Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Iwe Odoodun Awa Elerii Jehofa​—2015

 À Ń WÀÁSÙ A SÌ Ń KỌ́NI KÁRÍ AYÉ

Awon Ile Amerika

Awon Ile Amerika
  • ILẸ̀ 57

  • IYE ÈÈYÀN 980,780,095

  • IYE AKÉDE 4,034,693

  • IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 4,339,285

Àwọn Ọmọ Aláìlóbìí Ń Wá Sípàdé

Lọ́jọ́ kan, Angela tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Suriname ṣèbẹ̀wò sí ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ aláìlóbìí nítòsí ilé rẹ̀. Arábìnrin kan tó ti di akéde aláìṣiṣẹ́mọ́ ni ọ̀gá àgbà ilé náà, torí náà ó gbà kí Angela wàásù fún àwọn ọmọ náà. Ọmọ márùnlélọ́gọ́rin [85] ni Angela wàásù fún níbẹ̀, ó sì fi fídíò hàn wọ́n látorí ìkànnì jw.org. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ púpọ̀ nínú wọn lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tó yá, àwọn  aṣáájú-ọ̀nà méjì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e lọ, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn sì ní àwùjọ tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Arábìnrin aláìṣiṣẹ́mọ́ náà sọ pé òun ti kọ́ àwọn ọmọ náà láwọn orin kan nínú ìwé orin wa, òun sì máa ń ka ìtàn Bíbélì fún wọn lálẹ́. Ó ní ó wu òun láti máa wá sípàdé, àmọ́ òun ò lè fi àwọn ọmọ márùnlélọ́gọ́rin [85] náà sílẹ̀ láwọn nìkan. Nígbà tó yá, wọ́n ṣètò bí gbogbo wọn á ṣe máa wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ilé ìtọ́jú àwọn ọmọ aláìlóbìí náà kò jìn, torí náà àwọn ará máa ń lọ bá wọn kó àwọn ọmọ náà wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ní báyìí, arábìnrin náà àti gbogbo ọmọ márùnlélọ́gọ́rin [85] yẹn ti ń wá sí ìpàdé déédéé.

Gabriel Ran Bàbá Rẹ̀ Àgbà Lọ́wọ́

Orílẹ̀-Èdè Paraguay: Gabriel ń bá bàbá rẹ̀ àgbà sọ̀rọ̀

Nígbà tí Gabriel tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà ń pa dà bọ̀ láti àpéjọ àgbègbè lórílẹ̀-èdè Paraguay, ó ń ṣàṣàrò lórí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ó wá rántí bàbá rẹ̀ àgbà, ó fẹ́ràn bàbá náà gan-an, ó sì wù ú pé kí wọ́n jọ wà nínú Párádísè. Àmọ́ bàbá àgbà yìí kò fìgbà kankan nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́, ó sì máa ń ṣàtakò sí ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Lọ́jọ́ yẹn, Gabriel ní kí àwọn òbí òun bá òun fi fídíò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì pe bàbá àti ìyá òun àgbà lórílẹ̀-èdè Ajẹntínà. Gabriel ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún bàbá rẹ̀ àgbà, ó sì bi í pé, “Bàbá àgbà, ṣé ẹ máa fẹ́ ká jọ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” Bàbá náà gbà. Gabriel sì dábàá pé káwọn jọ kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé. Fún oṣù mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n jọ kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìwé náà. Torí pé àwọn méjèèjì ò mọ ìwé kà dáadáa, ṣe ni wọ́n máa ń múra sílẹ̀. Tí wọ́n bá ti fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́, Gabriel máa ń múra sílẹ̀, ó sì máa ń wọ ṣẹ́ẹ̀tì àti táì.

 Nígbà tó yá àwọn òbí àgbà náà wá lo ọ̀sẹ̀ mélòó kan lọ́dọ̀ àwọn òbí Gabriel. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, bàbá àgbà náà máa ń bá wọn lọ sípàdé. Nígbà tí bàbá náà sì pa dà sí orílẹ̀-èdè Ajẹntínà, arákùnrin kan ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà lọ pẹ̀lú rẹ̀ lọ́hùn-ún, ó sì ti tẹ̀ síwájú débi pé ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi báyìí. Ní báyìí, bàbá àti ìyá àgbà Gabriel ti jọ ń gbàdúrà lójoojúmọ́. Gabriel náà sì ti tẹ̀ síwájú dáadáa. Òun náà ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi. Bàbá àgbà náà sì ti sọ pé ó wu òun láti fi ẹ̀rí hàn pé òun ti ya ara òun sí mímọ́ fún Jèhófà nípa ṣíṣe ìrìbọmi.

“Wíwá Yín Kì Í Ṣe Lásán”

Nígbà tí Jennifer ń pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde? lórílẹ̀-èdè Brazil, ó kan ìlẹ̀kùn obìnrin kan tó ń kánjú lọ síbi ètò ìsìnkú ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan. Jennifer wá jẹ́ kó yé e pé ìwé tó sọ nípa bí a ṣe máa pa  dà rí àwọn èèyàn wa tó ti kú náà lòun fẹ́ fún un. Àkòrí ìwé náà ya obìnrin yìí lẹ́nu gan-an, ó sì gbà á. Arábìnrin náà béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá ó máa fẹ́ mú ẹ̀dà mélòó kan dání kó lè fún àwọn tí èèyàn wọn kú, obìnrin náà fara mọ́ ọn, ó sì ní kó fún òun ní ẹ̀dà mẹ́sàn-án sí i.

Nígbà tí Jennifer pa dà lọ bẹ obìnrin yìí wò, obìnrin náà sọ pé: “Lẹ́yìn tẹ́ ẹ lọ tán lọ́jọ́ tẹ́ ẹ kọ́kọ́ wá yẹn, mo wá rí i pé wíwá yín kì í ṣe lásán. Ọlọ́run ló rán yín wá kẹ́ ẹ lè wá tù mí nínú, torí mo nílò rẹ̀ gan-an.” Obìnrin yìí ti pín gbogbo ìwé náà. Mọ̀lẹ́bí wọn kan tó wàásù níbi ètò ìsìnkú náà ka gbogbo ohun tó wà nínú ìwé náà sókè ketekete. Gbogbo wọn mọyì rẹ̀, wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ obìnrin yìí fún àwọn ọ̀rọ̀ ìtùnú tí wọ́n rí kà níbẹ̀. Obìnrin náà gbà pé ká máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Wọ́n Wàásù Nínú Ọkọ̀ Èrò

Ó ṣẹlẹ̀ pé mẹ́ta lára àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì ní orílẹ̀-èdè Haiti wọ ọkọ̀ akérò kan tí wọ́n ń pè ní tap-tap, èyí tó ní oríṣiríṣi àwọ̀. Nínú ìrìn àjò tó gba wákàtí méjì àtààbọ̀ yìí, wọ́n wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn tí wọ́n jọ wọkọ̀, àròpọ̀ ìwé tí wọ́n fi sóde sì jẹ́ àádọ́ta [50] ìwé ìròyìn àti ọgbọ̀n [30] ìwé àṣàrò kúkúrú. Ọ̀kan lára àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì náà, ìyẹn Gurvitch, ka ibì kan fún ẹnì kan nínú ọkọ̀ náà látinú ìwé ìròyìn Jí! Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Pépé fetí kọ́ ohun tí wọ́n kà, ó sì yára dá sí ọ̀rọ̀ náà. Ó ní kí wọ́n wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì wá ṣẹlẹ̀ pé ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ tí Gurvitch wà ni ọ̀dọ́kùnrin náà ń gbé. Láti oṣù January, ọdún 2014 tí Pépé ti kọ́kọ́ bá àwọn ará wa pàdé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má tíì pa ìpàdé tàbí àpéjọ kankan jẹ. Ó máa ń sọ àwọn ohun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ fún àwọn ẹlòmíì títí kan bó ṣe ń fojú sọ́nà láti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi láìpẹ́.