Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Iwe Odoodun Awa Elerii Jehofa​—2015

Leta Latodo Igbimo Oludari

Leta Latodo Igbimo Oludari

Ẹ̀yin Ará Wa Ọ̀wọ́n:

“Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa gbogbo yín nínú àwọn àdúrà wa, nítorí láìdabọ̀ ni a ń fi iṣẹ́ ìṣòtítọ́ yín sọ́kàn àti òpò onífẹ̀ẹ́ yín àti ìfaradà yín nítorí ìrètí yín nínú Olúwa wa Jésù Kristi níwájú Ọlọ́run àti Baba wa.” (1 Tẹs. 1:2, 3) Gẹ́lẹ́ ni ọ̀rọ̀ yìí bá èrò wa nípa yín mu! À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí yín àti nítorí àwọn iṣẹ́ ribiribi tẹ́ ẹ̀ ń ṣe. Kí nìdí?

Ìdí ni pé lọ́dún tó kọjá, ẹ ti fi taratara ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ “iṣẹ́ ìṣòtítọ́” àti “òpò onífẹ̀ẹ́” tó jẹ mọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ nínú yín ti wá ọ̀nà láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yín gbòòrò sí i. Àwọn kan ti lọ sí àwọn ìlú tàbí orílẹ̀-èdè míì tí wọ́n ti nílò ọ̀pọ̀ àwọn tó ń wàásù Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn míì sì ti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i nípa wíwàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí. Ìṣírí táwọn míì rí gbà sì ti mú kí wọ́n ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lásìkò Ìrántí Ikú Kristi, nígbà ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká tàbí nígbà ìwàásù àkànṣe tó wáyé lóṣù August ọdún 2014. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò kálukú yín yàtọ̀ síra, síbẹ̀ a gbóríyìn fún yín torí à ń rí i pé tọkàntọkàn lẹ fi ń sin Jèhófà. (Kól. 3:23, 24) Ó dájú pé àwọn “iṣẹ́ ìṣòtítọ́” yín wà lára ohun tó ń mú ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà!

Tọkàntọkàn la sì tún mọyì “òpò onífẹ̀ẹ́” tí ẹ̀ ń ṣe lẹ́nu kíkọ́ àwọn ilé tí ètò Ọlọ́run ń lò kárí ayé. A nílò àwọn ilé náà ní kánjúkánjú torí pé iye àwa èèyàn Jèhófà túbọ̀ ń pọ̀ sí i. (Aísá. 60:22) Ẹ rò ó wò ná,  mílíọ̀nù mẹ́jọ, ọ̀kẹ́ mẹ́wàá lé ẹgbẹ̀rún, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àti márùndínláàádọ́ta [8,201,545] ni iye akéde tá a ní lọ́dún tó kọjá, ìpíndọ́gba àwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóṣooṣù sì jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́sàn-án, ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlélógún lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàáwàá, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún àti mẹ́tàlélọ́gbọ̀n [9,499,933]. Nítorí ìbísí tó ń wáyé yìí, ó ti wá gba pé ká mú ọ̀pọ̀ ẹ̀ka ọ́fíìsì gbòòrò sí í tàbí ká tún wọn ṣe. Èyí sì tún fi hàn pé a nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba púpọ̀ sí i. Òmíràn ni pé a nílò ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè káàkiri àgbáyé kí àwọn atúmọ̀ èdè yìí lè máa gbé níbi tí wọ́n ti ń sọ èdè wọn, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀.

Torí náà, a lè bi ara wa pé, ‘Ọ̀nà wo ni mo lè gbà kọ́wọ́ ti àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé yìí?’ Àwọn kan lára wa lè yọ̀ǹda ara wọn kí wọ́n lè lọ́wọ́ nínú àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé yìí. Yálà a mọ̀ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé tàbí a kò mọ̀ nípa rẹ̀, gbogbo wa la láǹfààní láti máa fi àwọn ohun ìní wa tó níye lórí ṣètìlẹ́yìn fún àwọn iṣẹ́ pàtàkì yìí. (Òwe 3:9, 10) Nígbà tí wọ́n ń kọ́ àgọ́ ìjọsìn, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣètìlẹ́yìn tọkàntọkàn débi pé wọ́n ní láti kéde pé kí wọ́n má mú ohunkóhun wá mọ́. (Ẹ́kís. 36:5-7) Ó dájú pé ìwúrí làwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ yìí jẹ́ fún wa, wọ́n sì máa ń wọ̀ wá lọ́kàn. “Òpò onífẹ̀ẹ́” tẹ́ ẹ̀ ń ṣe láwọn apá tó ṣe pàtàkì nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ yìí tún wà lára ohun tó ń mú ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà!

Bí ẹ̀yin ará wa ṣe ń lo ìfaradà láìyẹhùn tún jẹ́ ká rí ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa láyọ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè South Korea. Látọdún 1950 ni wọ́n ti ń fi àwọn ọ̀dọ́kùnrin wa lórílẹ̀-èdè yẹn sẹ́wọ̀n torí pé wọn kò lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ológun. Ìgbà tí kálukú wọn ń lò lẹ́wọ̀n sì yàtọ̀ síra. Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin wa ti ń fara da ìfinisẹ́wọ̀n yìí láti ọ̀pọ̀  ọdún wá, síbẹ̀ wọn kò yẹhùn. Ìfaradà wọn túbọ̀ fún ìgbàgbọ́ wa lókun!

Ní orílẹ̀-èdè Eritrea, ó lé ní ogún [20] ọdún tí mẹ́ta lára àwọn arákùnrin wa fi wà lẹ́wọ̀n. Wọ́n sì ti fi àwọn míì, títí kan àwọn arábìnrin wa àtàwọn ọmọ wọn, sẹ́wọ̀n bí wọn ò tiẹ̀ pẹ́ níbẹ̀ tóyẹn. A ti sapá gan-an kí wọ́n lè tú wọn sílẹ̀, àmọ́ pàbó ni àwọn ìsapá yìí já sí. Síbẹ̀, àwọn ará wa kò yẹhùn. Wọ́n rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ wọn láìka bí nǹkan ṣe le koko fún wọn sí. A ò gbàgbé àwọn olóòótọ́ yìí nínú àdúrà wa.—Róòmù 1:8, 9.

Òótọ́ ni pé wọn ò fi ọ̀pọ̀ nínú yín sẹ́wọ̀n torí ìgbàgbọ́ yín. Àmọ́ ọ̀pọ̀ nínú yín ni wàhálà ọjọ́ ogbó ti dé bá, àìsàn lílekoko ń yọ àwọn míì lẹ́nu, àwọn míì ń fara da inúnibíni látọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí, ọkọ tàbí aya aláìgbàgbọ́, a sì ráwọn tó jẹ́ pé àwọn nìkan ṣoṣo ló lè ṣàlàyé ìṣòro tó ń bá wọn fínra. Síbẹ̀, ẹ̀ ń sin Jèhófà tọkàntọkàn! (Ják. 1:12) A gbóríyìn fún yín gan-an ni. Bẹ́ ẹ ṣe ń lo ìfaradà láìyẹhùn tún wà lára ìdí tá a fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà.

Ó dájú pé iṣẹ́ ìṣòtítọ́ yín, òpò onífẹ̀ẹ́ yín àti bí ẹ ṣe ń fara dà á tún jẹ́ ká rí ìdí tó lágbára tó fi yẹ ká máa “fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí tí ó jẹ́ ẹni rere.” (Sm. 106:1) A nífẹ̀ẹ́ gbogbo yín gan-an ni, àdúrà wa sì ni pé kí Jèhófà túbọ̀ máa fún yín lókun, kó mẹ́sẹ̀ yín dúró, kó sì máa bù kún yín kẹ́ ẹ lè máa sìn ín títí láé.

Àwa arákùnrin yín,

Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà