Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

Mi O Fe Sin Olorun Mo

Martín Paredes

Mi O Fe Sin Olorun Mo
  • WỌ́N BÍ I NÍ 1976

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1991

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ìgbà tí Martín ń kẹ́kọ̀ọ́ láti di àlùfáà ló rí òtítọ́. Ó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ látìgbà yẹn, káwọn náà lè di olùjọsìn tòótọ́.

INÚ ìdílé tí wọ́n ti fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀sìn Kátólíìkì ni wọ́n ti tọ́ mi dàgbà, wọ́n sì fẹ́ kí n di àlùfáà. Torí náà, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá [12], mo gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ oríṣi mẹ́ta lọ́dọ̀ àlùfáà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Nígbà tí mo sì pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14] lọ́dún 1990, mo wọ ọ̀kan lára ilé ẹ̀kọ́ àwọn àlùfáà tó dára jù lọ ní Orílẹ̀-èdè Dominican.

Mo yára tẹ̀ síwájú nílé ẹ̀kọ́ náà, wọ́n sì sọ fún mi pé tí mo bá túbọ̀ jára mọ́ ẹ̀kọ́ náà, ó ṣeé ṣe kí n di bíṣọ́ọ̀bù. Àmọ́ nǹkan tojú sú mi nígbà tó yá. Èrò orí àwọn èèyàn ni wọ́n fi ń kọ́ wa dípò Bíbélì. Yàtọ̀ síyẹn, oníṣekúṣe paraku làwọn àlùfáà wọ̀nyẹn. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí mi ò fẹ́ sin Ọlọ́run mọ́ torí bí wọ́n ṣe ń fi ìṣekúṣe lọ̀ mí.

Ìgbà yẹn ni tọkọtaya míṣọ́nnárì kan wá sọ́dọ̀ olùṣirò owó nílé ẹ̀kọ́ àlùfáà tá a wà, wọ́n sì fún un ní ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́. Mo tọrọ ìwé náà, mo sì kà á láti páálí dé páálí. Mo wá sọ fún ara mi pé, ‘Ohun tí mo ti ń wá nìyí.’ Bí mo ṣe fi ilé ẹ̀kọ́ yẹn sílẹ̀ nìyẹn, mo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé. Oṣù mẹ́jọ lẹ́yìn náà ni mo ṣèrìbọmi ní oṣù July ọdún 1991. Mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà déédéé, mo sì fẹ́ arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ María. A ti di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe látọdún 2006. Dípò kí n fi Ọlọ́run sílẹ̀, mo ti wá fẹ́ láti máa ran àwọn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run lọ́wọ́ láti di olùjọsìn tòótọ́.