“Kí A Gba Gbogbo Onírúurú Ènìyàn Là”

Ìfẹ́ Jèhófà ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Orílẹ̀-èdè Dominican ti sapá gidigidi láti wàásù fáwọn èèyàn jákèjádò ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn, títí kan àwọn tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n orílẹ̀-èdè náà.

Ní ọdún 1997, nígbà tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe méjì kan ń ṣèbẹ̀wò ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ sí Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Najayo tó wà nílùú San Cristóbal, wọ́n rí ọmọ ilẹ̀ Kòlóńbíà kan tó ń jẹ́ Gloria, ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún [23] ni, ó ń ṣẹ̀wọ̀n torí pé ó máa ń gbé oògùn olóró. Obìnrin yìí ti máa ń bá arábìnrin kan tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n lọ́nà tí kò tọ́ sọ̀rọ̀. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe yìí fún Gloria ní ìwé Reasoning From the Scriptures àtàwọn ìtẹ̀jáde míì kó lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè rẹ̀ látinú Bíbélì. Bó ṣe ń fìtara kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípa lórí àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù, èyí sì mú kí àwọn tó wà nínú àwùjọ tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe náà ń ṣèbẹ̀wò sí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ máa pọ̀ sí i.

Ẹ̀kọ́ òtítọ́ yí ìgbésí ayé Gloria pa dà pátápátá, èyí mú kó di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi lọ́dún 1999. Ó lé ní àádọ́rin [70]  wákàtí tó fi ń wàásù lóṣooṣù lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà, ó sì ń kọ́ mẹ́fà lára àwọn tí wọ́n jọ wà lẹ́wọ̀n lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Lọ́dún 2000, Gloria kọ̀wé láti béèrè fún ìtúsílẹ̀, ààrẹ orílẹ̀-èdè náà sì fọwọ́ sí i pé kí wọ́n tú u sílẹ̀ torí ìwà rere tó ń hù. Wọ́n tú u sílẹ̀, wọ́n sì dá a pa dà sí orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà. Gloria ṣèrìbọmi kété lẹ́yìn tó pa dà sí ìlú rẹ̀ lọ́dún 2001, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kò fara mọ́ ìpinnu tó ṣe yìí rárá.

Gloria Cardona kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nígbà tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Òun àti ọkọ rẹ̀ ti di aṣáájú-ọ̀nà báyìí

Lẹ́yìn tí Gloria ṣèrìbọmi, ó di aṣáájú-ọ̀nà. Ó fẹ́ arákùnrin alàgbà kan tí òun náà jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ní báyìí, wọ́n ń sìn ní àgbègbè kan tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i lórílẹ̀-èdè Kòlóńbíà. Arábìnrin Gloria ti ran ọ̀pọ̀ àwọn tó kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ kí wọ́n lè ya ara wọn sí mímọ́, kí wọ́n sì ṣèrìbọmi. Ó sọ pé òun mọyì ohun tí Jèhófà ṣe fún òun, ọ̀nà tí òun sì lè gbà fi hàn pé òun moore ni pé kí òun ṣe ohun ti Jèhófà ti ṣe fún òun fáwọn ẹlòmíì nípa kíkọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

Ìtàn Arábìnrin Gloria ti jẹ́ ká rí i pé, àgádágodo lẹ́nu ọ̀nà ọgbà ẹ̀wọ̀n kò dí àwọn tó wà lẹ́wọ̀n lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó ń gbẹ̀mí là. Torí náà, àwọn aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lọ gbàṣẹ lọ́dọ̀ Ọ́fíìsì Ìjọba Tó Ń Rí sí Ọ̀ràn Ọgbà Ẹ̀wọ̀n ká lè máa dé àwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n púpọ̀ sí i ká sì máa kọ́ àwọn tó wà níbẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Látàrí ìyẹn, àwọn arákùnrin mẹ́tàlélógójì [43] àtàwọn arábìnrin mẹ́fà ni wọ́n ti fún láṣẹ pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́gbà ẹ̀wọ̀n mẹ́tàlá [13] lórílẹ̀-èdè náà.

“Mú Kí Àwọn Okùn Àgọ́ Rẹ Gùn Sí I”

Nígbà tó fi máa di ọdún 2000, iye akéde ìhìn rere tó wà ní Orílẹ̀-èdè Dominican ti di ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógún, ẹgbẹ̀ta àti mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [21,684], iye ìjọ jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún àti méjìlélógójì [342], iye àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n àti okòó dín nírinwó [34,380]. Àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógójì, ẹgbẹ̀ta àti mọ́kàndínlọ́gọ́rin [72,679]. Nítorí ìbísí tó wáyé yìí, àwọn  èèyàn Jèhófà ò jáfara láti ṣe ohun tí Aísáyà sọ pé: “Mú kí ibi àgọ́ rẹ túbọ̀ ní àyè gbígbòòrò. Kí wọ́n sì na àwọn aṣọ àgọ́ ibùgbé rẹ títóbilọ́lá. Má fawọ́ sẹ́yìn. Mú kí àwọn okùn àgọ́ rẹ gùn sí i.”—Aísá. 54:2.

Ohun kan tó wá kù báyìí ni bá a ṣe máa ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó máa gba àwọn akéde tó ń pọ̀ sí i yìí. Lọ́dún 1996, wọ́n parí kíkọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà nítòsí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nílùú Santo Domingo, ó sì wúlò gan-an fún àwọn ará tó wà ní olú ìlú orílẹ̀-èdè náà àtàwọn àgbègbè rẹ̀. Àmọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà ní Villa González, táwọn ará yòókù lórílẹ̀-èdè náà ti ń ṣèpàdé nílò àtúnṣe lójú méjèèjì tàbí kí wọ́n kọ́ òmíràn.

Ní ọdún 2001, inú àwọn ará dùn láti gbọ́ pé Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti fọwọ́ sí i pé kí wọ́n kọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó lè gba ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [2,500] èèyàn sí ìlú Villa González. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ará tún kún fún ayọ̀ pé wọ́n máa kọ́ ilé kan tí wọ́n á ti máa ṣe Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ [MTS] (tá a wá mọ̀ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run báyìí). Itòsí Gbọ̀ngàn Àpéjọ yìí ni wọ́n máa kọ́ ọ sí, ó sì máa ní àwọn yàrá tó jẹ́ ibùwọ̀, kíláàsì kan, yàrá ìkàwé, ilé ìdáná àti yàrá ìjẹun. Arákùnrin Theodore Jaracz tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló wá sọ àsọyé ìyàsímímọ́ àwọn ilé tuntun náà lọ́dún 2004. Látìgbà yẹn, kíláàsì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ló ti kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ náà.