Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016

 ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

A Ya Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Sí Mímọ́

A Ya Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Sí Mímọ́

LỌ́JỌ́ Sátidé, January 24, 2015, wọ́n ya ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Madagásíkà sí mímọ́. Arábìnrin kan tó wà níbẹ̀ sọ pé, “Mi ò lè sọ bí inú mi ti dùn tó.” Arábìnrin yìí wà lára àwọn 583 èèyàn tó láǹfààní àtirìn yíká ọ́fíìsì náà, tí wọ́n rí àwọn ilé gbígbé, yàrá ìjẹun ńlá àti ilé ìdáná tá a tún ṣe. Àwọn nǹkan míì tó fani mọ́ra ni pé wọ́n mú kí ọ́fíìsì ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn gbòòrò sí i, títí kan ẹ̀ka tó ń bójú tó ìnáwó àti ẹ̀ka tó ń bójú tó yíyàwòrán ilé àti kíkọ́ ọ. Bákan náà, wọ́n kọ́ yàrá ìgbóhùn sílẹ̀ fún ẹ̀ka tó ń gba ohùn àti àwòrán sílẹ̀ àti ẹ̀ka tó ń bójú tó Èdè Adití, wọ́n sì dá ẹ̀ka tó ń ṣe ìwé àwọn afọ́jú sílẹ̀. Lẹ́yìn àlàyé nípa bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Madagásíkà àti bó ṣe ń tẹ̀ síwájú, Arákùnrin Mark Sanderson tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí wá sọ àsọyé ìyàsímímọ́.

Ilé gbígbé oníyàrá mọ́kàndínlógún [19] tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Madagásíkà

Inú àwọn ará ní Jakarta, lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà, dùn gan-an nígbà tí wọ̀n ya ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn tuntun sí mímọ́ ní February 14,  2015. Ìdí ni pé omíyalé kan ṣẹlẹ̀ nílùú náà ṣáájú ìgbà yẹn. Àmọ́ kó tó di ọjọ́ tí wọ́n máa ya ẹ̀ka náà sí mímọ́, omi tó yalé ti fà. Abájọ tí inú wọn fi dùn gan-an. Ní báyìí, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ń lo àjà kan lára ilé alájà méjìlélógójì tó wà nílùú náà, láfikún sí àjà méjìlá lára ilé gogoro kan tí kò jìnnà sí tàkọ́kọ́. A sì tún ń lo àwọn ilé míì tí ò ṣe gogoro ládùúgbò náà fún àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì. Arákùnrin Anthony Morris tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí lo sọ àsọyé ìyàsímímọ́ náà. Lọ́jọ́ kejì, àwọn 15,257 ló pé jọ sí pápá ìṣeré láti gbọ́ àsọyé tí Arákùnrin Morris sọ tó ní àkòrí náà “Máa Fi Ìfaradà Ṣe Iṣẹ́ Rere Nìṣó.” A ṣe àtagbà ètò náà sáwọn ibi mọ́kànlélógójì [41], àwọn tó sì pé jọ síbẹ̀ jẹ́ 11,189. Ìkórajọ yìí ni ìgbà àkọ́kọ́ táwọn èèyàn Jèhófà tó péjọ máa pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà. Ọ̀kan lára àwọn míṣọ́nnárì tó kọ́kọ́ sìn lórílẹ̀-èdè náà, ìyẹn Ronald Jacka, sọ pé: “Lọ́dún 1951 tí mo dé sórílẹ̀-èdè yìí, gbogbo akéde tó wà kò ju mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26]. Àmọ́ lónìí, àwọn tó pé jọ síbi àkànṣe ìpàdé yìí lé ní 26,000. Ó dájú pé Jèhófà ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà!”