Wọ́n ‘Jẹ́ Oníṣọ̀ọ́ra bí Ejò àti Ọlọ́rùn-Mímọ́ bí Àdàbà’

Ó ṣe pàtàkì pé káwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa rí oúnjẹ tẹ̀mí gbà nígbà ìfòfindè, àmọ́ nǹkan le koko fáwọn olùjọsìn tòótọ́ lórílẹ̀-èdè náà nígbà yẹn. Lásìkò yẹn, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ni wọ́n mú tí wọ́n sì jù sẹ́wọ̀n fún àkókò tó yàtọ̀ síra.

Juanita Borges sọ pé: “Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ́dún 1953, mo mọ̀ dáadáa pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n mú èmi náà torí mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Nígbà tí mo lọ kí Arábìnrin Eneida Suárez ní oṣù November ọdún 1958, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ wá mú wa, wọ́n sì fẹ̀sùn kàn wá pé à ń ṣèpàdé. Wọ́n fi wá sẹ́wọ̀n oṣù mẹ́ta, wọ́n sì ní kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa san ọgọ́rùn-ún peso, tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún [16,000] náírà nígbà yẹn, gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn.”

Àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ní ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ nípa àwọn ará wa.

Ìjọba ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe káwa Ẹlẹ́rìí má bàa máa ṣe ìpàdé, àmọ́ ìyẹn ò dá àwọn ará wa dúró. Àmọ́ ṣá o, wọ́n ní láti ‘jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra bí ejò àti ọlọ́rùn-mímọ́ bí àdàbà.’ (Mát. 10:16) Andrea Almánzar sọ pé: “A kì í dé sípàdé nígbà kan náà. Ilẹ̀ sì máa ń ṣú gan-an ká tó pa dà sílé torí pé a kì í fẹ́ kúrò nígbà kan náà, kí wọ́n má bàa fura sí wa.”

Jeremías Glass kò ju ọmọ ọdún méje lọ nígbà tó di akéde lọ́dún 1957. Ẹ̀wọ̀n ni León, bàbá rẹ̀ wá nígbà tí wọ́n bí i. Ó rántí bí wọ́n ṣe máa ń rọra ṣèpàdé ní ìdákọ́ńkọ́ nílé wọn àtàwọn ohun tí wọ́n máa ń ṣe káwọn aláṣẹ má bàa rí wọn. Jeremías ṣàlàyé pé: “Wọ́n máa ń pín káàdì kékeré tí wọ́n ti kọ nọ́ńbà sí tó máa jẹ́ kí kálukú mọ ìgbà tóun máa jáde. Bí ìpàdé bá ti parí, bàbá mi máa ń ní kí n dúró sẹ́nu ọ̀nà kí n lè máa wo nọ́ńbà tó wà nínú káàdì àwọn tó bá ń jáde, kí n sì lè máa sọ fún wọn pé kí wọ́n jáde ní méjì-méjì, kí wọ́n má sì gba ọ̀nà ibì kan náà.”

Ohun míì tá a tún máa ń ṣe ni pé, a máa ń fi ìpàdé sí àkókò tí àwọn tó ń ṣọ́ wa kò ní fi bẹ́ẹ̀ rí wa. Bí àpẹẹrẹ, Pablo González ló kọ́ Mercedes García, ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ọmọ ọdún méje péré ni Mercedes nígbà tí ìyá rẹ̀ ṣàìsí, ẹ̀wọ̀n sì ni bàbá rẹ̀ wà nígbà yẹn. Ó wá ku òun, àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ márùn-ún àtàwọn àbúrò rẹ̀ mẹ́rin. Ọdún 1959 ni Mercedes ṣèrìbọmi nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́sàn-án. Aago mẹ́ta ààbọ̀ òru ni wọ́n sọ àsọyé ìrìbọmi rẹ̀, káwọn aláṣẹ má bàa fura sí wọn. Ilé arákùnrin kan ni wọ́n ti sọ àsọyé náà, wọ́n wá lọ rì í bọmi ní Odò Ozama tó ṣàn gba olú ìlú náà kọjá. Mercedes sọ pé: “Ìgbà tá à ń pa dà lọ sílé láago márùn-ún ààbọ̀ ìdájí làwọn ará àdúgbò ṣẹ̀ṣẹ̀ ń jí.”