Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016

Ká nípa ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbé ṣe lọ́dún 2015 àti ìtàn nípa iṣẹ́ wa ní orílẹ̀-èdè Indonéṣíà.

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Ọdún 2016

Ọ̀rọ̀ ìṣítí àti ọ̀rọ̀ ìwúrí wà nínú Hébérù 13:1.

Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Ọ̀rọ̀ tó ń fúnni níṣìírí yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà ni àwọn àrànṣe bí Ìkànnì jw.org, Ètò Orí Tẹlifíṣọ̀n JW àtàwọn ohun tá a fi ń pàtẹ àwọn ìwé wa níbi tí èrò pọ̀ sí.

“Àwọn Ètò Orí Tẹlifíṣọ̀n JW Ti Lọ Wà Jù!”

Àwọn ìmúrasílẹ̀ wo la ṣe ká lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbóhùn sáfẹ́fẹ́ lórí ètò Tẹlifíṣọ̀n JW tá à ń wò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì?

Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Lọ́nà Tó Túbọ̀ Yára

A ti ṣe àwọn ìyípadà kan ká lè kọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn gbọ̀ngàn tuntun tá a nílò.

Báwo Ni Iṣẹ́ Ṣe Ń Lọ Sí Ní Warwick?

Wo àlàyé díẹ̀ nípa ibi tí iṣẹ́ ìkọ́lé dé ní oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Tí A Kì Í Bá Nílé

Kí ló mú kí Terry gbà pé ohun tí òun gbọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ìdáhùn sí àdúrà òun?

Ìmọ́lẹ̀ Ń Mọ́lẹ̀ Sí I

Ní apá yìí, wà á rí bí Jèhófà ṣe ń tànmọ́lẹ̀ sí ipa ọ̀nà àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́.

A Ya Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Sí Mímọ́

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2015, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní orílẹ̀-èdè Madagásíkà àti Indonéṣíà rí ìbùkún àrà ọ̀tọ̀ kan gbà.

A Mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Jáde Láwọn Èdè Míì

Àwọn èdè tá a mú jáde lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2015 jẹ́ mẹ́rìndínlógún.

Ìròyìn Nípa Àwọn Ẹjọ́

Ọ̀pọ̀ ibi kárí ayé láwọn èèyàn ti ń ṣe ẹ̀tanú sí wa, èyí tó mú ká máa gbọ́rọ̀ relé ẹjọ́.

Ìròyìn—Nípa Àwọn Ará Wa

Ohun tó wà nínú àpótí tí ọmọdékùnrin Ken ṣe pamọ́ wúlò gan-an nígbà tá a ń kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Áfíríkà

Àwọn ọ̀nà tó mọ́gbọ́n dání wo làwọn Ẹlẹ́rìí ń lò láti wàásù ìhìn rere?

Àwọn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà

Kí nìdí tí ọmọbìnrin kan fi ń lo iná àbẹ́là láti kẹ́kọ̀ọ́ nínú igbó? Kí nìdí tí baálẹ̀ kan tí kò gba gbẹ̀rẹ́ fi ń retí àtirí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Kí ló fà á tí ẹnì kan tó ti máa ń ṣenúnibíni sí wa fi bú sẹ́kún?

Éṣíà àti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé

Kò sóhun náà tó lè di àwọn ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run, yálà ààbọ̀ ara ni o tàbí wọ́n fàṣẹ ọba mú wọn.

Yúróòpù

Ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹ̀yà Roma, ẹlẹ́wọ̀n kan àti obìnrin kan tó fẹ́ pa ara rẹ̀ láyọ̀ gan-an nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

Àgbègbè Oceania

À ń lo àwọn tábìlì àti kẹ̀kẹ́ tá a fi ń pàtẹ àwọn ìwé wa, Ìkànnì jw.org àtàwọn fídíò ètò Ọlọ́run láti kọ́ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́!

Àlàyé Ṣókí Nípa Indonéṣíà

Wo àkópọ̀ ṣókí nípa ilẹ̀, àwọn èèyàn àti àṣà tó wà ni orílẹ̀-èdè tó ní àwọn erékùṣù tó fẹ̀ jù láyé.

Òwò Èròjà Amóúnjẹ-ta-sánsán

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìndínlógún, òwò èròjà amóúnjẹ-ta-sánsán ló gbayé kan.

Ibí Yìí Gan-an ni Màá ti Bẹ̀rẹ̀

Àwọn akínkanjú aṣáájú-ọ̀nà lati Ọsirélíà ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwáásù láìka àwọn ìṣòro tí wọ́n kojú.

Bá A Ṣe Ń Wàásù Láyé Ọjọ́un

Àsọyé Bíbélì tá a ṣe lórí rédíò àti ìwàásù láwọn etíkun Indonéṣíà bí àwọn tó kórìíra òtítọ́ nínú.

Ẹgbẹ́ Bibelkring

Ohun tí wọ́n kà nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló mú wọn dá ẹgbẹ́ yìí sílẹ̀, àmọ́ ìgbà tó yá ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi èrò èèyàn darí ẹgbẹ́ náà.

Ó Mọyì Ọrọ̀ Tẹ̀mí

Àwọn ọ̀bàyéjẹ́ já wọlé Thio Seng Bie, wọ́n sì kẹ́rù rẹ̀ lọ, síbẹ̀ ṣe ló ń wò wọ́n. Àmọ́ ohun tí wọ́n ò kó mẹ́rù wúlò ju ohun tí wọ́n kó lọ.

Ìwàásù Méso Jáde ní West Java

Bí wọ́n ṣe ń fòfin de àwọn ìwé wa lọ́kan-ò-jọ̀kan, bẹ́ẹ̀ làwa Ẹlẹ́rìí ń dá ọgbọ́n oríṣiríṣi kí iṣẹ́ ìwáásù náà lè máa tẹ̀ síwájú.

Lábẹ́ Àjàgà Ìjọba Ilẹ̀ Japan

Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn Ẹlẹ́rìí kan wá ọ̀nà àbáyọ láti forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ Japan láìsì dá sọ̀rọ̀ òṣèlú tàbí ogun.

Akínkanjú Aṣáájú-ọ̀nà

Jálẹ̀ 60 ọdún tí André Elias fi ṣiṣẹ́ sìn, ó jólóòótọ́ bí wọ́n tiẹ̀ halẹ̀ mọ́ ọn tí wọ́n sì ń fọ̀rọ̀ lọ ọ́ nífun.

Àwọn Míṣọ́nnárì Láti Gílíádì Dé

Àwọn míṣọ́nnárì láti Gílíádì tó kọ́kọ́ dé mú kí iṣẹ́ ìwàásù gbòòrò kíákíá.

Iṣẹ́ Náà Gbòòrò dé Ìlà Oòrùn

Ṣé àwọn olórí ìsìn á ṣàṣeyọrí lọ́tẹ̀ yìí?

Àwọn Míṣọ́nnárì Míì Tún Dé

Ipò nǹkan yí pa dà bìrí láàárín ọdún 1973 sí 1978, àtiwàásù wá dogun.

Èèyàn Bíi Sárà

Tinútinú ni Titi Koetin fi ara rẹ̀ sábẹ́ àṣẹ ọkọ rẹ̀, ó sì rí èrè jìgbìnnì níbẹ̀.

Àpéjọ Mánigbàgbé Kan

A ṣe Àpéjọ “Ìhìn Rere Àìnípẹ̀kun” láṣeyọrí láìka àwọn ìṣòro tó yọjú.

Mo La Rògbòdìyàn Àwọn Kọ́múní ìsì Já

Wọ́n ti gbẹ́ sàréè tí wọ́n máa sin Ronald Jacka sí

Àádọ́ta Ọdún Lẹ́nu Iṣẹ́ Aṣáájú-Ọ̀nà Àkànṣe

Lọ́dún 1964, àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì kan halẹ̀ mọ́ wa pé: ‘Máà rí sí i pé kò sí Ajẹ́rìí Jèhófà kankan nílùú Manokwari ńbí!’ Ṣe ó ṣàṣeyọrí?

Ọ̀gá Àwọn Jàǹdùkú Di Ọmọlúwàbí

Ọ̀gá Àwọn Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ bèèrè pé: “Sòótọ́ fún mi, kí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe ní Indonéṣíà gan-an?”

Wọ́n Pinnu Láti Tẹ̀ Síwájú

Kí ló mú káwọn èèyàn tó ń róhun tó ń ṣẹlẹ̀ sọ pé, “Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí ṣáá, ńṣe lẹ dà bí ìṣó”?

Wọ́n Ò fi Ọ̀rọ̀ Ìpàdé Ṣeré

Nígbà tí wọ́n mú ìfòfinde kúrò lórí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọ̀gá àgbà kan sọ ẹ̀dà ọ̀rọ̀ pé: “Ìwé tá a fi forúkọ yín sílẹ̀ yìí kì í ṣe ìwé tó fún yín ní òmìnira láti máa jọ́sìn.”

Ìfẹ́ Tòótọ́ Lákòókò Àjálù

Ìmìtìtì ilẹ̀ kan tó lágbára sọ ìlú Gunungsitoli di ilẹ̀ẹ́lẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò ìrànwọ́ fáwọn ará wọn.

A Kò Ní Sẹ́ Ìgbàgbọ́ Wa

Daniel Lokollo rántí inúnibíni tí wọ́n ṣe sí i lẹ́wọ̀n.

A Tẹ̀ Lé Ìtọ́ni—A Sì Yè!

Ìjà àárín àwọn Mùsùlùmí àtàwọn Kristẹni lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà mú kí nǹkan nira fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ńbẹ̀.

Iṣẹ́ Wa Ń Tẹ̀ Síwájú

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n mú ìfòfindè iṣẹ́ wa kúrò ni ànfààní ńlá mẹ́ta yọjú fún àwọn ara.

Wọ́n Ń Fayọ̀ Polongo Orúkọ Jèhófà

Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí ṣe kápá àṣà tó ti mọ́ra tí kì í jẹ́ kí wọ́n lè fìgboyà wàásù?

Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Bọ́ sí Ojútáyé

Àwọn ara tó ń wá ibi táwọn èèyàn púpọ̀ á ti gbọ́ ìwàásù ti wá rí ibi tí àìní pọ̀ sí gan-an.

“Jèhófà Bù Kún Wa Ju Bá A Ṣe Rò Lọ!”

Ìjọ tó wà lábúlé Tugala, lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà rí ìbùkún àgbàyanu gbà.

A Dúpẹ́ Pé Ojú Túnra Rí!

Àwọn arábìnrin odi méjì tó jẹ́ ọmọ ìyá ò mọra torí pé àti kékeré ni wọ́n ti wọ́n gbé ọ̀kan nínú wọn ṣọmọ, òtítọ́ Bíbélì ló pa dà so wọ́n pọ̀.

Ní Ọgọ́rùn-ún Ọdún Sẹ́yìn—1916

Mánigbàgbé ni ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé níparí ọdún 1916 máa jẹ́ fún àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Gbogbo Àròpọ̀ ti Ọdún 2015

Àwọn nǹkan wo la ṣe, èló lò sì ná wa láti wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn?

Ìrántí Ikú Kristi—Friday, April 3, 2015

Ìkésíni tá a pín fún ọ̀sẹ̀ mẹ́rin mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi.