Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016

Indonéṣíà

Indonéṣíà

ÌRÒYÌN amóríyá tá a fẹ́ sọ yìí dá lórí àwọn Kristẹni onírẹ̀lẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n lo ìgboyà tí wọ́n sì di ìgbàgbọ́ wọn mú láìka rògbòdìyàn láàárín àwọn olóṣèlú, ìjà ẹ̀sìn àti bí àwọn ẹlẹ́sìn ṣe mú kí ìjọba fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wọn fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25]. A máa kà nípa arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ wà lára àwọn ti ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì fẹ́ pa, àá sì kà nípa ọ̀gá àwọn jàǹdùkú kan tó di olùjọ́sìn Jèhófà. Àá tún rí ìtàn àwọn ọmọbìnrin méjì kan tó jẹ́ odi tí wọ́n mú ara wọn lọ́rẹ̀ẹ́ kí wọ́n tó wá mọ̀ pé ọmọ ìyá làwọn. Pabanbarì rẹ̀, a máa mọ báwọn èèyàn Jèhófà ṣe wàásù káàkiri orílẹ̀-èdè Indonéṣíà, ìyẹn orílẹ̀-èdè táwọn Mùsùlùmí pọ̀ sí jù láyé.

NÍ APÁ YÌÍ

Àlàyé Ṣókí Nípa Indonéṣíà

Wo àkópọ̀ ṣókí nípa ilẹ̀, àwọn èèyàn àti àṣà tó wà ni orílẹ̀-èdè tó ní àwọn erékùṣù tó fẹ̀ jù láyé.

Òwò Èròjà Amóúnjẹ-ta-sánsán

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún, òwò èròjà amóúnjẹ-ta-sánsán ló gbayé kan.

Ibí Yìí Gan-an ni Màá ti Bẹ̀rẹ̀

Àwọn akínkanjú aṣáájú-ọ̀nà lati Ọsirélíà ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwáásù láìka àwọn ìṣòro tí wọ́n kojú.

Bá A Ṣe Ń Wàásù Láyé Ọjọ́un

Àsọyé Bíbélì tá a ṣe lórí rédíò àti ìwàásù láwọn etíkun Indonéṣíà bí àwọn tó kórìíra òtítọ́ nínú.

Ẹgbẹ́ Bibelkring

Ohun tí wọ́n kà nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló mú wọn dá ẹgbẹ́ yìí sílẹ̀, àmọ́ ìgbà tó yá ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi èrò èèyàn darí ẹgbẹ́ náà.

Ó Mọyì Ọrọ̀ Tẹ̀mí

Àwọn ọ̀bàyéjẹ́ já wọlé Thio Seng Bie, wọ́n sì kẹ́rù rẹ̀ lọ, síbẹ̀ ṣe ló ń wò wọ́n. Àmọ́ ohun tí wọ́n ò kó mẹ́rù wúlò ju ohun tí wọ́n kó lọ.

Ìwàásù Méso Jáde ní West Java

Bí wọ́n ṣe ń fòfin de àwọn ìwé wa lọ́kan-ò-jọ̀kan, bẹ́ẹ̀ làwa Ẹlẹ́rìí ń dá ọgbọ́n oríṣiríṣi kí iṣẹ́ ìwáásù náà lè máa tẹ̀ síwájú.

Lábẹ́ Àjàgà Ìjọba Ilẹ̀ Japan

Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn Ẹlẹ́rìí kan wá ọ̀nà àbáyọ láti forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ Japan láìsì dá sọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun.

Akínkanjú Aṣáájú-ọ̀nà

Jálẹ̀ 60 ọdún tí André Elias fi ṣiṣẹ́ sìn, ó jólóòótọ́ bí wọ́n tiẹ̀ halẹ̀ mọ́ ọn tí wọ́n sì ń fọ̀rọ̀ lọ ọ́ nífun.

Àwọn Míṣọ́nnárì Láti Gílíádì Dé

Àwọn míṣọ́nnárì láti Gílíádì tó kọ́kọ́ dé mú kí iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò kíákíá.

Iṣẹ́ Náà Gbòòrò dé Ìlà Oòrùn

Ṣé àwọn olórí ìsìn á ṣàṣeyọrí lọ́tẹ̀ yìí?

Àwọn Míṣọ́nnárì Míì Tún Dé

Ipò nǹkan yí pa dà bìrí láàárín ọdún 1973 sí 1978, àtiwàásù wá dogun.

Èèyàn Bíi Sárà

Tinútinú ni Titi Koetin fi ara rẹ̀ sábẹ́ àṣẹ ọkọ rẹ̀, ó sì rí èrè jìgbìnnì níbẹ̀.

Àpéjọ Mánigbàgbé Kan

A ṣe Àpéjọ “Ìhìn Rere Àìnípẹ̀kun” láṣeyọrí láìka àwọn ìṣòro tó yọjú.

Mo La Rògbòdìyàn Àwọn Kọ́múní ìsì Já

Wọ́n ti gbẹ́ sàréè tí wọ́n máa sin Ronald Jacka sí

Àádọ́ta Ọdún Lẹ́nu Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà Àkànṣe

Lọ́dún 1964, àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan halẹ̀ mọ́ wa pé: ‘Máà rí sí i pé kò sí Ajẹ́rìí Jèhófà kankan nílùú Manokwari ńbí!’ Ṣe ó ṣàṣeyọrí?

Ọ̀gá Àwọn Jàǹdùkú Di Ọmọlúwàbí

Ọ̀gá Àwọn Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ bèèrè pé: “Sòótọ́ fún mi, kí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ní Indonéṣíà gan-an?”

Wọ́n Pinnu Láti Tẹ̀ Síwájú

Kí ló mú káwọn èèyàn tó ń róhun tó ń ṣẹlẹ̀ sọ pé, “Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí ṣáá, ńṣe lẹ dà bí ìṣó”?

Wọ́n Ò fi Ọ̀rọ̀ Ìpàdé Ṣeré

Nígbà tí wọ́n mú ìfòfinde kúrò lórí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọ̀gá àgbà kan sọ ẹ̀dà ọ̀rọ̀ pé: “Ìwé tá a fi forúkọ yín sílẹ̀ yìí kì í ṣe ìwé tó fún yín ní òmìnira láti máa jọ́sìn.”

Ìfẹ́ Tòótọ́ Lákòókò Àjálù

Ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó lágbára sọ ìlú Gunungsitoli di ilẹ̀ẹ́lẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò ìrànwọ́ fáwọn ará wọn.

A Kò Ní Sẹ́ Ìgbàgbọ́ Wa

Daniel Lokollo rántí inúnibíni tí wọ́n ṣe sí i lẹ́wọ̀n.

A Tẹ̀ Lé Ìtọ́ni—A Sì Yè!

Ìjà àárín àwọn Mùsùlùmí àtàwọn Kristẹni lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà mú kí nǹkan nira fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ńbẹ̀.

Iṣẹ́ Wa Ń Tẹ̀ Síwájú

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n mú ìfòfindè iṣẹ́ wa kúrò ni ànfààní ńlá mẹ́ta yọjú fún àwọn ara.

Wọ́n Ń Fayọ̀ Polongo Orúkọ Jèhófà

Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí ṣe kápá àṣà tó ti mọ́ra tí kì í jẹ́ kí wọ́n lè fìgboyà wàásù?

Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Bọ́ sí Ojútáyé

Àwọn ara tó ń wá ibi táwọn èèyàn púpọ̀ á ti gbọ́ ìwàásù ti wá rí ibi tí àìní pọ̀ sí gan-an.

“Jèhófà Bù Kún Wa Ju Bá A Ṣe Rò Lọ!”

Ìjọ tó wà lábúlé Tugala, lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà rí ìbùkún àgbàyanu gbà.

A Dúpẹ́ Pé Ojú Túnra Rí!

Àwọn arábìnrin odi méjì tó jẹ́ ọmọ ìyá ò mọra torí pé àti kékeré ni wọ́n ti wọ́n gbé ọ̀kan nínú wọn ṣọmọ, òtítọ́ Bíbélì ló pa dà so wọ́n pọ̀.