Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Iwe Odoodun Awa Elerii Jehofa​—2015

 ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

Jagunjagun Ti Ko Gba Pe Olorun Wa Di Iranse Olorun

Juan Crispín

Jagunjagun Ti Ko Gba Pe Olorun Wa Di Iranse Olorun
  • WỌ́N BÍ I NÍ 1944

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1964

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Jagunjagun tí kò gbà pé Ọlọ́run wà tẹ́lẹ̀, tó ti wá pé àádọ́ta [50] ọdún báyìí tó ti ń sin Jèhófà láìyẹsẹ̀.

NÍGBÀ tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, bí ìtàn ẹ̀sìn ṣe kún fún ìkórìíra tojú sú mi. Bí Ọlọ́run ò ṣe tíì fi òpin sí ipò òṣì àti ìwà ìrẹ́jẹ máa ń rú mi lójú. Ìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn kì í fi í ṣe ohun tí Bíbélì sọ sì tún máa ń ṣe mí ní kàyéfì. Torí náà, mo dẹni tí kò gbà pé Ọlọ́run wà, mo sì ronú pé àtúnṣe sọ́rọ̀ òṣèlú nìkan ló lè tún ayé yìí ṣe.

Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìwé ìròyìn Jí! lọ́dún 1962. Nígbà tó sì di ọdún 1963, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tí mo kọ́ wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Mo wá rí i pé kò yẹ kí n máa dá Ọlọ́run lẹ́bi torí onírúurú ìwà ìbàjẹ́ táwọn ẹlẹ́sìn ń hù àti pé Ọlọ́run ní àwọn ohun pàtàkì lọ́kàn fún aráyé tó fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa. Ní oṣù méjì péré lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni mo ti ń sọ fáwọn èèyàn pé Ìjọba Ọlọ́run máa rọ́pò ayé tí ìwà ìbàjẹ́ kúnnú rẹ̀ yìí. Mo ṣèrìbọmi lọ́dún 1964, mo sì di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lọ́dún 1966. Mo gbà pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ ló gba ẹ̀mí mi là torí pé ọ̀pọ̀ àwọn tá a jọ ń jagun nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ọ́ ni wọ́n ti jù sẹ́wọ̀n. Àwọn míì ti sá kúrò nílùú, wọ́n sì ti pa àwọn míì ní ìpa ìkà. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó yí mi pa dà. Mi ò gbà tẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run wà, mi ò sì nírètí, àmọ́ mo dúpẹ́ pé Jèhófà tó ṣèlérí ayé tuntun òdodo ti sọ mí di ìránṣẹ́ rẹ̀.

Arákùnrin Crispín ń darí ìjọsìn òwúrọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì