Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Iwe Odoodun Awa Elerii Jehofa​—2015

 ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

Jehofa Mu Ki Opo Eeyan Wa Kekoo

Leonardo Amor

Jehofa Mu Ki Opo Eeyan Wa Kekoo
  • WỌ́N BÍ I NÍ 1943

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1961

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́. Ó sì ti lé ní àádọ́ta [50] ọdún báyìí tó ti ń sin Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún.

MÒ Ń kẹ́kọ̀ọ́ òfin lọ́wọ́ ní yunifásítì nígbà tí wọ́n pa Trujillo lọ́dún 1961. Nǹkan bí oṣù kan lẹ́yìn náà ni mo ṣèrìbọmi. Iṣẹ́ amòfin ni bàbá mi fẹ́ kí n ṣe, àmọ́ mo rí i pé ẹ̀kọ́ tí Jèhófà ń kọ́ wa ṣe pàtàkì jùyẹn lọ. Torí náà, láìka bí bàbá mi ṣe ń fúngun mọ́ mi sí, mo fi yunifásítì sílẹ̀. Kò sì pẹ́ rárá lẹ́yìn náà tí wọ́n fi ní kí n máa sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.

Ìlú La Vega wà lára àwọn ìlú tí wọ́n gbé mi lọ. Ọjọ́ pẹ́ táwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ti gbilẹ̀ níbẹ̀. Ní gbogbo ìgbà tí mo fi wà níbẹ̀, kò sẹ́ni tó wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Tí mo bá ń sọ àsọyé, ẹni tá a jọ ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà nìkan ló máa ń wà níbẹ̀ láti tẹ́tí gbọ́ mi. Síbẹ̀, Jèhófà fún mi lókun nípasẹ̀ àwọn àpéjọ tí mo máa ń lọ, àdúrà kíkankíkan àti bí mo ṣe máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tí mo bá ń gbàdúrà, mo máa ń bi Jèhófà bóyá ìjọ ṣì máa wà nílùú La Vega. Inú mi dùn láti sọ pé Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ti wà nílùú náà báyìí. Ìjọ ti di mẹ́rìnlá [14] níbẹ̀, iye akéde Ìjọba Ọlọ́run tó wà níbẹ̀ sì ti lé ní ẹgbẹ̀rin [800].

Ọdún 1965 ni mo fẹ́ Ángela, wọ́n sì pè wá sí Bẹ́tẹ́lì lọ́dún 1981. Nígbà tí mo ṣèrìbọmi, ẹgbẹ̀ta àti mọ́kànlélọ́gọ́rin [681] ni iye akéde tó wà ní Orílẹ̀-èdè Dominican. Àmọ́ ní báyìí, iye akéde ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógójì [36,000], ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló sì máa ń kóra jọ láwọn àpéjọ wa. Tí n bá ronú pa dà sẹ́yìn, ó máa ń yà mí lẹ́nu láti rí bí Jèhófà ṣe mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ inú Bíbélì.

Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Reiner Thompson, Juan Crispín, Thomas Dean, Leonel Peguero, Leonardo Amor àti Richard Stoddard