Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Iwe Odoodun Awa Elerii Jehofa​—2015

 À Ń WÀÁSÙ A SÌ Ń KỌ́NI KÁRÍ AYÉ

Yuroopu

Yuroopu
  • ILẸ̀ 47

  • IYE ÈÈYÀN 741,311,996

  • IYE AKÉDE 1,611,036

  • IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 847,343

Àwọn Ọmọ Ilé Ìwé Lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba

Orílẹ̀-Èdè Finland: Àwọn ọmọ kíláàsì kẹrin wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba

Nígbà tí ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Ines tó wà ní kíláàsì kẹrin lórílẹ̀-èdè Finland gbọ́ pé wọ́n máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ nípa ẹ̀sìn, ó pinnu láti pe àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn ọmọ kíláàsì náà àti olùkọ́ wọn sì gbà láti lọ.

Ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, méjìdínlógójì [38] lára àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́  náà gun kẹ̀kẹ́, wọ́n sì rin ìrìn àjò nǹkan bíi kìlómítà márùn-ún wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Olùkọ́ méjì àti olùkọ́ àgbà iléèwé náà tẹ̀ lé wọn wá. Arákùnrin méjì àti arábìnrin mẹ́ta lọ pàdé wọn ní Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Nígbà tí wọ́n ń jẹ ìpápánu, àwọn ọmọ iléèwé náà béèrè ìbéèrè nípa gbọ̀ngàn náà àti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n ní: “Kí lẹ máa ń ṣe ní ìpàdé yín?” Wọ́n tọ́ka sí yàrá ìkàwé, wọ́n sì béèrè pé: “Yàrá wo ló wà níbẹ̀ yẹn?” Wọ́n rí Mátíù 6:10 tó jẹ́ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdọọdún lára ògiri, wọ́n sì béèrè pé: “Èwo ni ‘ẹ́ẹ́fà àti ẹẹ́wàá tí wọ́n fi àmì pípín sí láàárín yẹn?’”

Torí pé ilé ìwé náà ń kópa nínú ètò kan tí wọ́n fẹ́ fi ki ọwọ́ bíbúmọ́ni nílé ìwé bọlẹ̀, àwọn ará fi fídíò náà, Beat a Bully Without Using Your Fists hàn wọ́n lórí ìkànnì jw.org. Wọ́n tún fi àwọn nǹkan míì hàn wọ́n lórí Ìkànnì wa, wọ́n sì gbọ́ orin Ìjọba Ọlọ́run kan. Wọ́n lò tó wákàtí kan kí wọ́n tó lọ.

Olùkọ́ àgbà, àwọn olùkọ́ àtàwọn ọmọ ilé ìwé náà gbádùn ìbẹ̀wò yìí gan-an. Olùkọ́ àgbà náà fẹ́ràn àwọn nǹkan tó rí lórí ìkànnì wa, ó sì gbà pé ó máa wúlò láti máa fi kọ́ àwọn ọmọ ilé ìwé lẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀sìn. Inú rẹ̀ sì dùn láti gbọ́ pé àwọn ará gba àwọn kíláàsì yòókù láyè láti ṣèbẹ̀wò sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Látàrí ìyẹn, olùkọ́ kíláàsì míì kàn sí àwọn ará wa lọ́jọ́ kejì láti bi wọ́n bóyá kíláàsì tiẹ̀ náà lè ṣèbẹ̀wò sí Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Ó Rí Ìṣúra Lórí Àkìtàn

Cristina tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ròmáníà kò lọ iléèwé, kò sì mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Tálákà ni, ike àti agolo ló sì máa ń ṣà lórí àkìtàn láti fi wá jíjẹ mímu. Lọ́jọ́ kan tó ń ṣa ilẹ̀ lórí àkìtàn, ó tajú kán rí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ní àwòrán àwọn èèyàn tó rẹwà tí wọ́n sì láyọ̀. Ó rò ó lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘Irú àwọn èèyàn yìí á sì wà níbì kan láyé yìí o.’ Cristina ṣáà fẹ́ mọ nǹkan tó wà nínú àwọn ìwé náà. Torí náà, ó ní kí ẹnì  kan kà á sí òun létí. Nígbà tó gbọ́ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn ló wà nínú àwọn ìwé náà, ó dùn ún pé àwọn èèyàn kó ìwé tó dá lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà sí àkìtàn. Cristina kò yéé lọ sórí àkìtàn náà láti lọ kó àwọn ìwé pẹlẹbẹ, ìwé ìléwọ́ àtàwọn ìwé ìròyìn wa. Àwọn kan lára ìwé náà ṣì wà lódindi, àwọn míì sì ti fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Cristina kọ́ bó ṣe lè máa kàwé kó lè máa ka àwọn ohun tó wà nínú àwọn ìwé náà.

 Nígbà tó yá, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn sí Cristina, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Inú rẹ̀ dùn sí bí Jèhófà ṣe jẹ́ kó lè sún mọ́ òun nípasẹ̀ àwọn ìwé tí àwọn èèyàn kò mọyì rẹ̀. Ó ti ń wá sípàdé báyìí, ó sì fẹ́ràn ẹ̀kọ́ tó ń kọ́. Ọ̀kan lára ohun tó ń fún un láyọ̀ jù lọ ni pé ó ti wá ń rí àwọn ìwé ìròyìn, ìwé ńlá àtàwọn ìwé pẹlẹbẹ tuntun gbà báyìí. Kì í wá wọn lọ sórí àkìtàn mọ́. Dájúdájú, Cristina ti rí ìṣúra lórí àkìtàn!

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Inú “Igbó”

Orílẹ̀-Èdè Jámánì: Arábìnrin Margret ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú igbó

Ó jẹ́ àṣà Arábìnrin Margret tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Jámánì láti máa nasẹ̀ lọ sínú igbó kan tí wọ́n ti ń gbafẹ́ láràárọ̀ tòun ti ajá rẹ̀. Ó sọ pé: “Mo sábà máa ń bá àwọn tí mo bá pàdé lọ́nà sọ̀rọ̀. Tí wọn ò bá kánjú, màá mú ọ̀rọ̀ náà wọnú Bíbélì.”

Lọ́jọ́ kan, arábìnrin yìí bá màmá kan tọ́jọ́ orí rẹ̀ ti lé ní àádọ́rin [70] ọdún pàdé, ó mú ajá tiẹ̀ náà nasẹ̀ wá síbẹ̀. Arábìnrin Margret ló kọ́kọ́ bá màmá náà sọ̀rọ̀. Màmá yìí gbádùn ìjíròrò náà, ó sì sọ fún Arábìnrin Margret pé òun máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, òun sì máa ń ka Bíbélì lójoojúmọ́. Látìgbà yẹn wá, ojoojúmọ́ ni wọ́n ń pàdé tí wọ́n sì máa ń sọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lọ́jọ́ kan, màmá náà bi Arábìnrin Margret pé: “Kí ló mú kó o mọ Bíbélì dunjú tóyẹn?” Arábìnrin Margret sọ fún un pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun.

Arábìnrin Margret fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ màmá yìí lọ́pọ̀ ìgbà, àmọ́ kò gbà. Síbẹ̀ wọn ń bá ìjíròrò wọn lọ. Lẹ́yìn oṣù mélòó kan, Arábìnrin Margret tún fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́. Lọ́tẹ̀ yìí, màmá náà sọ fún arábìnrin wa pé ẹ̀rù ló ń ba òun láti kẹ́kọ̀ọ́ torí ọkùnrin tí wọ́n jọ ń gbé kórìíra àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

 Arábìnrin Margret mú Bíbélì àti ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? dání lọ́jọ́ tó tún lọ sínú igbó náà. Nígbà tí Arábìnrin Margret rí màmá náà, ó fìgboyà sọ pé: “Lọ́tẹ̀ yìí, mi ò ní sọ pé kẹ́ ẹ jẹ́ ká ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ‘igbó’ ni màá fẹ́ kẹ́ ẹ jẹ́ ká ṣe.” Omijé bọ́ lójú màmá náà, ó sì gbà pé ká jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ̀ẹ̀mẹfà lọ́sẹ̀ ló máa ń wá fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú “igbó” tá à ń ṣe níbi ìgbafẹ́ yẹn. Bí ojú ọjọ́ ò bá dáa, Arábìnrin Margret máa ń lo agbòjò àti iná tọ́ọ̀ṣì nígbà míì tó bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà.

Ó Mi Orí Sọ́tùn-ún Sósì, Ṣùgbọ́n Kò Yé Wọn

Arábìnrin Delphine ń kọ́ obìnrin kan tó ń jẹ́ Irina lẹ́kọ̀ọ́ lórílẹ̀-èdè Bọ̀géríà. Inú Irina dùn gan-an sí ẹ̀kọ́ tó ń kọ́, ó sì máa ń lọ sípàdé déédéé. Àmọ́ ọkọ Irina kò fẹ́ kó ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọkùnrin yìí àti ìdílé rẹ̀ wá kó lọ sí abúlé kékeré kan lórílẹ̀-èdè Sweden, bó ṣe di pé Irina kò rí Arábìnrin Delphine mọ́ nìyẹn. Àmọ́, Arábìnrin Alexandra àti Rebecca tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà bá Irina pàdé, Irina kò sì lè sọ èdè Swedish. Àwọn arábìnrin náà lo ìwé Good News for People of All Nations, wọ́n sì ní kí Irina kà á lédè Bulgarian. Lẹ́yìn náà, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé náà, wọ́n bi í bóyá ó máa fẹ́ gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lédè rẹ̀. Irina mi orí rẹ̀ sọ́tùn-ún sósì tokuntokun. Àwọn arábìnrin náà bá fi ibẹ̀ sílẹ̀ torí wọ́n rò pé Irina kò nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn.

Nígbà tó yá, Arábìnrin Alexandra wá rántí pé arábìnrin ọmọ ilẹ̀ Sweden kan tó ń jẹ́ Linda ń sìn lórílẹ̀-èdè Bọ̀géríà, ó sì máa wá sọ́dọ̀ wọn lọ́sẹ̀ mélòó kan sí i. Ó ronú pé ó máa dára tí Irina bá gbọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́ ní èdè àbínibí rẹ̀. Nígbà tí Arábìnrin Linda dé, òun àti Arábìnrin Alexandra jọ lọ sọ́dọ̀ Irina. Irina sọ fún Arábìnrin Linda pé òun máa ń gbàdúrà lálaalẹ́ pé kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́  kí òun lè máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì òun nìṣó. Ó sábà máa ń mú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? lédè Bọ̀géríà kiri. Ó fẹ́ kí ìwé náà wà lọ́wọ́ rẹ̀ kó lè fi han àwọn Ẹlẹ́rìí tó bá rí ní àdúgbò, àmọ́ kò rí Ẹlẹ́rìí kankan. Inú Irina dùn gan-an láti gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì púpọ̀ sí i lédè Bọ̀géríà!

Arábìnrin Linda béèrè ohun tó mú kí Arábìnrin Alexandra lérò pé Irina kò nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Arábìnrin Alexandra ṣàlàyé pé Irina mi orí rẹ̀ láti sọ pé òun kò nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀rọ̀ náà pa Arábìnrin Linda lẹ́rìn-ín, ó sì sọ fún wọn pé àwọn èèyàn ilẹ̀ Bọ̀géríà máa ń mi orí sókè sódò láti fi hàn pé àwọn kò fara mọ́ nǹkan, wọ́n á sì mi orí sọ́tùn-ún sósì, bí wọ́n bá fara mọ́ ọn. Irina ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ̀ nìṣó lédè Bulgarian títí tó fi gbọ́ èdè Swedish. Báwo ló ṣe ń ṣe é? Ó pa dà kàn sí Arábìnrin Delphine, wọ́n sì máa ń fi fídíò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì pe ara wọn láti ṣèkẹ́kọ̀ọ́.

Bàbá Tó Fi Àpẹẹrẹ Rere Lélẹ̀

Láti kékeré ni Jemima, ọmọbìnrin kan tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Sípéènì ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àmọ́ nígbà tó pé ọmọ ọdún méje, nǹkan ṣàdédé yí pa dà fún un. Ìyá rẹ̀ pinnu pé òun ò ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́, ó sì kọ bàbá rẹ̀ sílẹ̀. Nígbà tí Jemima pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá, òun náà ò lọ sípàdé mọ́, kò sì gbà kí bàbá rẹ̀ ràn án lọ́wọ́ kó lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run.

Bí Jemima ṣe ń dàgbà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ nínú onírúurú ẹgbẹ́ òṣèlú àtàwọn tó ń jà fún ẹ̀tọ́ aráàlú kó lè gbèjà àwọn mẹ̀kúnnù. Nígbà tó yá, iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ Jemima, Domingo tó jẹ́ bàbá rẹ̀ wá fi iṣẹ́ lọ̀ ọ́ pé kí wọ́n jọ máa kun ilé.

Lọ́jọ́ kan, nígbà táwọn méjèèjì ń ṣiṣẹ́, Domingo fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ Jemima, àmọ́ kò gbà. Ó wá sọ fún bàbá rẹ̀ pé òun máa jẹ́ kó mọ̀ tó bá ti wu òun láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Domingo máa ń tẹ́tí sí Bíbélì kíkà àtàwọn ìtẹ̀jáde tí wọ́n gba ohùn wọn sílẹ̀, àmọ́ ṣe ni ọmọ rẹ̀ máa ń ki gbohùngbohùn kékeré bọ etí láti máa fi gbọ́ orin aláriwo.

 Domingo fẹ́ ìyàwó míì nígbà tó yá, wọ́n sì pè é sí Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Tọkọtaya lóṣù November 2012. Orí Jemima wú nígbà tó gbọ́ pé bàbá òun máa lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Bíbélì fún oṣù méjì àti pé ó máa fi gbogbo dúkìá rẹ̀ sílẹ̀ táá sì lọ síbikíbi tí wọ́n bá ní kó lọ. Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí Jemima rí bí ẹ̀kọ́ òtítọ́ ṣe jinlẹ̀ tó lọ́kàn bàbá rẹ̀, ó sì fẹ́ mọ ohun tó fà á.

Jemima jáwọ́ nínú gbígbọ́ àwọn orin aláriwo, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́tí sí Bíbélì kíkà àtàwọn ìtẹ̀jáde tí bàbá rẹ̀ máa ń gbọ́. Ó tún bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè onírúurú ìbéèrè. Lọ́jọ́ kan tí Domingo ń kun ilé lórí àkàbà, Jemima sọ fún un pé: “Ṣé ẹ rántí ọjọ́ tí mo sọ pé màá sọ fún yín tí mo bá ṣe tán láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Àkókò ti tó báyìí.”

Ohun tó sọ yìí dùn mọ́ Domingo gan-an. Ní oṣù January, ọdún 2013, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀. Ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n pe Domingo sí bẹ̀rẹ̀ ní oṣù April, torí náà wọ́n ń fi fídíò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì pera wọn kí wọ́n lè máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nìṣó. Jemima wá lọ́jọ́ tí bàbá rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ yege, ó sì gbádùn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ náà. Jemima ṣèrìbọmi ní December 14, ọdún 2013.

Jemima sọ pé: “Jèhófà ti mú sùúrù fún mi gan-an, mo sì mọ̀ pé ọ̀rọ̀ mi kò sú u rárá. Ohun tí mi ò lè rí nínú ayé ló fún mi, ìyẹn sì ni àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́. Ẹgbẹ́ ará tí a ní kárí ayé ti jẹ́ kí n túbọ̀ mọyì ìfẹ́ ńláǹlà tí Jèhófà ní sí wa.”

Àǹfààní Tó Wà Nínú Bíbọ̀wọ̀ Fúnni

Ní March 30, ọdún 2014, Arákùnrin Vasilii tó ti wà lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà tipẹ́, ń fi àtẹ ìwé wàásù nítòsí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nígbà tí àwọn ọlọ́pàá gbé ọkọ̀ wọn dé.  Ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá náà sọ̀ kalẹ̀, ó sì sọ fún Arákùnrin Vasilii pé kó dáwọ́ ohun tó ń ṣe dúró torí àròyé táwọn ará àdúgbò náà ń ṣe. Ọlọ́pàá míì ń fi ẹ̀rọ gba ọ̀rọ̀ wọn sílẹ̀ sórí fídíò. Arákùnrin Vasilii wá wò ó pé ó máa dáa kí òun ṣe ohun tí ọlọ́pàá náà sọ, kí òun má sì jà fún ẹ̀tọ́ òun. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, àwọn èèyàn ti kóra jọ, wọ́n sì ń wòran. Arákùnrin Vasilii kúrò níbẹ̀, àmọ́ lẹ́yìn ọjọ́ méjì, ó lọ rí ọ̀gá àwọn ọlọ́pàá náà. Wọ́n sì jẹ́ kó wọlé. Nígbà tí Arákùnrin Vasilii wọlé, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ̀gá ọlọ́pàá náà fún iṣẹ́ pàtàkì tí wọ́n ń ṣe ládùúgbò àti bí wọ́n ṣe bá òun sọ̀rọ̀ bí ọmọlúwàbí lọ́jọ́ méjì sẹ́yìn. Ọ̀gá ọlọ́pàá náà yíjú sí igbákejì rẹ̀, ó sì sọ pé: “Ọdún kejìlélọ́gbọ̀n [32] rèé tí mo ti ń ṣiṣẹ́ ọlọ́pàá, mi ò tíì gbọ́ ọ rí kí ẹnikẹ́ni dúpẹ́ lọ́wọ́ wa!” Bí wọ́n ṣe ń bá ọ̀rọ̀ wọn lọ, Arákùnrin Vasilii jẹ́ kí ọ̀gá ọlọ́pàá náà mọ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù tí à ń ṣe bófin mu ní gbogbo ọ̀nà. Ọ̀gá ọlọ́pàá náà wá sọ pé nígbà tó mọ̀ pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti máa wàásù, kí nìdí tó fi fara mọ́ ohun tí ọlọ́pàá náà sọ pé kó dáwọ́ ohun tó ń ṣe dúró? Arákùnrin Vasilii fèsì pé: “Mo máa ń bọ̀wọ̀ fún àwọn ọlọ́pàá. Ẹ wo bó ṣe máa rí, ká ní mo fẹ̀sùn kan ọlọ́pàá yẹn pé kò mọ òfin níṣojú àwọn tó ń wòran.” Ọ̀rọ̀ yìí wú ọ̀gá ọlọ́pàá náà àti igbákejì rẹ̀ lórí gan-an, wọ́n sì fi dá Arákùnrin Vasilii lójú pé ẹnikẹ́ni kò ní yọ ọ́ lẹ́nu mọ́ níbi tó ń pàtẹ ìwé sí.