• ILẸ̀ 29

  • IYE ÈÈYÀN 40,642,855

  • IYE AKÉDE 98,353

  • IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 66,022

Ó Lo Ìgboyà Láti Jẹ́rìí

Lọ́jọ́ kan lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà, olùkọ́ kan ń kọ́ àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa fọgbọ́n yan ọ̀rẹ́, ọ̀kan lára àwọn ọmọ kíláàsì náà sì ni ọ̀dọ́bìnrin ọlọ́dún méjìlá kan tó ń jẹ́ Emily. Ni Emily bá tọ olùkọ́ rẹ̀ lọ, ó sì fi fídíò eré ojú pátákó tá a pè ní Ta Ni Ọ̀rẹ́ Tòótọ́? hàn án. Fídíò náà dùn mọ́ tíṣà náà débi pé ó fi fídíò náà han àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀, tí gbogbo wọn sì pa rọ́rọ́ nígbà tí wọ́n  ń wo fídíò náà. Lẹ́yìn náà, wọ́n fi odindi wákàtí kan sọ̀rọ̀ lórí fídíò náà. Kò mọ síbẹ̀, tíṣà yìí tún lọ sáwọn kíláàsì míì ó sì fi fídíò náà hàn wọ́n. Nígbà tó yá, Emily fi ìkànnì jw.org han tíṣà náà àtàwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀. Emily wá sọ pé, “Jèhófà fún mi nígboyà láti fi ìkànnì wa han àìmọye àwọn ọmọléèwé mi. Inú mi dùn pé Jèhófà bù kún mi.”

Ìpàtẹ Ọjà Ní Àdádó Kan

Lásìkò kan táwọn èèyàn pàtẹ ọjà nílùú Suai, lórílẹ̀-èdè Timor-Leste, àwọn akéde márùn-ún kan rin ìrìn àjò wákàtí mẹ́sàn-án lọ síbẹ̀ kí wọ́n lè pàtẹ àwọn ìwé wa, bẹ́ẹ̀ sì rèé gbágungbàgun lojú ọ̀nà náà, wọ́n á sì tún pọ́nkè. Ẹnu ya àwọn tó wá síbi ìpàtẹ ọjà náà nígbà tí wọ́n rí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní èdè méjìlá [12] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n ń sọ lágbègbè yẹn. Ìwọ̀nba kéréje ni àwọn ìwé táwọn òǹṣèwé tíì ṣe jáde láwọn èdè yẹn. Àwọn èdè míì ò tiẹ̀ ní ìwé kankan ní èdè wọn. Nígbà tí obìnrin kan rí àkòrí ọ̀kan lára àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà, ṣe ló pariwo: “Èdè ìlú mi nìyẹn!” Ìgbà àkọ́kọ́ tó máa rí ìwé tí wọ́n fi èdè Bunak tó jẹ́ èdè ìbílẹ̀ rẹ̀ kọ nìyẹn. Láàárín ọjọ́ mẹ́rin péré, àwọn akéde yẹn fi ìwé tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin, ọgọ́rùn-ún márún àti mọ́kànléláàdọ́rin [4,571] sóde. Àìmọye èèyàn ló sì bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n wá kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ nílé. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ ló jẹ́ pé ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn. Ọ̀pọ̀ wákàtí ni àwọn  ọmọdé fi jókòó tí wọ́n ń wo fídíò Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà ní èdè Tetun Dili. Àwọn ọmọ míì tíẹ̀ há àwọn ọ̀rọ̀ orin yẹn sórí tí wọ́n sì ń fi ìdùnnú kọ ọ́.

Timor-Leste: Àwọn ọmọdé gbádùn láti máa wo àwọn fídíò Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà

“Ohun Táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Nílò Gan-an Nìyi”

Brian àti Roxanne tó jẹ́ míṣọ́nnárì béèrè lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ gíga kan ní erékùṣù Palau kí wọ́n lé pàtẹ àwọn ìwé wa ní ọgbà ilé ẹ̀kọ́ náà. Wọ́n lọ bá ọ̀gá pátápátá ilé ẹ̀kọ́ náà, wọ́n sì fi fídíò kan tó wà lórí ìkànnì jw.org hàn án.  Fídíò yìí sọ nìpa bí a ṣe máa ń wàásù láwọn ibi tí èrò máa ń pọ̀ sí. Wọ́n tún fún un ní díẹ̀ lára àwọn ìwé tí wọ́n fẹ́ pàtẹ rẹ̀ kó lè yẹ̀ ẹ́ wò. Ọ̀gá pátápátá yìí sọ pé kí wọn lọ bá ọ̀gá tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ilé-ìwé. Nígbà tí wọ́n lọ bá ọ̀gá yẹn, ó tún ní kí wọ́n lọ bá ọ̀gá tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́.

Arákùnrin Brian ròyìn pé: “Ọ̀gá tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí fara balẹ̀ gbọ́ wa, àmọ ṣe ló ní pé ká pa dà lọ sí ọ́fíìsí ọ̀gá pátápátá tá a kọ́kọ́ pàdé. Ìgbà tá a débẹ̀, wọ́n ní ká lọ kọ lẹ́tà wá pé a fẹ́ kí wọ́n fún wa láyè láti pàtẹ́ ìwé wa. Gbogbo bí wọ́n ṣe ń dà wá ríborìbo yìí jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà sú wa. Síbẹ̀, a kọ lẹ́tà náà, a sì fún wọn.”

Palau: Roxanne àti Brian bá ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ jíròrò nígbà tí wọ́n pàtẹ àwọn ìwé wa ní ọgbà ilé ẹ̀kọ́ gíga kan

 Brian àti Roxanne pa dà sọ́dọ̀ ọ̀gá tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kí wọ́n lè mọ èsì lẹ́tà wọn. Gbogbo èrò ọkàn wọn ni pé ṣe ni ọ̀gá náà máa sọ pé kò sáyè. Arákùnrin Brian sọ pé: “Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún wa nígbà tí ọ̀gá náà sọ fún wa pé òun ti ka gbogbo ìwé tá a kó wá. Ó ní ìwé dáadáa ni wọ́n, àti pé irú ìwé táwọn akẹ́kọ̀ọ́ nílò gan-an nìyí.” Àfi bí àlá, bí wọ́n ṣe fún wa láyè nìyẹn

Arákùnrin Brian ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Ọ̀gá tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ilé-ìwé sọ fún wa pé àwọn ti ṣètò pé káwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń gbé nínú ọgbà lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tó bá wù wọ́n ní ọjọ́ Sunday. Ó ní, ‘Tó bá jẹ́ ṣọ́ọ̀ṣí yín ni wọ́n fẹ́ lọ, àá gbé wọn lọ.’ Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún èmi àti Roxanne, kàkà kí wọ́n sọ pé àwọn ò fún wa láyè, ṣe ni wọ́n tún sọ pé àwọn á gbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba.”

Ní ọjọ́ àkọ́kọ́ tí Brian àti Roxanne pàtẹ àwọn ìwé wa nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ náà, ìwé ńlá márùnlélọ́gọ́ta [65], ìwé ìròyìn mẹ́jọ àti ìwé pẹlẹbẹ mọ́kànlá [11] ni wọ́n fi sóde. Àìmọye àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ sì ni wọn fetí sílẹ̀. Ọ̀gá tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ilé-ìwé àti ọ̀gá tó ń bójú tó ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n tún wá lọ́jọ́ míì.

Àwọn Tó Wá Rajà Wo Àwọn Fídíò Wa

Arákùnrin Lipson jẹ́ ọ̀kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní orílẹ̀-èdè Solomon Islands. Lọ́jọ́ kan tó ń darí bọ̀ láti òde-ẹ̀rí, ó ń gbọ́ tí wọ́n ń kọ orin ìjọba Ọlọ́run nínú ilé ìtajà kan. Ló bá yà síbẹ̀ kó lè wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún un nígbà tó rí èrò rẹpẹtẹ lọ́mọdé lágbà tí wọ́n ń wo tẹlifíṣọ̀n kan tó ń gbé orin 55 jáde, ìyẹn “Ìyè Àìnípẹ̀kun Nígbẹ̀yìngbẹ́yín!” èyí táwọn ọmọdé kọ nínú Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà. Nígbà tí orin yẹn parí, ẹni tó ni ilé ìtajà náà sọ pé: “Fídíò míì wà tí mo fẹ́ fi hàn yín.” Bó tún ṣe gbé fídíò Olè Ò Dáa sí i nìyẹn. Lẹ́yìn tí ìyẹn parí, ó wá rọ gbogbo wọn pé kí wọ́n má jí nǹkan nínú ilé ìtajà òun.

 Torí àwọn míì tún dé bá wọn lẹ́nu rẹ̀, ẹni tó ni ilé ìtajà náà sọ fún wọn pé: “Mo fẹ́ kí ẹ gbọ́ orin tí mo fẹ́ràn jù lọ.” Ló bá tún fi orin 55 yẹn sí i. Lẹ́yìn ìyẹn, ó fi fídíò Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? àti Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? lédè Pidgin ti Solomon Islands, hàn wọ́n.

Solomon Islands: Ẹni tó ni ilé ìtajà ń fi àwọn fídíò tó wà lórí Ìkànnì jw.org han àwọn tó wá rajà

Ìwọ̀nba èèyàn kéréje ní Solomon Islands ló láǹfààní láti lo Íńtánẹ́ẹ̀tì torí pé owó gọbọi ló máa ń náni, ó sì lójú àwọn tó ń rí Íńtánẹ́ẹ̀tì ọ̀hún lò. Láìka àwọn ìṣòro yìí sí, ẹni tó ni ilé ìtajà yìí ń fi àwọn fídíò wa tan òtítọ́ Bíbélì kálẹ̀. Kẹ́ẹ sì máa wòó, ọ̀gbẹ́ni yìí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà o.

Ó Rí Orúkọ Ọlọ́run Nínú Ìwé Náà

Ní gbogbo ọjọ́ Monday, tọkọtaya kan máa ń pàtẹ àwọn ìwé wa ní ìlú Nouméa tí í ṣe olú-ìlú orílẹ̀-èdè New Caledonia. Lọ́jọ́ kan, obìnrin kan fìtìjú lọ sídìí àtẹ náà, kò sọ ‘kó’, àmọ́ ó mú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?  ó sì tẹsẹ̀ mọ́rìn. Ní nǹkan bí ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lẹ́yin ìyẹn, ó pa dà wá pẹ̀lú ìwé náà lọ́wọ́ rẹ̀. Ó kọjú sí tọkọtaya náà, ó sì sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ ti ká ìwé yìí débí?” Ló bá ṣí ìwé náà, ó sì nàka sí orúkọ Jèhófà, ó ní: “Orúkọ Ọlọ́run nìyẹn! Láti bí ọ̀sẹ̀ mélòó kan ni mo ti ń ṣèwádìí níbi ìkówèésí kí n lè mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Bí mo ṣe wọnú ọkọ̀ mi pé kí ń wo ohun tó wà nínú ìwé yín tí mo mú, ohun tí mo kọ́kọ́ rí ni orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà. Ìyẹn ni mo ṣe ní kí ń pa dà wá dúpẹ́ lọ́wọ́ yín.” Àwọn tọkọtaya yìí bá obìnrin náà jíròrò, gbogbo wọn sì gbádùn ìjíròrò náà. Wọ́n fi àfikún àlàyé tó ní àkòrí náà “Ìtumọ̀ Orúkọ Ọlọ́run àti Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lò Ó”, èyí tó wà nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni hàn an. Obìnrin náà sọ pé òun fẹ́ parí ìwádìí tí òun ń ṣe níbi ìkówèésí ná, àmọ òun ti wá mọ̀ pé ní gbogbo ọjọ́ Monday ni àtẹ yìí máa ń wà níbí