Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Brazil: Valdira rèé tó ń lo iná àbẹ́là láti kẹ́kọ̀ọ́, tòun ti fóònù rẹ̀ létí

 À Ń WÀÁSÙ A SÌ Ń KỌ́NI KÁRÍ AYÉ

Àwọn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà

Àwọn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà
  • ILẸ̀ 57

  • IYE ÈÈYÀN 982,501,976

  • IYE AKÉDE 4,102,272

  • IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 4,345,532

Ṣé Wàá Lè Kẹ́kọ̀ọ́ Nínú Oko Lálẹ́ Pẹ̀lú Iná Àbẹ́là

Lọ́jọ́ kan, tọkọtaya aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan lọ ṣiṣẹ́ ní àgbègbè àdádó kan lórílẹ̀-èdè Brazil, ibẹ̀ ni wọ́n ti gbọ́ pé obìnrin kan tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Valdira, ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí ní ọdún mẹ́tàlá [13] sẹ́yìn. Bí wọ́n ṣe kò sírìn nìyẹn, lójú ọ̀nà eléruku tí wọ́n sì tún la àwọn odò tó ṣòro rìn kọjá. Wọ́n rí Valdira, inú òun náà sì dùn láti tún bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Torí pé ibi tọ́mọbìnrin  náà ń gbé jìnnà sílùú, wọ́n jọ ṣètò pé àwọn á máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ́nà àkànṣe. Wọn pinnu láti máa ṣe é lórí fóònù. Àmọ́, inú oko kan báyìí ni ibi kan ṣoṣo tí Valdira ti lè gba ìpè, ibẹ̀ sì jìnnà sílé. Yàtọ̀ síyẹn, lẹ́yìn aago mẹ́sàn-án alẹ́ ló tó lè ráyè kẹ́kọ̀ọ́. Ẹ ò rí pọ́rọ̀ náà nira díẹ̀, kí ọ̀dọ́bìnrin kan dá wà nínú igbó, tòun ti fóònù létí kó lóun ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì! Iná àbẹ́là ló tún máa tàn kó lè ríwèé tó ń kà.

Tó bá tún dọjọ́ Sunday, Valdira á tún gba inú igbó lọ kó lè lọ fi fóònú gbádùn ìpàdé ọjọ́ Sunday. Kódà, á tún mú Bíbélì rẹ̀, Ilé Ìṣọ́ rẹ̀ àti ìwé orin rẹ̀ dání. Tójò bá sì ń rọ̀, á mú ọ̀ǹbùrẹ́là dání.

Lóṣù March, Valdira rìnrìn àjò tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún [100] kìlómítà láti lọ sípàdé àkànṣe kan tí wọ́n ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nílùú tó lọ náà. Ìpàdé yẹn ni wọ́n ti mú àkọ̀tun Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde lédè Potogí. Inú ẹ̀ dùn gan-an pé òun náà ní ẹ̀dà Bíbélì tuntun yẹn. Táwọn èèyàn bá ń yìn ín torí bó ṣe ń sapá láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣe ni Valdira máa ń sọ pé, “Aà, ohun tó ń dunni ní pọ̀ lọ́là ẹni!”

“Mo Mọ̀ Pé Màá Ṣalábàápàdé Yín Lọ́jọ́ Kan”

Ẹ̀yà Yukpa wà lára àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Amẹ́ríkà tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Kòlóńbíà. Lọ́jọ́ kan, arákùnrin Frank tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ń múra àtilọ wàásù níbi táwọn ẹ̀yà náà ń gbé. Àmọ́, wọ́n ta arákùnrin náà lólobó pé baálẹ̀ abúlé náà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ John Jairo, ti fojú àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tó lọ wàásù níbẹ̀ rí màbo. Wọ́n ní, ìgbà kan tiẹ̀ wà tí baálẹ̀ náà gbọ́ pé àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì abúlé náà ń gba ìdámẹ́wàá, bí baálẹ̀ ṣe gbé ìbọn nìyẹn tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í yìn ín sókè. Kíá ni àlùfáà náà feré gé e.

Kòlóńbíà: Frank, tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ń kọ́ àwọn èèyàn tó jẹ́ ẹ̀yà Yukpa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Kí larákùnrin Frank wá ṣe? Ẹ gbọ́hun tó sọ: “Nígbà tá a dé abúlé náà, ǹjẹ́ ẹ mẹni tá a kọ́kọ́ bá sọ̀rọ̀? Ọmọbìnrin baálẹ̀ ni! Lẹ́yìn tá a fi ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? hàn án,  ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló sọ pé, ‘Ìsìn tí mo fẹ́ ṣe gan-an nìyí!’ Ló bá sá lọ sínú ilé, ó sọ fún bàbá rẹ̀ pé a wà níta. Bàbá rẹ̀ ní ká wọlé. Ẹ̀rù bà wá, àmọ́ a wọlé lọ bá a. Ká tó lanu sọ̀rọ̀, baálẹ̀ náà wí pé: ‘Mo mọ̀ pẹ́yin lẹ̀ ń ṣèsìn tòótọ́. Lọ́dún mẹ́jọ sẹ́yìn, nígbà tí mo wà nílùú Becerril, mo ríwèé kan he nínú pàǹtírí, ìwé náà jọ èyí tẹ́ ẹ fún ọmọ mi yìí. Mo kà á, àtìgbà yẹn ni mo ti ń retí àtifojú kàn yín. Mo mọ̀ pé màá ṣalábàápàdé yín lọ́jọ́ kan. Mo fẹ́ kẹ́ ẹ máa kọ́ mi ní Bíbélì, kẹ́ ẹ kọ́ ìdílé mi àtàwọn èèyàn abúlé yìí lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ilé nilé yín.’

Omi lé ròrò lójú wa bó ṣe ń sọ̀rọ̀ yẹn. Gbogbo abúlé kóra jọ láti gbọ́ ìwàásù wa. Ǹjẹ́ ẹ mọ ẹni tó ṣe ògbufọ̀ ọ̀rọ̀ wa sí èdè àwọn èèyàn náà? Baálẹ̀ fúnra rẹ̀, ìyẹn John Jairo. Nígbà  tá a fẹ́ máa lọ, ó yá wa ní kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan pé kó bá wa gbé ẹrù wa. Mẹ́tàdínláàádọ́ta [47] ni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá à ń darí, àmọ́ tá a bá ka àwọn èèyàn náà lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, wọ́n jẹ́ ọgọ́fà [120], títí kan baálẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀.”

Ẹni Tó Ń Ṣenúnibíni Tẹ́lẹ̀ Di Ẹlẹ́rìí

Ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ José, Kátólíìkì ni tẹ́lẹ̀, orílẹ̀-èdè Ecuador ló sì ń gbé. Ẹ gbọ́hun tó sọ: “Tẹ́lẹ̀, mo kórìíra àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí ìgbẹ́. Odindi ọdún mẹ́wàá ni mo fi fínná mọ́ wọn. Mo máa ń bẹ àwọn jàǹdùkú lọ́wẹ̀ sí wọn, mo máa ń ṣàìdáa sí wọn, mo sì máa ń fẹ̀sùn olè kàn wọ́n. Tí wọ́n bá dé àgọ́ ọlọ́pàá, mo máa ń sọ fáwọn ọlọ́pàá pé èmi alára ni màá fi àgádágodo tìlẹ̀kùn ibi tí wọ́n kó wọn sí.  Ìgbà kan tiẹ̀ wà tá a ba mọ́tò Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan jẹ́. A tún ju mọtosááikù ọkàn lára wọn sínú ọ̀gbun tó jìn gan-an.

Àmọ́, lọ́dún 2010, mo ní àrùn ibà téèyàn máa ń kó lára ẹlẹ́dẹ̀ tí wọ́n ń pè ní swine flu. Dókítà tó ń tọ́jú mi ní kí n kúrò nílé ti mò ń gbé níbi òkè ńlá Andes, kí n gba ibi tí kò sí otútù lọ nítòsí etíkun, kára mi lè yá. Bí mo ṣe gba oko ìbátan mi lọ nìyẹn, oko náà kò jìnnà sétíkun, àmọ́ èmi nìkan ni mo ríra mi lóko náà. Bọ́rọ̀ ṣe wá rí yìí, ó wù mi gan-an kí n rẹ́ni tí màá máa bá sọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ ẹ màwọn tó wá síbẹ̀? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà! Tí mo jàjà rẹ́ni tí màá bá sọ̀rọ̀, ṣe la tẹ́ pẹpẹ ọ̀rọ̀, bí wọ́n ṣe ń ṣàlàyé Bíbélì sì ya mi lẹ́nu gan-an. Ká má fọ̀rọ̀ gùn, mo gbà pé kí wọ́n máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo gbádùn ẹ̀kọ́ náà, lẹ́yìn oṣù mẹ́fà mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé. Báwọn ará ṣe ń kí mi tí wọ́n ń yọ̀ mọ́ mi wú mi lórí gan-an débi pé mo bi ara mi pé, ‘Ǹjẹ́ kì í ṣe àwọn aráabí ló ń ṣẹ̀sìn tòótọ́ báyìí?’ Mo tẹ̀ síwájú nínú ẹ̀kọ́ mi, ìgbà tó doṣù April ọdún 2014, mo ṣèrìbọmi.

Ó dùn mí gan-an pé mo ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, mo dúpẹ́ pé Jèhófà fún mi láyè láti ṣe àwọn àtúnṣe kan. Ní àpéjọ àyíká kan tá a ṣe ní October 4, 2014, wọ́n fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò, wọ́n bi mí pé: ‘Tó o bá láǹfààní àtitọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn tó o ṣenúnibíni sí nígbà yẹn, ṣé wàá lè ṣe bẹ́ẹ̀?’ Mo fèsì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pé màá ṣe bẹ́ẹ̀, pàápàá fún arákùnrin kan tó ń jẹ́ Edmundo, ká sọ pé mo lè rí i ni. Àṣé alábòójútó àyíká ti ní kí arákùnrin náà dúró sẹ́yìn pèpéle, mi ò sì mọ̀. Arákùnrin Edmundo bá yọjú síta, la bá dì mọ́ra lórí pèpéle, omijé sì ń dà lójú wa pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀. Orí àwùjọ wú, làwọn náà bá ń domi lójú.”

“Jèhófà Jọ̀ọ́, Jẹ́ Káwọn Ẹlẹ́rìí Rẹ Wá Mi Kàn”

Paraguay: Obìnrin yìí ń béèrè bóyá Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn arábìnrin náà

Lọ́jọ́ kan nílùú Asunción, lórílẹ̀-èdè Paraguay, àwọn arábìnrin kan jáde òde ẹ̀rí. Nígbà tó fi máa dọ̀sán, wọ́n parí ibi tí wọ́n yàn fún wọn láti ṣe. Oòrùn tó mú lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn  kúrò ní díẹ̀, síbẹ̀ wọ́n ronú pé á dáa káwọn ṣe ilé mélòó kan sí i. Ọ̀kan lára àwọn ará náà sọ pé, “A ò mọ̀ bóyá ẹnì kan ń gbàdúrà.” Àbí ẹ ò rí nǹkan, báwọn arábìnrin wa ṣe dé ilé kan tó wà ní kọ̀rọ̀, wọ́n rí obìnrin kan tó kí wọn tẹ̀ríntẹ̀rín, tó sì béèrè bóyá Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n. Obìnrin yẹn sọ pé orílẹ̀-èdè Bolivia lòun wà tẹ́lẹ̀ àti pé iṣẹ́ ló gbé òun wá sórílẹ̀-èdè Paraguay ní oṣù kan sẹ́yìn. Ó sọ pé òun ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ará wa kóun tó wá síbí. Ó ti béèrè lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò rẹ̀ pé kí wọ́n júwe ibi táwọn Ẹlẹ́rìí wà àmọ́ kò sẹ́ni tó mọbẹ̀, ló bá gbàdúrà pé, “Jèhófà jọ̀ọ́, jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí rẹ wá mi kàn.” Ọjọ́ yẹn gan-an làwọn arábìnrin yẹn wá síbẹ̀, wọ́n yáa ṣètò láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ.