Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Bòlífíà: Wọ́n ń kọ́ ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè Aymara ní ìlú El Alto

Àwọn Ohun Pàtàkì Tó Ṣẹlẹ̀ Lọ́dún Tó Kọjá

Àwọn Ohun Pàtàkì Tó Ṣẹlẹ̀ Lọ́dún Tó Kọjá

NÍGBÀ tí Bíbélì ń ṣàlàyé ohun tí Ọlọ́run máa gbé ṣe nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀, Áísáyà 9:7 sọ pé: “Ìtara Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò ṣe èyí.” Bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba yẹn ṣe fi ìtara tó lé kenkà hàn fún ìjọsìn tòótọ́ jálẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Jòh. 2:17) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé náà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù bá a ṣe ń fi ìtara wàásù káwọn èèyàn lè wá jadùn ìfẹ́ Jèhófá, Bàbá wa ọ̀run. Àwọn ìròyìn tó tẹ̀ lé e yìí fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.

El salvador: Àpéjọ agbègbè 2015

NÍ APÁ YÌÍ

“Àwọn Ètò Orí Tẹlifíṣọ̀n JW Ti Lọ Wà Jù!”

Àwọn ìmúrasílẹ̀ wo la ṣe ká lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbóhùn sáfẹ́fẹ́ lórí ètò Tẹlifíṣọ̀n JW tá à ń wò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?

Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Lọ́nà Tó Túbọ̀ Yára

A ti ṣe àwọn ìyípadà kan ká lè kọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn gbọ̀ngàn tuntun tá a nílò.

Báwo Ni Iṣẹ́ Ṣe Ń Lọ Sí Ní Warwick?

Wo àlàyé díẹ̀ nípa ibi tí iṣẹ́ ìkọ́lé dé ní oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Tí A Kì Í Bá Nílé

Kí ló mú kí Terry gbà pé ohun tí òun gbọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ìdáhùn sí àdúrà òun?

Ìmọ́lẹ̀ Ń Mọ́lẹ̀ Sí I

Ní apá yìí, wà á rí bí Jèhófà ṣe ń tànmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́.

A Ya Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Sí Mímọ́

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2015, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè Madagásíkà àti Indonéṣíà rí ìbùkún àrà ọ̀tọ̀ kan gbà.

A Mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde Láwọn Èdè Míì

Àwọn èdè tá a mú jáde lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2015 jẹ́ mẹ́rìndínlógún.

Ìròyìn Nípa Àwọn Ẹjọ́

Ọ̀pọ̀ ibi kárí ayé láwọn èèyàn ti ń ṣe ẹ̀tanú sí wa, èyí tó mú ká máa gbọ́rọ̀ relé ẹjọ́.

Ìròyìn—Nípa Àwọn Ará Wa

Ohun tó wà nínú àpótí tí ọmọdékùnrin Ken ṣe pamọ́ wúlò gan-an nígbà tá a ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba.