Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Iwe Odoodun Awa Elerii Jehofa​—2015

 ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

Won Fi Won Sewon, Won si Fofin De Won

Won Fi Won Sewon, Won si Fofin De Won

Ìjọba Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n Torí Wọ́n Kọ̀ Láti Wọṣẹ́ Ológun

Arákùnrin Enrique Glass àti ọgbà ẹ̀wọ̀n tó ní àjàalẹ̀ tí wọ́n fi sí fún ọ̀sẹ̀ méjì

Ní June 19, ọdún 1949, àwọn ọmọ Orílẹ̀-èdè Dominican kan tí wọ́n ti kúrò nílùú tẹ́lẹ̀ wọ ọkọ̀ òfuurufú wá láti ilẹ̀ òkèèrè kí wọ́n lè gbàjọba lọ́wọ́ Rafael Trujillo tó jẹ́ apàṣẹwàá. Àmọ́ kò pẹ́ rárá tí ọwọ́ pálábá wọn fi ségi. Síbẹ̀, ìjọba Trujillo fi gbogbo àwọn tó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun àtàwọn tí wọ́n kà sí ọ̀tá ìjọba sẹ́wọ̀n. Arákùnrin León àtàwọn ará tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, títí kan Enrique àti Rafael Glass wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n kọ́kọ́ fi sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun.

León sọ pé: “Àwọn sójà ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ mú [èmi àtàwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́], wọ́n sì da ìbéèrè bò wá. Lẹ́yìn tí wọ́n halẹ̀ mọ́ wa, wọ́n fi wá sílẹ̀. Àfi bó ṣe di ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà tí wọ́n tún wá mú wa lọ́nà tí kò bá ìlànà mu pé ká wa wọṣẹ́ ológun. Nígbà tá a kọ̀ jálẹ̀, wọ́n jù wá sẹ́wọ̀n. Inú ẹ̀wọ̀n la ti pàdé àwọn mẹ́rin míì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ẹ̀gbọ́n mi àti àbúrò mi kan wà lára wọn. Lẹ́yìn tí wọ́n tú wa sílẹ̀, wọ́n tún mú wa, wọ́n sì jù wá sẹ́wọ̀n pa dà. Ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n tún pa dà mú wa lẹ́yìn ọjọ́ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n fi wá sílẹ̀. Nǹkan bí ọdún méje la lò lẹ́wọ̀n, ẹ̀wọ̀n ọdún márùn-ún ni wọ́n sì dá fún wa kẹ́yìn.”

‘Àní, láwọn ìgbà tí wọ́n nà wá lẹ́gba tàbí tí wọ́n fi igi tàbí ìdí ìbọn gún wa, a fara dà á, torí pé Jèhófà fún wa lókun’

Léraléra ni àdánwò ìgbàgbọ́ ń dojú kọ àwọn ará wa lẹ́wọ̀n. Àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ tọ̀sán tòru. Ọ̀gá àwọn ẹ̀ṣọ́ tó wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Fort Ozama tí wọ́n kọ́kọ́ fi wá sí sọ pé: “Ẹ̀yin ajẹ́rìí Jèhófà, mo fẹ́ kẹ́ ẹ wá sọ fún mi tẹ́ ẹ bá ti di ajẹ́rìí Èṣù, kí n lè tú yín sílẹ̀.” Àmọ́ gbogbo ìhàlẹ̀ àwọn alátakò yìí ò ba ìwà títọ́ àwọn ará wa tó jẹ́ adúróṣinṣin jẹ́. León sọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀, ó ní: ‘Ìgbà gbogbo ni Jèhófà ń fún wa lókun ká lè fara dà á, a sì ń rọ́wọ́ rẹ̀ lára wa, kódà nínú àwọn ohun tí ò tó nǹkan pàápàá. Àní, láwọn ìgbà tí wọ́n nà wá lẹ́gba tàbí tí wọ́n fi igi tàbí ìdí ìbọn gún wa, a fara dà á, torí pé Jèhófà fún wa lókun.’

Ìjọba Fòfin De Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Láwọn apá ibòmíràn ní Orílẹ̀-èdè Dominican, ṣe ni àwọn alátakò ìjọsìn tòótọ́ ń koná mọ́ inúnibíni. Síbẹ̀, nígbà tó fi máa di oṣù May ọdún 1950, òjìlérúgba dín méjì [238] akéde ló ti wà lórílẹ̀-èdè náà láfikún sí àwọn míṣọ́nnárì. Mọ́kànlélógún [21] lára àwọn akéde náà ló sì jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà alákòókò kíkún.

Ìwé ìròyìn gbé e jáde pé wọ́n ti fi àwọn ará wa sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n kọ̀ jálẹ̀ láti wọṣẹ́ ológun

Lásìkò yẹn, òṣìṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kan kọ̀wé sí Akọ̀wé Ààrẹ Orílẹ̀-Èdè pé: “Àwọn ẹ̀ya ẹ̀sìn tó ń jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn ṣì ń fi ìtara ṣiṣẹ́ wọn ní gbogbo ìlú [Ciudad Trujillo] wa yìí.” Ó tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Màá tún sọ pé kí ìjọba wá nǹkan gbòógì ṣe sọ́rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ yìí. Torí pé wọ́n ń fi iṣẹ́ ìwàásù wọn àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n ń ṣe gbé nǹkan gbòdì kí wọ́n lè yí àwọn èèyàn lérò pa dà, pàápàá àwọn tí kò mọwọ́ ọ̀tún yàtọ̀ sósì.”

Ọ̀gbẹ́ni J. Antonio Hungría tó jẹ́ Akọ̀wé Ìjọba Lórí Ètò Abẹ́lé àti Ètò Ọlọ́pàá ní kí Arákùnrin Brandt kọ lẹ́tà wá láti fi ṣàlàyé èrò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa iṣẹ́ ológun, kíkí àsíá àti sísan owó orí. Arákùnrin Brandt lo àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé “Jeki Ọlọrun Jẹ Olõtọ” láti fi kọ lẹ́tà náà. Síbẹ̀, ní June 21, ọdún 1950, Ọ̀gbẹ́ni Hungría pàṣẹ tó fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Orílẹ̀-èdè Dominican. Ó ní kí Arákùnrin Brandt wá sí ọ́fíìsì òun láti wá fi etí ara rẹ̀ gbọ́ àṣẹ náà. Arákùnrin Brandt wá ní ṣé ó fẹ́ kí àwọn míṣọ́nnárì kúrò lórílẹ̀-èdè náà ni? Àmọ́ Ọ̀gbẹ́ni Hungría sọ pé kò pọn dandan kí wọ́n lọ, tí wọ́n bá ti gbà pé àwọn máa pa òfin mọ́ tí wọn ò sì ní máa sọ̀rọ̀ ẹ̀sìn wọn fáwọn èèyàn. *

^ ìpínrọ̀ 1 Lọ́sẹ̀ mélòó kan kí wọ́n tó pàṣẹ náà, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Kátólíìkì gbé àwọn àpilẹ̀kọ gígùn jàn-ànràn jan-anran jáde nínú ìwé ìròyìn láti fi bẹnu àtẹ́ lu àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì tún fẹ̀sùn kàn wá pé ìjọba Kọ́múníìsì là ń ṣojú fún.