ ń pa ní orílẹ̀-èdè Indonéṣíà. Ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, wíwàásù níbi tí èrò pọ̀ sí ti di apá kan ìwàásù wa!”

À Ń Lo Èdè Tó Wọ Àwọn Èèyàn Lọ́kàn

Tá a bá ń ka àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní àgbègbè tí èdè pọ̀ sí jù lọ láyé, ọ̀kan ni Indonéṣíà. * Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn èèyàn náà ló ń sọ èdè Indonesian tó jẹ́ èdè àjùmọ̀lò, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ wọn ló ní èdè ìbílẹ̀ tí wọ́n ń sọ láàárín ara wọn, ìyẹn sì lèdè tó ń mú kí ọ̀rọ̀ wọ àwọn èèyàn lọ́kàn gan-an.

Àwùjọ tó ń tú mọ́ èdè Batak-Toba ní North Sumatra rèé

Lọ́dún 2012, ẹ̀ka ọ́fíìsì pinnu pé àwọn fẹ́ mọ bí àwọn ṣe lè ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn tó ń sọ onírúurú èdè yìí. Arákùnrin Tom Van Leemputten sọ pé: “A bẹ̀rẹ̀ sí í túmọ̀ àwọn ìwé wa sí èdè ìbílẹ̀ méjìlá tí àwọn ọgọ́fà [120] mílíọ̀nù èèyàn ń sọ. Nígbà táwọn atúmọ̀ èdè Javanese rí ìwé àṣàrò kúkúrú tá a kọ́kọ́ ṣe lédè náà, omijé ayọ̀ bọ́ lójú wọn. Ẹ ò rí nǹkan, inú wọn dùn pé àwọn náà rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà lédè àwọn!”

Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ìjọ ló ṣì ń ṣe àwọn ìpàdé wọn lédè Indonesian, títí kan àwọn tó fẹ́ràn àtimáa bá ara wọn sọ èdè àbínibí wọn. Arákùnrin  Lothar Mihank ròyìn pé: “Lọ́dún 2013, èmi àti ìyàwó mi, Carmen, lọ sí àpéjọ ọlọ́jọ́ méjì ní erékùṣù Nias tó wà ní North Sumatra. Èyí tó pọ̀ jù lára irínwó [400] tó pésẹ̀ sí àpéjọ yẹn ló gbọ́ èdè Nias, àmọ́ èdè Indonesian ni wọ́n fi sọ gbogbo àsọyé ọjọ́ àkọ́kọ́. Lẹ́yìn témi àtàwọn olùbánisọ̀rọ̀ jọ foríkorí, a sọ fún àwọn tó pé jọ pé èdè Nias la máa fi ṣe àpéjọ lọ́jọ́ kejì. Ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀? Egbẹ̀ta [600] èèyàn ló wá sí àpéjọ náà lọ́jọ́ kejì, àyè ò gbà wá, ṣe ni gbogbo wa fún mọ́ra.” Carmen ìyàwó rẹ̀ fi kún un: “Ó ṣe kedere pé àwọn èèyàn náà tẹ́tí dáadáa lọ́jọ́ kejì tí wọ́n lo èdè Nias ju ti ọjọ́ àkọ́kọ́ tí wọ́n lo èdè Indonesian. Ìdì sì ni pé èdè àbínibí làwọn olùbánisọ̀rọ̀ fi ṣe iṣẹ́ wọn. Inú àwọn èèyàn náà dùn gan-an pé wọ́n gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lédè wọn, wọ́n sì lóye rẹ̀ dáadáa.”

Wọ́n ń kọ́ adití kan lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́

Àní àwọn adití ń gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní èdè tiwọn pẹ̀lú. Látọdún 2010, àwọn atúmọ̀ èdè ti túmọ̀ ìwé pẹlẹbẹ  méje àti ìwé àṣàrò kúkúrú mẹ́jọ sí Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Indonesian. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀ka ọ́fíìsì ti ṣètò àwọn kíláàsì mẹ́rìnlélógún [24] tí wọ́n ti ń kọ́ àwọn èèyàn ní èdè adití, èyí sì ti mú ká dá ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́ta [750] àwọn ará lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa fi èdè adití wàásù. Lónìí, àwọn ìjọ àtàwọn àwùjọ mẹ́tàlélógún [23] ló ń ṣèrànwọ́ fún àwọn adití tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́ta tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà. Wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tu àwọn adití náà nínú, wọ́n sì ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa jọ́sìn Jèhófà.

Ní báyìí, àwùjọ àwọn atúmọ̀ èdè mẹ́tàdínlógójì [37] lò wà ni Ẹ̀ka Ìtúmọ̀ Èdè lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan èdè náà sì ní àwùjọ atúmọ̀ èdè tirẹ̀. Lápapọ̀, méjìdínlọ́gọ́fà [117] làwọn atúmọ̀ èdè tó ń ṣiṣẹ́ láwọn ibi mọ́kàndínlógún [19] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórílẹ̀-èdè náà, pa pọ̀ pẹ̀lú àádọ́ta [50] àwọn ará míì tó ń ṣe àwọn iṣẹ́ míì tó tún pọn dandan níbẹ̀.

^ ìpínrọ̀ 2 Ọdún 1999 la ṣe odindi Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Indonesian. Ọdún méje gbáko ni àwọn atúmọ̀ èdè fi ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè parí iṣẹ́ lórí Bíbélì náà, láìka pé wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, wọ́n gbé ìwé Insight on the Scriptures, jáde lédè Indonesian. Lẹ́yìn náà ni wọ́n tún ṣe Watchtower Library on CD-ROM, jáde lédè Indonesian. Ó dájú pé iṣẹ́ ńlá làwọn atúmọ̀ èdè náà ṣe!

^ ìpínrọ̀ 2 707 ni èdè tí wọ́n ń sọ ní Indonéṣíà, nígbà tí orílẹ̀-èdè tó múlé gbè é, ìyẹn Papua New Guinea, ní èdè 838.