Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016

 ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ

Ìmọ́lẹ̀ Ń Mọ́lẹ̀ Sí I

Ìmọ́lẹ̀ Ń Mọ́lẹ̀ Sí I

TORÍ pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mọ̀ pé Jèhófà ni Orísun ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí tàbí pé Òun ló lè jẹ́ káwọn lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n máa ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ‘ìmọ́lẹ̀ àti òtítọ́’ máa tọ́ àwọn sọ́nà, kó sì máa darí àwọn. (Sm. 43:3) Bí ayé yìí ṣe túbọ̀ ń jìn sínú òkùnkùn birimùbirimù, ṣe ni Jèhófà túbọ̀ ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ máa ṣamọ̀nà àwa èèyàn rẹ̀. Èyí wá mú kí ipa ọ̀nà wa “dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i.” (Òwe 4:18) Bí Jèhófà ṣe túbọ̀ ń fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ṣamọ̀nà wa ti mú kí ọ̀nà tá a gbà ṣètò àwọn nǹkan túbọ̀ dára sí i, bẹ́ẹ̀ sì làwọn ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ àti ìwà wa ń sunwọ̀n sí i. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àtúnṣe tó wáyé lẹ́nu àìpẹ́ yìí sáwọn ohun tá a gbà gbọ́?