Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016

 ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Lọ́nà Tó Túbọ̀ Yára

Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Lọ́nà Tó Túbọ̀ Yára

OHUN ayọ̀ gbáà ló jẹ́ fún wa láti rí bí Jèhófà ṣe ń mú kí ìsìn tòótọ́ gbilẹ̀ karí ayé lọ́nà tó yára kánkán! (Aísá. 60:22) Torí náà, a tún nílò àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba púpọ̀ sí i tí a ó ti máa jọ́sìn. Karí ayé, Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tá a nílò àtàwọn tó ń fẹ́ àtúnṣe ju ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá [13,000] lọ.

Kí iṣẹ́ náà lè túbọ̀ yára kánkán kó sì dínwó, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń ṣe àwọn ìyípadà kan ní àwọn ẹ̀ka tó ń bójú tó ilé kíkọ́. Wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá ẹ̀ka tuntun kan sílẹ̀ lóríleeṣẹ́ wa ní Brooklyn, New York, tí wọ́n pè ní Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ Kárí Ayé (WDC), ẹ̀ka yìí sì ti ń ṣiṣẹ́ kára lórí bí iṣẹ́ ìkọ́lé àti àtúnṣe àwọn Gbọ̀ngàn wa á ṣe  gbé pẹ́ẹ́lí sí i kárí ayé. Bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ Láwọn Ilẹ̀ Kan (RDC) tó wà ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì ti Australasia, Central Europe, South Africa àti Amẹ́ríkà náà ń ṣètò bí wọ́n á ṣe máa kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní àwọn àgbègbè tó wà lábẹ́ wọn, lọ́nà tó yára kánkán tó sì dínwó. Àwọn ẹ̀ka RDC yìí tún dá àwọn ẹ̀ka kéékèèké tó wà lábẹ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n á ṣe máa mójú tó àwọn gbọ̀ngàn náà. Ìyẹn nìkan kọ́, ní àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ̀ọ̀kan, a ní ẹ̀ka tí wọ́n ń pè ní Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó Sì Ń Kọ́ Ọ ní Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Kọ̀ọ̀kan (LDC) tó ń ṣètò kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ àti Gbọ̀ngàn Ìjọba àti bí àwọn ará á ṣe máa mójú tó o.

Ní January 2015, gbogbo àwọn alàgbà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pésẹ̀ sí ìpàdé kan tí wọ́n fi fídíò ṣe àtagbà rẹ̀. Nínú ìpàdé yẹn ni ètò Ọlọ́run ti ṣàlàyé ètò tuntun tí a ò máa lò láti pilẹ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba, láti kọ́ ọ àti láti máa mójú tó o. Díẹ̀ nínú àwọn ohun tí wọ́n kọ́ rèé:

  • Kíkọ́ Ọ: Ìgbìmọ̀ Ìṣèwéjáde lá máa fi ìlànà kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba lélẹ̀. Ohun tí wọ́n máa kọ́ fáwọn ará sì gbọ́dọ̀ bá ipò àyíká wọn mu. Gbọ̀ngàn náà á jẹ́ èyí tó lálòpẹ́, tó bágbà mu, tó sì dínwó.

  • Mímójú tó O: Wọ́n máa dá àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ní ìjọ kọ̀ọ̀kan lẹ́kọ̀ọ́ láti máa mójú tó àwọn gbọ̀ngàn náà kí wọ́n lè lálòpẹ́.

Tá a bá wòó, iṣẹ́ ńlá niṣẹ́ yìí, kò sì rọrùn láti máa mójú tó o. Àmọ́, báwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ á túbọ̀ mú kí iṣẹ́ náà yárá lọ́nà tá á fi hàn pé à ń lo àwọn ọrẹ tó ń wọlé lọ́nà tó mọ́gbọ́ dání.