Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Iwe Odoodun Awa Elerii Jehofa​—2015

 À Ń WÀÁSÙ A SÌ Ń KỌ́NI KÁRÍ AYÉ

Agbegbe Oceania

Agbegbe Oceania
  • ILẸ̀ 29

  • IYE ÈÈYÀN 40,208,390

  • IYE AKÉDE 97,583

  • IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 64,675

Ìdìpọ̀ Ìwé Ni Wọ́n Fún Wọn

A ò tíì fi bẹ́ẹ̀ mú ìhìn rere dé ọ̀pọ̀ erékùṣù tó wà ní àgbègbè Micronesia. Torí náà, àwọn akéde kan láti Àwọn Erékùṣù Marshall ṣètò láti wọkọ̀ ojú omi lọ síbẹ̀ kí wọ́n lè lọ lo ọ̀sẹ̀ méjì. Wọ́n gbéra láti erékùṣù Majuro, wọ́n dé àwọn erékùṣù Wotje àti Ormed tí wọn jẹ́ ara àgbájọ erékùṣù Wotje.

Kí wọ́n lè jẹ́rìí fún àwọn èèyàn púpọ̀ bó bá ti lè ṣeé ṣe tó, àwọn ará yìí di àwọn ìwé mélòó kan pọ̀  kí wọ́n tó kúrò nílé. Ìwé ìròyìn mẹ́rin-mẹ́rin àti ìwé pẹlẹbẹ méjì-méjì ló wà nínú ìdìpọ̀ kọ̀ọ̀kan. Torí pé àwọn akéde yìí kò mọ ìgbà táwọn tún máa pa dà wá sí erékùṣù yìí, àwọn ìwé tí wọ́n dì pọ̀ yẹn ni wọ́n fi sílẹ̀ fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn, wọ́n sì rọ àwọn tí wọ́n gba àwọn ìwé náà pé kí wọ́n fún àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn lára rẹ̀. Láàárín ọ̀sẹ̀ méjì yẹn, iye ìwé pẹlẹbẹ tí àwọn akéde yìí fi sóde jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àti mọ́kànlélọ́gbọ̀n [531], iye ìwé ìròyìn jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àti mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [756], wọ́n sì tún fi ìwé ńlá méje sóde.

“O Ṣeun Gan-an Tí O Kò Gbàgbé Wa”

Ní oṣù February, ọdún 2014, àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́fà láti orílẹ̀-èdè Papua New Guinea gbéra òde ìwàásù ọlọ́jọ́ mẹ́wàá ní àwọn abúlé tó wà ní Erékùṣù Karkar ayọnáyèéfín. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fetí sílẹ̀, wọ́n sì fi ìwé tó tó ẹgbẹ̀rún kan àti mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [1,064] sóde. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Relvie sọ pé: “Lọ́jọ́ tá a bẹ̀rẹ̀, a wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù títí di aago mẹ́ta ọ̀sán. Omi tá a gbé dání ti tán, ẹnu ti ń ro wá, ọ̀fun wa sì ti gbẹ torí pé a ò yéé sọ̀rọ̀. Nígbà tí mò ń bá ọmọdébìnrin kan sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, mo fẹ́ ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan fún un, àmọ́ mi ò lè kà á torí pé òùngbẹ ń gbẹ mí lákọlákọ. Ìgbà yẹn gan-an ni ọmọ náà fi omi lọ̀ mí.”

Kó tó di pé a kúrò ní abúlé kan báyìí ní alẹ́ ọjọ́ kan, a bá ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń gbé níbẹ̀ ṣèpàdé, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ṣọ́ọ̀ṣì wọn náà sì wà níbẹ̀. Arábìnrin Relvie sọ pé: “Ṣe ni mo dà bíi Sítéfánù tó gbèjà òtítọ́ níwájú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn, ìyàtọ̀ ibẹ̀ ni pé àwọn tá a bá sọ̀rọ̀ yìí kò ṣàtakò sí wa.” Lẹ́yìn tí àwọn akéde mẹ́fà yìí ti sọ̀rọ̀ tán, obìnrin tó ń ṣe kòkáárí ilé ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi ní Ṣọ́ọ̀ṣì Lutheran dìde, ó sì  dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn akéde náà, tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, pé ó mú ẹ̀kọ́ òtítọ́ wá fáwọn èèyàn rẹ̀. Obìnrin náà ní: “Àpẹẹrẹ rere tó o fi lélẹ̀ yìí dà bíi ti obìnrin ará Samáríà tó lọ sọ àwọn ohun rere tó gbọ́ lọ́dọ̀ Jésù fún àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀. O ṣeun gan-an tí o kò gbàgbé wa.”

Ṣé Wọ́n Kéré Jù Láti Wàásù?

Erékùṣù Kiribátì: Teariki àti Tueti

Ní àárọ̀ ọjọ́ kan, ní erékùṣù Tarawa tó wà lára àwọn erékùṣù Kiribátì, ọmọ ọdún méje kan tó ń jẹ́ Teariki wà lóde ẹ̀rí pẹ̀lú Tueti, bàbá rẹ̀. Nígbà tí wọ́n wọ ilé kan, wọ́n rí àwọn ọkùnrin àti obìnrin bíi mẹ́wàá tí wọ́n jẹ́ ọmọ ogún [20] sí ọgbọ̀n [30] ọdún. Lẹ́yìn tí bàbá Teariki ti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ọ̀kan lára wọn sọ pé: “A máa ń rí i tẹ́ ẹ máa ń mú àwọn ọmọ yín kéékèèké jáde ìwàásù. Ẹ ò ṣe máa fi wọ́n sílẹ̀ nílé? Wọ́n kéré jù láti wàásù nípa Ọlọ́run.”

Arákùnrin Tueti fèsì pé: “Ṣé ẹ fẹ́ mọ̀ bóyá ọmọ mi lè wàásù? Ẹ ò ṣe jẹ́ kí n bọ́ síta, kẹ́ ẹ lè gbọ́ ohun tó máa sọ.” Wọ́n fara mọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Wọ́n ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, a fẹ́ gbọ́ ohun tó fẹ́ wí.”

Lẹ́yìn tí Tueti bọ́ síta, Teariki bi wọ́n pé, “Ṣé ẹ mọ orúkọ Ọlọ́run?”

“Ọ̀kan lára wọn fèsì pé: “Mo mọ̀ ọ́n, Jésù ni!” Òmíràn sọ pé, “Ọlọ́run.” Ẹlòmíì sì sọ pé, “Olúwa.”

Teariki wá ní: “Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ. Ẹ jẹ́ ká ṣí i sínú ìwé Aísáyà 42:5, a lè jọ kà á.” Lẹ́yìn tí wọ́n ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà, ó bi wọ́n pé, “Ta ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?”

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́ tó wà níbẹ̀ dáhùn pé: “Ọlọ́run.” Teariki wá sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Ọlọ́run tòótọ́ ló ń sọ. Tá a bá ka ẹsẹ kẹjọ, kí ni Ọlọ́run tòótọ́ sọ fún wa? Ó ní, ‘Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi; èmi kì yóò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn.’ Ṣé ẹ ti mọ orúkọ Ọlọ́run báyìí?”

 Gbogbo wọn dáhùn pé, “Jèhófà ni.”

Bí wọ́n ṣe ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, Teariki bi wọ́n pé: “Àǹfààní wo ló wà nínú lílo Jèhófà, orúkọ Ọlọ́run? Ẹ jẹ́ ká wò ó nínú Ìṣe 2:21. Ó kà pé: ‘Olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.’ Àǹfààní wo ló wà nínú lílo orúkọ Ọlọ́run?”

Ọ̀dọ́ kan lára wọn dáhùn pé, “Ká lè rí ìgbàlà.”

Ibi tí wọ́n sọ̀rọ̀ dé nìyí tí bàbá Teariki fi pa dà wọlé. Ó wá bi wọ́n pé: “Kí ni èrò yín báyìí? Ṣé àwọn ọmọ wa kéékèèké lè wàásù àbí wọn ò lè wàásù? Ṣé ó yẹ ká máa mú wọn dání àbí kò yẹ?” Gbogbo wọn gbà pé àwọn ọmọ náà lè wàásù àti pé ó yẹ ká máa mú wọn lọ sóde ẹ̀rí. Tueti wá  sọ pé, “Ẹ̀yin náà lè fi Bíbélì kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ bíi ti Teariki, tẹ́ ẹ bá kẹ́kọ̀ọ́ ohun tó wà nínú rẹ̀.”

A Mú Ìhìn Rere Dé Abúlé Kan Tó Wà Lórí Òkè

Ní oṣù November, ọdún 2013, Arákùnrin Jean-Pierre, tó ń ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè tó wà nílùú Port-Vila lórílẹ̀-èdè Vanuatu, wọ ọkọ̀ òfuurufú lọ sí erékùṣù ìbílẹ̀ rẹ̀ láti lọ ṣe àpéjọ àyíká. Nígbà tí ọkọ̀ òfuurufú tó wọ̀ gúnlẹ̀ sí erékùṣù náà, àwọn kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ wá bá a láti apá gúúsù erékùṣù náà, wọ́n sì ní kó fún àwọn ní àwọn ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìwé ìròyìn tó kó dání ló fún wọn tán. Lẹ́yìn náà ni aṣáájú ẹ̀sìn kan wá bá a pé kó fún òun náà ní ìwé. Ọkùnrin yìí rọ Arákùnrin Jean-Pierre pé kó wá sí abúlé àwọn, ó ní: “Ebi tẹ̀mí ń pa wá. Wá sí abúlé wa kó o lè wá dáhùn gbogbo ìbéèrè wa.” Ní òwúrọ̀ kùtù ọjọ́ tó tẹ̀ lé àpéjọ àyíká náà, Jean-Pierre gbéra ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn lọ sí orí òkè kan tó da gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́. Nígbà tó yá, ó dé orí òkè tí abúlé náà wà. Lẹ́yìn tí àwọn ará abúlé náà fi ọ̀yàyà kí i káàbọ̀, ó sọ ohun tó wà nínú Ìròyìn Ìjọba Ọlọ́run No. 38 fún wọn, àkòrí rẹ̀ ni, “Ǹjẹ́ Àwọn Òkú Lè Jíǹde?” Ó sọ fún nǹkan bí ọgbọ̀n [30] èèyàn tó ń fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n máa fojú bá nǹkan tí òun ń kà lọ nínú Bíbélì wọn. Nǹkan bíi wákàtí méje ni wọ́n fi bára wọn sọ̀rọ̀. Ebi tẹ̀mí ń pa àwọn ará abúlé yìí lóòótọ́! Bàbá àgbàlagbà kan tó jẹ́ ẹni àádọ́rin [70] ọdún sọ pé, “Látìgbà tí wọ́n ti bí mi, mi ò tíì gbọ́ àlàyé tó ṣe kedere báyìí nípa àwọn òkú rí!”

Abúlé náà ni Jean-Pierre sùn mọ́jú. Òun àti pásítọ̀ kan ni wọ́n jọ sùn sí yàrá. Nígbà tó jí láàárọ̀, ó rí i pé pásítọ̀ náà ti ń ka ọ̀kan lára àwọn ìwé ìròyìn wa. Arákùnrin Jean-Pierre béèrè ohun tó ń kà, ó sì sọ fún un tayọ̀tayọ̀ pé ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run lòun ń kà. Ó gbà pé Ìjọba Ọlọ́run kò sí nínú ọkàn àwọn Farisí tí Jésù dẹ́bi fún nínú ìwé  Lúùkù 17:21. Torí náà kò lè jẹ́ inú ọkàn èèyàn ni Ìjọba Ọlọ́run wà bí wọ́n ṣe fi kọ́ àwọn ní ṣọ́ọ̀ṣì. Nígbà tí Arákùnrin Jean-Pierre pa dà sí ìlú Port-Vila, ó ń kàn sí àwọn tó ti bá sọ̀rọ̀ ní abúlé náà látorí fóònú. Àwọn arákùnrin mẹ́ta láti ìjọ kan nítòsí yọ̀ǹda ara wọn láti lọ ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní abúlé náà, àwọn mọ́kàndínláàádọ́fà [109] ló pésẹ̀ síbẹ̀!

Orílẹ̀-Èdè Vanuatu