Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016

 INDONÉṢÍÀ

A Dúpẹ́ Pé Ojú Túnra Rí!

Gẹ́gẹ́ bí Linda àti Sally Ong ṣe sọ ọ́

A Dúpẹ́ Pé Ojú Túnra Rí!

Linda: Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá [12] ni ìyá mi sọ fún mi pé mo ní àbúrò obìnrin tí àwọn kan gbà ṣọmọ. Mo máa ń rò ó bóyá odi ni wọ́n bí òun náà bíi tèmi. Àmọ́ mi ò mọ onítọ̀hún títí tí mo fi dàgbà.

Sally: Mi ò mọ̀ pé ńṣe ni a gbà mí sọmọ. Ẹni tó wò mí dàgbà bí ìyá máa ń lù mí bí ẹran, ó sì máa ń ṣe mí bí ẹrú. Èyí máa ń dá kún ìbànújẹ́ àti ìdárò mi torí pé mó tún jẹ́ odi látìgbà tí wọ́n ti bí mi. Nígbà tó yà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wàásù dé ọ̀dọ̀ mi, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí ìyá yìí mọ̀ pé mo ń kẹ́kọ̀ọ́, ó fi bẹ́líìtì nà mí bí ẹni máa kú, ó tì mí mọ́lé bí ẹlẹ́wọ̀n, ó sì pààrọ̀ kọ́kọ́rọ́ ilé kí n má bàa jáde. Nígbà tí mo pé ọmọ ogún [20] ọdún, mó sá kúrò níle, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì gbà mí sílé. Mo ṣèrìbọmi ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2012.

 Linda: Nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ogún [20] ọdún ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìgbà tó yá ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn àpéjọ agbègbè tí a ń tú sí èdè àwọn adití tí wọ́n ń ṣe ní ìlú Jakarta. Ibẹ̀ ni mo ti pádè àìmọye àwọn odi bíi tèmi. Ọ̀kan nínú wọn ni Sally, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí tó ń gbé ní North Sumatra. Ara mi ṣáà fà sí Sally lọ́nà kan ṣáá, àmọ́ mi ò mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.

Sally: Èmi àti Linda di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn. Ó máa ń ṣe mí bíi pé àwa méjèèjì jọra, àmọ́ màá tún gbé èrò náà kúrò lọ́kàn.

Linda: Ní August 2012, ní ọjọ́ tó ku ọ̀la tí màá ṣèrìbọmi, ọkàn mi ṣáà ṣàfẹ́rí àbúrò mi tó sọnù yìí. Mo wá bẹ Jèhófà pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí ń rí àbúro mi torí mo fẹ́ sọ fún un nípa ìwọ Ẹlẹ́dàá.” Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni ìyá mi gba àtẹ̀jíṣẹ́ látọ̀dọ̀ ẹnìkan tó mọ̀ nípa àbúrò mi tó sọnù. La bá bẹ̀rẹ̀ sí í wá bá a ṣe máa kàn sí Sally.

Sally: Nígbà tí Linda ṣàlàyé fún mí pé èmi ni àbúrò rẹ̀ tó ti sọnù látọdún yìí wá, kíá ni mo wọkọ̀ òfuurufú lọ sí Jakarta lọ pàdé rẹ̀. Bí mo ṣe jáde ní pápákọ̀ òfuurufú ni mo rí Linda àti Bàbá mi, ìyá mi àtàwọn ẹ̀gbọ́n mi tó kù, tí wọ́n wá kí mi káàbọ̀. Orí mi wú, ara mi sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n. A dì mọ́ra, a sì fi ẹnu ko ẹnu. Ìyá mi ló dì mọ́ mi pẹ́ jù. Gbogbo wa n sunkún. Pẹ̀lú omijé ni bàbá àti ìyá mi fi ń bẹ̀ mí pé kí n máà bínú pé àwọn gbé mi fún ẹlòmíì ṣọmọ, gbogbo wa bá tún bú sẹ́kún, a sì tún dì mọ́ra.

Linda: Nítorí ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwa méjèèjì gbé dàgbà, ìwà àti ànímọ́ wa yàtọ̀ síra. Àmọ́, àwa méjèèjì ti mọwọ́ ara wa, a sì fẹ́ràn ara wa gan-an.

Sally: Èmi àti Linda jọ ń gbé ni báyìí, ìjọ kan náà la wà, ìyẹn ìjọ tó ń lo èdè àwọn aditi tó wà ní Jakarta.

Linda: Ó lé ní ogún [20] ọdún tí èmi àti Sally fi pínyà. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ojú túnra rí nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín!