Àwọn Míṣọ́nnárì Ń Báṣẹ́ Lọ Lábẹ́lẹ̀

Látìgbà tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè yìí ni ojú àwọn ará wa ti bẹ̀rẹ̀ sí í rí màbo. Arábìnrin Alma Parson tó jẹ́ míṣọ́nnárì sọ pé: ‘Wọ́n ti àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa pa, wọ́n sì ka iṣẹ́ wa léèwọ̀. Àdánwò táwọn ará wa ọ̀wọ́n dojú kọ àti ìyà tí wọ́n fi jẹ wọ́n nígbà yẹn kúrò ní kèrémí.’ Bí wọ́n ṣe ń lé wọn kúrò níbi iṣẹ́ ni wọ́n tún ń jù wọ́n sẹ́wọ̀n. Àmọ́ inú Arábìnrin Parson dùn bó tún ṣe rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: ‘Àìmọye ìgbà là ń rọ́wọ́ ìtọ́sọ́nà àti ààbò Jèhófà kedere lára wa.’ Torí pé àwọn ará náà ò ṣiyè méjì nípa ‘ọwọ́ ìtọ́sọ́nà’ Jèhófà, wọ́n ń báṣẹ́ náà lọ lábẹ́lẹ̀.

Wọn ò gbà wá láyè láti ṣèpàdé ìjọ mọ́. Arákùnrin Lennart Johnson sọ pé: ‘Àwọn ará pín ara wọn sí àwùjọ kéékèèké wọ́n sì rọra ń ṣèpàdé nínú àwọn ilé àdáni. Ibẹ̀ la ti ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ tá a fi ẹ̀rọ ṣe àdàkọ rẹ̀. Gbogbo àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin nígbà yẹn mọyì okun tẹ̀mí tí Jèhófà ń fún wa nínú àwọn àwùjọ kéékèèké náà.’

Roy àti Juanita Brandt wà lára àwọn tí kò kúrò lórílẹ̀-èdè náà nígbà ìfòfindè

Ní gbogbo àkókò yẹn, ìjọba túbọ̀ ń ṣe òfíntótó, wọn ò sì yéé fòòró ẹ̀mí àwọn ará wa, àmọ́ wọn kò bẹ̀rù. Nínú ìwé tí Ọ̀gbẹ́ni Hungría tó jẹ́ akọ̀wé ìjọba kọ sí Ààrẹ Orílẹ̀-èdè ní September 15, ọdún 1950, ó sọ pé: “A ti pe Ọ̀gbẹ́ni Lee Roy Brandt àtàwọn olùdarí míì lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sí ọ́fíìsì yìí léraléra, a sì ti sọ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ polongo ẹgbẹ́ wọn tá a ti fòfin dè ní orílẹ̀-èdè yìí mọ́. Àmọ́ wọ́n kọ etí ikún sí àṣẹ yẹn. Ojoojúmọ́ ni ìròyìn ń tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nílẹ̀ yìí pé wọn ò jáwọ́, ṣe ni wọ́n ń polongo ara wọn kiri lábẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì ń fi àwọn èròǹgbà ìjọba ṣe yẹ̀yẹ́.” Nígbà tó máa parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó dámọ̀ràn pé kí ìjọba lé gbogbo “ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó ń múpò iwájú nínú dídarí” àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò nílùú.

‘Ìgbàgbọ́ Wọn Túbọ̀ Lágbára’

Lọ́wọ́ ìparí ọdún 1950, Arákùnrin Knorr àti Henschel bẹ orílẹ̀-èdè náà wò. Lẹ́yìn náà, wọ́n gbé àwọn kan lára àwọn míṣọ́nnárì tó wà níbẹ̀ lọ sí orílẹ̀-èdè Ajẹntínà, Guatemala àti Puerto Rico. Àwọn yòókù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kí ìjọba lè jẹ́ kí wọ́n dúró sílùú. Bí àpẹẹrẹ, Arákùnrin Brandt bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nílé iṣẹ́ mànàmáná, àwọn yòókù sì ń kọ́ àwọn èèyàn ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ìwé Ọdọọdún 1951 [Gẹ̀ẹ́sì] sọ nípa àwọn míṣọ́nnárì náà pé: “Bí wọ́n ṣe dúró sí orílẹ̀-èdè náà tí wọn ò sì sá lọ nígbà rògbòdìyàn yìí mú kí ìgbàgbọ́ àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn Olúwa tí wọ́n tipasẹ̀ wọn kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ túbọ̀ lágbára. Inú gbogbo wọn ń dùn bí wọ́n ṣe ń rí i pé àwọn míṣọ́nnárì yìí fìgboyà dúró sídìí iṣẹ́ wọn.”

‘Bí wọ́n ṣe dúró mú kí ìgbàgbọ́ àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn lágbára’

Dorothy Lawrence wà lára àwọn míṣọ́nnárì tó ń kọ́ àwọn èèyàn lédè Gẹ̀ẹ́sì. Ní àfikún sí ìyẹn, ó tún máa ń kọ́ àwọn tó bá fìfẹ́ hàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Èyí mú kó lè ran àwọn kan lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.

Àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà tún dá àwọn ọgbọ́n míì kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù lọ láìka bí wọ́n ṣe ń ṣọ́ wọn lọ́wọ́ lẹ́sẹ̀ sí. Nígbà míì wọ́n máa ń yọ ojú ìwé mélòó kan nínú àwọn ìwé wa sínú àpò ẹ̀wù wọn tàbí kí wọ́n fi sínú báàgì tí wọ́n fi ń ra ọjà, káwọn èèyàn má bàa fura sí wọn tí wọ́n bá ń wàásù. Wọ́n ṣe ìwé tí wọ́n fi ń ròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá bí ìwé ọjà rírà. Dípò kí wọ́n kọ iye ìwé ńlá, ìwé pẹlẹbẹ, ìwé ìròyìn, ìpadàbẹ̀wò àti wákàtí sínú ìwé náà, ìbẹ́pẹ, ẹ̀wà, ẹyin, kábéèjì àti ẹ̀fọ́ tẹ̀tẹ̀ ni wọ́n fi ń rọ́pò wọn. Pákí ni wọ́n máa ń pe Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n fi ẹ̀rọ ṣe àdàkọ rẹ̀ torí pé pákí tàbí ẹ̀gẹ́ pọ̀ dáadáa lágbègbè náà.

Iṣẹ́ Sísọni Di Ọmọ Ẹ̀yìn Kò Dáwọ́ Dúró

Ní June 16, ọdún 1954, Ọ̀gbẹ́ni Rafael Trujillo tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn pẹ̀lú àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì, èyí tó fún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn náà láwọn àkànṣe àǹfààní ní Orílẹ̀-èdè Dominican. Nígbà yẹn, ó ti ń lọ sí nǹkan bí ọdún mẹ́rin tí wọ́n ti fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Síbẹ̀, nígbà tó fi máa di ọdún 1955, iye akéde tó wà ní Orílẹ̀-èdè Dominican ti di irínwó àti méjìdínlọ́gọ́rin [478]. Kí ló mú kí irú ìbísí yìí wáyé pẹ̀lú bí nǹkan ṣe le koko yẹn? Ìwé Ọdọọdún 1956 [Gẹ̀ẹ́sì] sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà ló ń fún wa lókun. Àwọn ará ní ìgbàgbọ́ tó lágbára, wọ́n wà níṣọ̀kan, wọ́n sì ń fìgboyà bá iṣẹ́ náà lọ.”

Ní oṣù July, ọdún 1955, a fi lẹ́tà tí agbẹjọ́rò wa kọ láti oríléeṣẹ́ wa jíṣẹ́ fún Ọ̀gbẹ́ni Trujillo. Lẹ́tà náà ṣàlàyé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nípa bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣeé dá sí ọ̀rọ̀ ogun àti òṣèlú, ó sì rọ Ọ̀gbẹ́ni Trujillo pé kó ‘mú òfin tí wọ́n fi de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti àjọ Watch Tower Bible and Tract Society kúrò.’ Ibo lọ̀rọ̀ náà wá já sí?