Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Rọ́ṣíà: Wọ́n ń wàásù ìhìn rere nílùú Moscow

 ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

Ìròyìn Nípa Àwọn Ẹjọ́

Ìròyìn Nípa Àwọn Ẹjọ́

A Forúkọ Ẹ̀sìn Wa Sílẹ̀ Lábẹ́ Òfin

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò nílò pé ká forúkọ wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin ká tó lè jọ́sìn Ọlọ́run wa. Àmọ́ tá a bá forúkọ wa sílẹ̀, àá lè háyà tàbí ká kọ́ àwọn ibi tá a ti ń ṣe àwọn ìpàdé wa, àá sì lè máa kó àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọ̀lú.

 • Lọ́dún 2004, ilé ẹjọ́ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fagi lé àjọ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò lábẹ́ òfin ní ìlú Moscow. Èyí ló fà á táwọn ará wa ní ìlú Moscow fi ń dojú kọ ọ̀pọ̀ ìdààmú. Bí àpẹẹrẹ, ṣe ni àwọn ọlọ́pàá ń fòòró ẹ̀mí wọn, tí àwọn ará ìlú ò sì jẹ́ káwọn ará wa fẹ̀dọ̀ lórí òróǹro lóde ẹ̀rí. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó nilé tá a ti ń ṣèpàdé ní ká kó jáde, ó wá di pé káwọn ará máa wá ibi tí wọ́n á ti máa ṣèpàdé wọn. Lọ́dún 2010, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ECHR) jẹ́ kó ṣe kedere pé lóòótọ́ ni orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà fi ẹ̀tọ́ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Moscow ní lábẹ́ òfin dù wá, ó sì pàṣẹ pé kí ìjọba orílẹ̀-èdè náà rí i dájú  pé wọ́n dá gbogbo ẹ̀tọ́ wa pa dà fún wa. Inú wa dùn láti sọ fún yín pé ní May 27, 2015, Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ ti Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà, Ẹ̀ka ti ìlú Moscow ti fi orúkọ ẹ̀sìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní ìlú Moscow.

Owó Orí

Kárí ayé, àwọn ìjọba ayé kì í béèrè pé káwọn àjọ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò san owó orí, bó ṣe jẹ́ pé wọn kì í sọ pé káwọn àjọ ẹlẹ́sìn àtàwọn ẹgbẹ́ aláàánú sanwó orí. Àmọ́ nígbà míì, àwọn ìjọba kan máa ń sọ pé àfi dandan ká sanwó orí.

 • Lórílẹ̀-èdè Sweden, ìjọba sọ pé ilé iṣẹ́ ni Bẹ́tẹ́lì jẹ́, pé ṣe ni a gba àwọn ará tó wà níbẹ̀ síṣẹ́, àti pé wọn kì í ṣe òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tó ń ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run. Kódà, ìjọba náà ti ń ṣírò ẹgbẹẹgbẹ̀rún owó Yúrò tí wọ́n máa bù lé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa àti ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ará wa tó wà níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí owó orí. Ohun tí wọ́n dáwọ́ lé yìí ló mú káwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Sweden gbé ọ̀rọ̀ yìí lọ sáwọn ilé ẹjọ́ tó wà lórílẹ̀-èdè náà. Yàtọ̀ síyẹn, a tún gbé ẹjọ́ mẹ́fà míì lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ECHR).

Ẹ̀rí Ọkàn Wa Kò Gbà Wá Láyè Láti Ṣiṣẹ́ Ológun

Ojú pàtàkì làwa èèyàn Jèhófà fi wo àṣẹ tó wà nínú Bíbélì pé káwọn olùjọsìn tòótọ́ “fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀” kí wọ́n má sì “kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.” (Aísá. 2:4) A pinnu pé a ò ní ṣe iṣẹ́ ológun, àmọ́ a gbà láti ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú míì dípò iṣẹ́ ológun. Síbẹ̀, àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè kan ní àwọn ò gbà, àfi ká ṣiṣẹ́ ológun.

 • Òfin tí orílẹ̀-èdè South Korea ń lò báyìí kò fàyè gba ẹni tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ sọ pé kó má ṣe lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ológun. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé láti ohun tó ju ọgọ́ta [60] ọdún sẹ́yìn, àwọn arákùnrin tó lé lẹ́gbẹ̀rún méjìdínlógún [18,000] ni ìjọba ti jù sẹ́wọ̀n torí pé wọn ò wọṣẹ́ ológun. Bóyá ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wà lórílẹ̀-èdè yẹn tí èèyàn rẹ̀ tàbí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan kò wẹ̀wọ̀n rí lórí ọ̀rọ̀ yìí. Lọ́dún 2004 àti 2011, Ilé Ẹjọ́ Ìjọba Ilẹ̀ South Korea sọ pé ó bófin mu báwọn ṣe ń fi àwọn ará wa sẹ́wọ̀n. Àmọ́ nígbà tó di July 2015, Ilé Ẹjọ́ yìí jókòó láti tún  ẹjọ́ náà gbọ́. Àdúrà táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé ń gbà ni pé kí  ọ̀rọ̀ yìí yọrí síbi tó dáa, kí wọ́n má ṣe tún máa ju àwọn arákùnrin wa lórílẹ̀-èdè South Korea sẹ́wọ̀n mọ torí pé wọ́n ń sin Ọlọ́run.

 • Ọdún yìí ló máa pé ọdún kejìlélógún [22] táwọn arákùnrin wa mẹ́ta ti wà látìmọ́lé lórílẹ̀-èdè Eritrea torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè láti wọṣẹ́ ológun. Àwọn náà ni Paulos Eyassu, Negede Teklemariam àti Isaac Mogos. Èyí tó burú níbẹ̀ ni pé ìjọba ilẹ̀ náà kò gbọ́rọ̀ náà lọ ilé ẹjọ́, wọn ò sì gbà wá láyè láti gbèjà ara wa nílé ẹjọ́. Yàtọ̀ sáwọn arákùnrin yìí, àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó lé láàádọ́ta [50] míì ni ìjọba ń pọ́n lójú láwọn ilé ẹ̀wọ̀n tó burú jáì. Láìfi gbogbo ìyẹn pè, àwọn ará wa di ìgbàgbọ́ wọn mú. Ó dá wa lójú pé elétí-gbáròyé ni Jèhófà, ó ń kíyè sí “ìmí ẹ̀dùn” àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí ìgbàgbọ́ wọn, ó sì dá wa lójú pé Jèhófà á dá sọ́rọ̀ náà.Sm. 79:11.

 • Lórílẹ̀-èdè Ukraine, ìjọba ní kí Arákùnrin Vitaliy Shalaiko wá sí bárékè àwọn ológun ní August 2014 kó lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ológun. Torí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ kò gbà á láyè láti ṣe iṣẹ́ ológun, ó sọ fún wọn pé kí wọ́n jẹ́ kóun ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun. Ní ìjọba bá gbọ́rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́, wọ́n fẹ̀sùn kan Arákùnrin Shalaiko pé kò fẹ́ wọṣẹ́ ológun, àmọ́ ilé ẹjọ́ àkọ́kọ́ àti ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sọ pé ẹjọ́ arákùnrin wa tọ́, torí náà kò jẹ̀bi. Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sọ pé ó dáa bí ìjọba ṣe  ń ṣàníyàn nípa ààbò ìlú, àmọ́ ìyẹn ò wá ní kí wọ́n fẹ̀tọ́ àwọn èèyàn dù wọ́n. Ó tún sọ pé, “ẹ ò lè sọ pé káwọn èèyàn ṣe ohun tó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn wọn torí pé ẹ fẹ́ dáàbò bo ìlú.” Ìdájọ́ yẹn ò tẹ́ ìjọba lọ́rùn, wọ́n bá tún gbéra, ó dilé ẹjọ́ gíga. Ní June 23, 2015, Àkànṣe Ilé Ẹjọ́ Gíga Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ìlú àti Ìwà Ọ̀daràn ní Orílẹ̀-èdè Ukraine sọ pé òun fara mọ́ ìdájọ́ àwọn ilé ẹjọ́ tí wọ́n ti kọ́kọ́ gbẹ́jọ́ náà. Nípa bẹ́ẹ̀, ilé ẹjọ́ gíga yìí sọ pé àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà wọ́n láyè láti ṣe iṣẹ́ ológun lè ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú míì, kódà lásìkò tí nǹkan ò fara rọ nílùú.

Ukraine: Vitaliy Shalaiko gbádùn kó máa wàásù

Pẹ̀lú ibi tí wọ́n fẹnu ọ̀rọ̀ náà jóná sí yìí, báwo ló ṣe rí lára Arákùnrin Shalaiko? Ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Jeremáyà 1:19, fún mi lókun gan-an ni. Mo ti ní in lọ́kàn pé ibi yòówù kọ́rọ̀ náà já sí, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kí n ṣáà ti jólóòótọ́ sí Jèhófà. Ó dá mi lójú pé kò ní fi mí sílẹ̀ rára, kàkà bẹ́ẹ̀ á fún mi lágbára láti dìgbàgbọ́ mi mú. Àmọ́, ibi tọ́rọ̀ náà já sí yà mí lẹ́nu gan-an. Ilé ẹjọ́ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ló dá mi láre. Àwọn ará tì mí lẹ́yìn ní gbogbo ìgbà tá a fi ń lọ sókè sódò yẹn, wọn ò fi mí sílẹ̀.”

À Kì Í Dá Sọ́rọ̀ Òṣèlú àti Ayẹyẹ Orílẹ̀-èdè

Àwọn èèyàn tún máa ń fínná mọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí pé à kì í dá sọ̀rọ̀ ayẹyẹ orílẹ̀-èdè. Níléèwé, àwọn aláṣẹ máa ń fúngun mọ́ àwọn ọmọ wa pé kí wọ́n ṣe ohun tó lódì sí ìfẹ́ Jèhófà, wọ́n á ní àfi dandan kí wọ́n kọ orin orílẹ̀-èdè tàbí kí wọ́n kí àsíá.

 • Ní àgbègbè Karongi, lórílẹ̀-èdè Rùwáńdà, àwọn aláṣẹ iléèwé fẹ̀sùn kan àwọn ọmọ wa kan pé wọn ò bọ̀wọ̀ fún orin orílẹ̀-èdè wọn torí pé wọn ò kọrin orílẹ̀-èdè náà. Torí bẹ́ẹ̀, wọ́n lé àwọn ọmọ náà kúrò níléèwé, kódà wọ́n tún fi wọ́n sẹ́wọ̀n. Ọ̀rọ̀ náà délé ẹjọ́, nígbà tó sì dí November 28, 2014, Ilé Ẹjọ́ Karongi sọ pé àwọn ọmọ náà ò jẹ̀bi, ó sì jẹ́ kó ṣe kedere pé béèyàn ò bá kọrin orílẹ̀-èdè, kò túmọ̀ sí pé kò bọ̀wọ̀ fún orílẹ̀-èdè rẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè míì ní Áfíríkà tí wọ́n ti ń fúngun mọ àwọn ọmọ wa tí wọ́n sì ń lé wọn kúrò níléèwé ni Kamẹrúùnù, Democratic Republic of Congo, Equatorial Guinea àti Màláwì. Àwọn ará wa tó wà lórílẹ̀-èdè yẹn ń sapá láti jẹ́ kí ìjọba àtàwọn aláṣẹ iléèwé lóye ìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi lọ́wọ́ sí ayẹyẹ orílẹ̀-èdè tàbí òṣèlú.

 • Honduras: Wọ́n pàpà fún Mirna Paz àti Bessy Serrano níwèé ẹ̀rí wọn

    Ní December 2013, iléèwé ìjọba kan tó wà nílùú Lepaera, lórílẹ̀-èdè Honduras, kọ̀ jálẹ̀ pé òun ò ní fún àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì ní ìwé ẹ̀rí torí pé wọn ò kọrin orílẹ̀-èdè, wọn ò sì ka ẹ̀jẹ́ orílẹ̀-èdè níwájú àsíá. Kí làwọn ará wa ṣe? Àwọn ará wa méjì tí wọ́n jẹ́ agbẹjọ́rò lọ bá ẹnì kan tó jẹ́ aṣojú ìjọba ní Ilé-Iṣẹ́ Ètò Ẹ̀kọ́ kí wọ́n lè yanjú ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n jẹ́ kó mọ bí àwọn ilé ẹjọ́ lórílẹ̀-èdè míì ṣe dá àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre nígbà tí wọ́n bójú tó irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Èèyàn dáadáa lọkùnrin ọ̀hún, ó ní káwọn ọmọléèwé náà àtàwọn òbí wọn kọ ẹ̀dùn ọkàn wọn síwèé, kí wọ́n mú un lọ fún ọ̀gá tó ń bójú tó ọ̀ràn ẹjọ́ ní ọ́fíìsì Ilé-Iṣẹ́ Ètò Ẹ̀kọ́ lórílẹ̀-èdè Honduras. Lẹ́yìn yíyiri ọ̀rọ̀ náà wo, ó sọ fáwọn tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ lórílẹ̀-èdè náà ní July 29, 2014, pé, “gbogbo èèyàn tó wà lórílẹ̀-èdè wa ló lẹ́tọ̀ọ́ láti lọ́ síléèwé láìka ẹ̀sìn tónítọ̀hún ń ṣe sí tàbí ohun tó gbà gbọ́,” ó sì sọ fún iléèwé táwọn ọmọ náà wà pé kí wọ́n fún àwọn ọmọ náà níwèé ẹ̀rí wọn kíá.

Ìjọba Ń Ṣe Ẹ̀tanú sí Wa

Níbi gbogbo táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà láyé, a máa ń pa àṣẹ Jésù mọ́ tó sọ pé ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn, ká máa kóra jọ pẹ̀lú àwọn ará wa láti jọ́sìn Ọlọ́run, ká sì máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé. Bẹ́ẹ̀ la ò kóyán àṣẹ tí Bíbélì pa fún wa kéré pé ká máa gbin òfin Jèhófà sínú àwọn ọmọ wa, ká sì “ta kété . . .  sí ẹ̀jẹ̀.” (Ìṣe 15:20; Diu. 6:5-7) Àmọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn aláṣẹ ìjọba máa ń ṣì wá lóye nígbà tá a bá rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà yìí, èyí sì máa ń fa ìforígbárí.

 • Bí àpẹẹrẹ, ní ìpínlẹ̀ Florida lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tọkọtaya kan gbẹ́jọ́ lọ sílé ẹjọ́ pé kí ilé ẹjọ́ pinnu èwo nínú àwọn méjèèjì ló yẹ kó máa fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kọ́ àwọn ọmọ wọn mẹ́ta. Adájọ́ sọ pé ìyá tó jẹ́ onísìn Kátólíìkì nìkan ni kó máa ṣe bẹ́ẹ̀, bàbá ò gbọ́dọ̀ fohun tó yàtọ̀ síyẹn kọ́ wọn. Bí ọkọ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ṣe gbẹ́jọ́ lọ sílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn nìyẹn, nígbà tó sì máa di August 18, 2014, ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn da ẹjọ́ àkọ́kọ́ nù. Irú ẹjọ́ yìí ti wáyé láwọn ilé ẹjọ́ kan sẹ́yìn, torí náà ìpinnu táwọn yẹn ṣe nilé ẹjọ́ yìí náà gbé ìpinnu wọn kà, wọ́n wá sọ pé: “Léraléra làwọn ilé ẹjọ ti jẹ́ kó ṣe kedere pé òbí kan lẹ́tọ̀ọ́ láti fọ̀rọ̀ ẹ̀sìn tiẹ̀ kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ kọ́ làwọn ọmọ náà ń gbé. Ìdí táwọn ilé ẹjọ́ fi sọ bẹ́ẹ̀ ni pé kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé irú ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀ á pa ọmọ náà lára.”

  Ìdájọ́ yìí mú káwọn ọmọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí láǹfààní àtikẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà láìsí ìdíwọ́, wọ́n sì ń rí ìtọ́ni tó wúlò gbà. Ní báyìí, wọ́n ń tẹ̀ síwájú gan-an nínú ìjọsìn wọn bí wọ́n ṣe ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé. Bàbá àwọn ọmọ yìí sọ pé: “Bí mo ṣe fara da ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ti tún mú kí ìgbàgbọ́ mi lágbára sí i. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló dán ìgbàgbọ́ mi wò lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àmọ́ mo dúpẹ́ pé Jèhófà ò jẹ́ kí n yẹsẹ̀! Mo mọ̀ pé látìgbà tá a ti pinnu pé a máa sin Jèhófà la ti gbà pé àá dojú kọ inúnibíni.”

 • Namibia: Efigenia Semente rèé pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta

  Orílẹ̀-èdè Nàmíbíà ni Arábìnrin Efigenia Semente ń gbé, ọmọ mẹ́ta ló ní, òun náà sì ti fojú winá ìdánwò ìgbàgbọ́. Ilé ìwòsàn ló wà nígbà tó bí ọmọ kẹta, bó ṣe di pé ọ̀rọ̀ náà fẹ́ yíwọ́ nìyẹn. Ẹnu ìyẹn ló wà tí àwọn nọ́ọ̀sì àtàwọn dókítà kan, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí lára ẹbí rẹ̀ wá bá a pé, àfi dandan kárábìnrin wa gbẹ̀jẹ̀, kódà wọ́n lọ gbàwé àṣẹ ní kóòtù. Gbogbo agbára tí Arábìnrin Semente ní lo fi gbèjà ara rẹ̀ pé òun ò gbẹ̀jẹ̀, òun náà sì gbalé ẹjọ́ lọ kí wọ́n lè mọ̀ pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu irú ìtọ́jú tí òun fẹ́. Ní June 24, 2015, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Nàmíbíà gbèjà Arábìnrin Semente, wọ́n sì sọ pé, “olúkúlùkù èèyàn ló lẹ́tọ̀ọ́ láti yan ohun tó fẹ́ àtohun tí kò fẹ́ ká ṣe sí òun, yálà èèyàn jẹ́ òbí tàbí bẹ́ẹ̀ kọ̀. Ẹ̀tọ́ gbogbo wa ni, ẹnì kan kò sì gbọ́dọ̀ fi ẹ̀tọ́ yìí du ẹlòmíì.” Arábìnrin Semente sọ pé:  “A rọ́wọ́ Jèhófà lára wa lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. A dúpẹ́ pé a wà lára ẹgbẹ́ ará kárí ayé. Òótọ́ ò ní á má sọ̀un, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.”

 • Kì í ṣèní kì í ṣàná táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Switzerland ti ń wàásù láwọn ìlú ńlá níbi térò ti ń lọ tí wọ́n ń bọ̀. Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn aláṣẹ ìlú Geneva pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ “pàtẹ ohunkóhun tó ń polongo ẹ̀sìn ní tààràtà tàbí lọ́nà tí kò ṣe tààràtà láwọn ibi térò pọ̀ sí.” Àwọn ará wa gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́, wọ́n jẹ́ kó ṣe kedere pé tí ìjọba bá sọ pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ pàtẹ ohunkóhun tó ń polongo ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, “a jẹ́ pé àwọn èèyàn kò ní lómìnira láti ṣe ẹ̀sìn tó wù wọ́n nìyẹn, wọ́n ò sì ní lè sọ̀rọ̀ fàlàlà.” Ilé ẹjọ́ fara mọ́ èrò àwọn ará wa, ní báyìí ìjọba ti gbà láti fikùnlukùn pẹ̀lú àwọn ará wà kí wọ́n lè jọ wo àwọn ibi térò máa ń wà tá a lè máa pàtẹ àwọn ìwé wa sí.

 • Àwọn aláṣẹ ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan ti wá tẹra mọ ogun tí wọ́n ń bá àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jà, wọ́n sì ń wá bí wọ́n á ṣe paná ìjọsìn wa. Ìgbà gbogbo ni Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ààbò Ìlú máa ń ké sí àwọn ará wa, tí wọ́n á sì da ìbéèrè bo ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Wọ́n tún máa ń lọ sílé àwọn ará, wọ́n á tú gbogbo ẹrù ilé wọn yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́. Kí ni wọ́n ń wá? Àwọn ìwé tí ìjọba sọ pé kò gbọ́dọ̀ wọ̀lú. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fáwọn èèyàn níbi gbogbo láyé nígbà tí wọn gbọ́ ohun tí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó  Ààbò Ìlú ṣe ní February 2015. Wọ́n ti àwọn ará wa méjì mọ́lé, ìyẹn Irina Zakharchenko àti Valida Jabrayilova, torí pé wọ́n ń sọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún aládùúgbò wọn. Ó dùn wá pé ìjọba ń fọwọ́ ọlá gbá àwọn ará wa lójú lọ́nà yìí, àmọ́ inú wa ń dùn pé àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Azerbaijan ò jẹ́ kóhun tí ìjọba ń ṣe sí wọn yìí paná ìtara wọn, wọ́n sì túbọ̀ ń fìgboyà wàásù “ìhìn rere Ìjọba” Ọlọ́run fáwọn aládùúgbò wọn.Mát. 24:14.

 • Ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà kò fojúure wo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà rárá, ṣe ni wọ́n ṣáà ń dí ìjọsìn wa lọ́wọ́. Ní báyìí, ọgọ́rin [80] lára àwọn ìtẹ̀jáde wa ni Ìjọba Àpapọ̀ orílẹ̀-èdè náà kà sí ìwé tó kún fún ọ̀rọ̀ “àwọn agbawèrèmẹ́sìn.” Torí bẹ́ẹ̀, bí wọ́n bá rí èyíkéyìí lára àwọn ìwé bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ ẹnì kan, títí kan Ìwé Ìtàn Bíbélì, tàbí tó ń pín in kiri, onítọ̀hún ti lùfin ìjọba nìyẹn. Wọn ò mà fi mọ síbẹ̀ o, ní December 2014, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà gbẹ́sẹ̀ lé ìkànnì wa, ìyẹn jw.org, wọ́n sọ pé ìkànnì “àwọn agbawèrèmẹ́sìn” ni. Ìyẹn wá mú káwọn tó ń rí sí ọ̀rọ̀ íńtánẹ́ẹ̀tì lórílẹ̀-èdè náà dínà mọ́ Ìkànnì jw.org. Tí ìjọba bá sì rí ẹnikẹ́ni tó ń rọ àwọn èèyàn láti máa lo ìkànnì yìí, arúfin ni wọ́n á pe onítọ̀hún. Yàtọ̀ síyẹn, láti March 2015, àwọn ọ̀gá aṣọ́bodè kò tún gbà mọ́ pé káwọn ìwé wa máa wọ orílẹ̀-èdè náà, títí kan Bíbélì àtàwọn ìwé wa míì tí kò sí lára àwọn ìwé tí ilé ẹjọ́ kà sí ìwé “àwọn agbawèrèmẹ́sìn.”

Ọ̀rọ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa nílùú Taganrog ṣì wà nílé ẹjọ́. Ẹ rántí pé àwọn aláṣẹ ibẹ̀ sọ pé “ọ̀daràn” làwọn ará wa mẹ́rìndínlógún [16] torí pé wọ́n kó ara wọn jọ láti jọ́sìn. Bákan náà nílùú Samara, àwọn aláṣẹ ti lọ sílé ẹjọ́ láti fòfin de ìgbòkègbodò wa, wọ́n ní “agbawèrèmẹ́sìn” ni wá. Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé gbogbo ohun táwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ń ṣe kò tu irun kan lára àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin? Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n túbọ̀ ń fi “àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run,” wọ́n ò jẹ́ kíwà àwọn èèyàn náà dí wọn lọ́wọ́.Mát. 22:21.