Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Ísírẹ́lì: Wọ́n ń lo ẹ̀rọ alágbèéká láti wàásù ìhìn Ìjọba Ọlọ́run

 À Ń WÀÁSÙ A SÌ Ń KỌ́NI KÁRÍ AYÉ

Éṣíà àti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé

Éṣíà àti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé
  • ILẸ̀ 49

  • IYE ÈÈYÀN 4,409,131,383

  • IYE AKÉDE 718,716

  • IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 766,364

Ọgọ́rùn-ún Wákàtí fún Ọgọ́rùn-ún Ọdún

Lórílẹ̀-èdè kan ní ilẹ̀ Éṣíà, gbajúgbajà òṣèré orí tẹlifíṣọ̀n kan gbà pé ká máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ tóbìnrin yìí fi bẹ̀rẹ̀ sí í fohun tó ń kọ́ sílò, ó kó gbogbo ìwé oògùn tó ń lò dànù títí kan àwọn ọmọlángidi tó ń lò nínú ẹ̀sìn Búdà tó ń ṣe.

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́mọnú obìnrin náà rọ̀ ọ́ pé: “O ò ṣe dá ìkẹ́kọ̀ọ́  tó ò ń ṣe yìí dúró ná fún ọdún mẹ́ta péré kó o lè pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ rẹ? Tó bá sì yá, wàá tún pa dà sídìí ẹ̀kọ́ rẹ.”

Nígbà tóbìnrin náà máa fèsì, ó ní: “Ọdún kẹrìnlélógún [24] rèé ti mo ti ń wá Jèhófà. Kí nìdí tí màá fi wá sọ pé ó dẹ̀yìn ọdún mẹ́ta míì kí n tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀?”

Lọ́sẹ̀ ti obìnrin náà máa ṣe iṣẹ́ àkọ́kọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ilé iṣẹ́ ńlá kan tó máa ń bá ṣe fíìmù pè é. Wọ́n ní kó wá bá wọn ṣe iṣẹ́ ọlọ́dún mẹ́rin kan tó máa mú èrè rẹpẹtẹ wá fún un, àmọ́, apá èyíkéyìí tí àwọn bá ní kó ṣe nínú fíìmù náà ló ní láti ṣe. Kò tiẹ̀ rò ó lẹ́ẹ̀mejì tó fi sọ pé òun ò ṣe. Nígbà tó fi máa di oṣù May, ọdún 2014, ó di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, ó wá pinnu pé tó bá fi máa di oṣù August, òun á lo ọgọ́rùn-ún wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Nígbà tí wọ́n bi í pé kí nìdí tó fi fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní, “Mo fẹ́ ṣayẹyẹ ọgọ́rùn-ún ọdún ti Jésù ti wà lórí ìtẹ́, torí náà, màá lo wákàtí kan fún ọdún kan ìṣàkóso Kristi!” Ọ̀rọ̀ yìí kọjá ẹnu lásán, ohun tó ṣe gan-an nìyẹn. Ó ṣèrìbọmi ní January 2015, ní báyìí o ti di aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.

A Ráyè Wàásù Lálẹ́ Ọjọ́ Tá A Sun Àtìmọ́lé

Lórílẹ̀-èdè Siri Láńkà, arábìnrin mẹ́rin wọkọ̀ bọ́ọ̀sì láti lọ wàásù ní ìpínlẹ̀ kan tí a kò pín fúnni. Àwọn onísìn Búdà pọ̀ gan-an lágbègbè yẹn. Lọ́jọ́ kejì, ọ̀kan lára àwọn ẹlẹ́sìn Búdà àti awakọ̀ takisí kan wá bá àwọn arábìnrin náà. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, àwọn èèyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgbọ̀n [30] ti ṣùrù bò wọ́n. Ẹnu ẹ̀ ni wọ́n wà táwọn ọlọ́pàá dé, wọ́n mú àwọn arábìnrin náà lọ sí àgọ́ wọn, wọ́n sì tì wọ́n mọ́lé lóru mọ́jú láìṣẹ̀ láìrò. Àwọn ọ̀daràn ayé òun ọ̀run ni wọ́n jọ wà látìmọ́lé náà, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n rọ̀jò èébú lé àwọn arábìnrin náà lórí, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀ rírùn sí wọn. Láìfi yẹn pè, àwọn ará wa lo  àǹfààní tí wọ́n ni yẹn láti wàásù. Ọ̀kan lára àwọn arábìnrin náà sọ pé: “Lóòótọ́ àwọn apààyàn la jọ wà látìmọ́lé, àmọ́ mó ráyè bá wọn sọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó yà wọ́n lẹ́nu pé wọ́n fi wá sátìmọ́lé, àìmọye ìbéèrè ni wọ́n sì ń béèrè, wọ́n fẹ́ mọ ohun tí mo gbà gbọ́. Ọ̀kan lára wọn tiẹ̀ bi mí pé, ‘Kí làṣírí ayọ̀ rẹ gan-an?’”

Siri Láńkà: Àwọn arábìnrin mẹ́rin yìí wọkọ̀ bọ́ọ̀sì láti lọ wàásù ní ìpínlẹ̀ kan tí a kò pín fúnni

Ọ̀rọ̀ yìí ti dé Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Siri Láńkà, wọ́n sì gbà láti dá sọ́ràn náà, pé kí àwọn ọlọ́pàá ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi fẹ̀tọ́ tá a ní lábẹ́ òfin dù wá, tí wọ́n sì fi wá sátìmọ́lé láìdúró gbẹ́jọ́. À ń rétí ìgbà tí ilé ẹjọ́ máa jókòó.

A Ṣèrànwọ́ fún Obìnrin Tó Wà Lórí Ìdùbúlẹ̀ Tọ̀sán-tòru

Aṣáájú-ọ̀nà ni Arábìnrin Michiko lórílẹ̀-èdè Japan, ó ń kọ́ ìyá àgbàlagbà kan lẹ́kọ̀ọ́ nílé ìwòsàn, èdè àwọn adití ni wọ́n sì fi ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ náà. Arábìnrin yìí wá béèrè lọ́wọ́ àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn náà bóyá àwọn aláìsàn míì wà tóun lè bá sọ̀rọ̀. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Kazumi wà lára àwọn tí Arábìnrin Michiko bá sọ̀rọ̀. Obìnrin yìí máa ń gbọ́rọ̀ àmọ́ kò lè sọ, jàǹbá ọkọ̀ ló sọ ọ́ dẹni tí kò lè dìde lórí bẹ́ẹ̀dì. Ẹni ọdún mẹ́tàlélógún [23] ni nígbà tí jàǹbá náà ṣe é, látìgbà yẹn kò lè gbóúnjẹ mì bẹ́ẹ̀ sì ni kò lè mumi. Ṣe ló ń bi Michiko lọ́pọ̀ ìbéèrè, ó sì gbà kó máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́.

Japan: Kazumi gbádùn kó máa kọ lẹ́tà sáwọn èèyàn láti gbé wọn ró

Nígbà tí wọ́n bá ń kẹ́kọ̀ọ́, Arábìnrin Michiko máa ń bi Kazumi léèrè ọ̀rọ̀, Kazumi á sì fọwọ́ kan ibi tí ìdáhùn wà nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí kó kọ ọ́ sílẹ̀. Ìgbà tó yá, Kazumi ní fóònù, ìyẹn wá jẹ́ kó ṣeé ṣe fún òun àti Arábìnrin Michiko láti jọ máa jíròrò ẹsẹ ojúmọ́ láràárọ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Kazumi ò fi bẹ́ẹ̀ lókun nípa tara, ojoojúmọ́ ló ń lágbára sí i nípa tẹ̀mí débi pé ó sọ fáwọn ará pé òun náà fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó fi máa dẹni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta [61], lẹ́yìn tó ti fi  ọdún mẹ́tàlá [13] kẹ́kọ̀ọ́, Kazumi di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi.

Torí pé orí ìdùbúlẹ̀ ni Kazumi máa ń wà, ìjọ ṣètò pé kí wọ́n máa gbohùn ìpàdé àtàwọn àpéjọ sílẹ̀ sórí ẹ̀rọ, wọ́n á sì fún un kóun náà lè gbádùn rẹ̀. Báwo ni Kazumi ṣe ń lóhùn sípàdé? Àwọn arábìnrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ máa ń ka ìdáhùn tó ti múra sílẹ̀ sétí àwùjọ nípàdé.

Kazumi tún máa ń gbé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ń wá sípàdé ró. Lọ́nà wo? Ó máa ń kọ lẹ́tà sí wọn. Ó máa ń wàásù fáwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn àtàwọn èèyàn tó bá wá kí i. Kazumi máa ń sọ fún wọn pé, “Tó o bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá láyọ̀.”

Ẹlẹ́sìn Ìbílẹ̀ Kẹ́kọ̀ọ́ Òtítọ́

Lórílẹ̀-èdè kan tó wà lápá ìsàlẹ̀ ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Éṣíà, arábìnrin wa kan lọ sọ́dọ̀ àwọn dókítà tó ń tọjú ojú nílé ìwòsàn  kan, ó sì bá ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ níbẹ̀. Arábìnrin wa bí i léèrè pé, “Ṣé wàá fẹ́ kára rẹ jí pépé kó o sì wà láàyè títí láé níbi tó lẹ́wà gan-an?” Bí wọ́n ṣè bẹ̀rẹ̀ sí tàkurọ̀sọ nìyẹn, tí arábìnrin wa sí fún un ní ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run. Ọkùnrin náà fún arábìnrin wa ní nọ́ńbà fóònù rẹ̀, òun náà sì fún arákùnrin kan níjọ wọn ní nọ́ńbà náà kónítọ̀hún lè lọ̀ máa bẹ ọkùnrin náà wò. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí arákùnrin wa kàn sí ọkùnrin náà tó sì sọ fún un pé kó wá gbọ́ àkànṣe àsọyé nípàdé wa. Ó kúkú wá, ó sì gbádùn ìpàdé náà dọ́ba, pàápàá jù lọ àwọn orin ìjọba tá a kọ. Ohun míì tó tún wú u lórí ni báwọn ará ṣe kí i tẹ̀rín tọ̀yàyà.

Ọkùnrin yẹn béèrè lọ́wọ́ àwọn ará pé ṣé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àwọn yunifásítì tá a ti ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn tàbí àwọn ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ àlùfáà, wọ́n sọ fún un pé ńṣe làwa máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé wọn, wọ́n sì fi bá a ṣe máa ń ṣe é hàn án. Nígbà tọ́sẹ̀ yẹn fi máa parí, o ti parí orí 1 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ní báyìí, ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ń lọ ní rabidun, ó ń wá sípàdé, ó sì máa ń lóhùn sípàdé lákòókò Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́.

Nígbà tọ́kùnrin ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ yìí lọ sí àpéjọ àyíká wa kan, ó ṣalábàápàdé ẹnì kan tó wá láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, onítọ̀hún sì rọ̀ ọ́ pé kó ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, tá à ń pè ní Bẹ́tẹ́lì. Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ le e, ọkùnrin yìí rin ìrìn àjò tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó wákàtí mẹ́wàá lọ sí Bẹ́tẹ́lì, nígbà tó dé ọ̀hún, ṣe làwọn ará ń yọ̀ mọ́ ọn. Nígbà tóṣù February ọdún 2015 fi máa parí, ó sọ fáwọn èèyàn ẹ̀ pé òun ò ṣe ẹ̀sìn ìbílẹ̀ mọ́, ó tẹra mọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀, òun náà sì ti ń  kópa tó jọjú láwọn ìpàdé wa.

Ó Sọ Nù, A sì Tún Rí I

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ètò Ọlọ́run rán àwọn aṣáájú-ọ̀nà kan lọ sí apá òkè ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Íńdíà. Ọjọ́ pẹ́ tá a ti wàásù láwọn àgbègbè yẹn kẹyìn, torí náà àwọn ará náà ṣiṣẹ́ gan-an, ọ̀pọ̀ èèyàn lò sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n tiẹ̀ fẹ́ ká kọ́ ilé  ìpàdé wa síbẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń lọ láti lọ kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n rí ilé kan tí wọn ò tíì kọ́ parí, wọ́n kọ́kọ́ fẹ́ lọ wádìí rẹ̀ wò, àmọ́ wọ́n tún pinnu pé káwọn má wulẹ̀ lọ. Ẹ̀ẹ̀kan náà ni wọ́n tún ṣẹ́rí pa dà. Nígbà tí wọ́n máa dé ẹ̀yìn ilé yẹn, wọ́n bá ìyá àgbàlagbà kan pàdé, wọ́n sì sọ fún un pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn. Ó wò wọ́n, ó tún wọn wò, ó bá sọ pé, “Ẹlẹ́rìí Jèhófà lèmi náà.” Inú rẹ̀ dùn, ló bá ní kí wọ́n máa bọ̀ ńlé òun. Ó fi àwọn ìwé wa tó ní látọdún 1970 sí 1989 hàn wọ́n. Ní nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ọdún sẹ́yìn ló kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà kan, ó lọ sáwọn ìpàdé wa láìka pé ọkọ rẹ̀ ta kò ó. Ó dá a lójú pé òun ti rí òtítọ́, àmọ́ nígbà táwọn aṣáájú-ọ̀nà náà fibẹ̀ sílẹ̀, kò rẹ́ni fojú jọ mọ́. Àwọn ọmọ rẹ̀  bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tó wu olúkúlùkù, àmọ́ òun ò lọ ṣọ́ọ̀ṣì kankan.

Íńdíà: Obìnrin tó ti kẹ́kọ̀ọ́ rí yìí ń fi àwọn ìwé tó ti ní látọdún 1970 sí 1989 han àwọn ará

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn ọmọ ìyá náà ń fúngun mọ́ ọn pé kó lọ forúkọ sílẹ̀ ní ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ṣọ́ọ̀ṣì náà kò ní sin ín tó bá kú. Kódà, àbúrò rẹ̀ kan lóun á fi tipátipá mú un lọ, àmọ́ súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ kò jẹ́ kí wọn tètè débẹ̀, bí wọ́n ṣe pa dà sílé nìyẹn. Àbúrò rẹ̀ yẹn sọ pé tó bá dọjọ́ kejì, àwọn á pa dà lọ, àmọ́ ọ̀rọ̀ bẹ́yìn yọ. Kí ló ṣẹlẹ̀? Àìsàn kọ lu àbúrò ìyá náà, ó sì wá jẹ́ pé ọ̀sán ọjọ́ yẹn gan-an làwọn aṣáájú-ọ̀nà bá ìyà náà pàdé! Ó ti pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, ó ń lọ sáwọn ìpàdé, ó sì ń rọ àwọn ọmọ rẹ̀ àtàwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀ pé káwọn náà kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.