Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

 ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

Bi Mo Se Mo Ohun Ti Maa Fi Aye Mi Se

José Estévez

Bi Mo Se Mo Ohun Ti Maa Fi Aye Mi Se
  • WỌ́N BÍ I NÍ 1968

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1989

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Nígbà tí José wà ní kékeré, ó kó lọ sí ìgboro kó lè rí tajé ṣe. Ibẹ̀ ló ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó nítara, ó sì ti ń fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún báyìí.

ỌMỌ ọdún mọ́kànlá ni José nígbà tó kó lọ sí ìlú Santo Domingo. Ó máa ń tún bàtà ṣe, ó máa ń ta ọsàn, ó sì máa ń ta àwọn ohun aládùn tó tutù láti fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀. Nígbà tó fi máa di ọ̀dọ́, àwọn èèyàn ti mọ̀ ọ́n sí òṣìṣẹ́ kára. Ní ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn náà, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni kó máa bá òun bójú tó ilé òun. Ibẹ̀ ni José ti rí ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye lórí tábìlì tí wọ́n ti ń jẹun. José ka ìwé náà mọ́jú òru ọjọ́ náà. Ó wá rí i pé òun ti rí ohun kan tó máa jẹ́ kí ayé òun nítumọ̀.

Ní òpin ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, José lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà nítòsí rẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòun. Ó sọ fún àwọn ará pé òun ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ kí òun máa lọ sípàdé kí òun sì máa wàásù ìhìn rere. Ó tún sọ fún wọn pé òun ti kà  nípa àwọn ohun tí kò yẹ káwọn Kristẹni máa ṣe nínú ìwé Iwọ Le Walaaye, ó sì fi dá wọn lójú pé òun kì í ṣe èyíkéyìí nínú àwọn ohun tí kò dáa yẹn. Ní ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn náà ni José di akéde. Ó sì ṣèrìbọmi ní oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlélógún [21].

Nígbà tí iṣẹ́ José kò jẹ́ kó ráyè ìpàdé dáadáa, ó fi iṣẹ́ náà sílẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míì tí owó tí wọ́n ń san níbẹ̀ kò ju ìdá mẹ́rin iye tó ń gbà tẹ́lẹ̀ lọ. Ó ti wá ń ráyè ìpàdé dáadáa báyìí, ó sì tún ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Àmọ́ lẹ́yìn tó gbéyàwó tó sì bímọ ọkùnrin méjì, kò ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà mọ́.

Arákùnrin José pinnu láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láti kékeré. Torí náà, nígbà tó di oṣù kẹta tí Josefina ìyàwó rẹ̀ ti lóyún Noé, ọmọ rẹ̀ àkọ́bí, ó máa ń ka Ìwé Ìtàn Bíbélì sókè kí ọmọ náà lè máa gbọ́ ọ nínú ikùn ìyá rẹ̀ lọ́hùn-ún. Nígbà tí wọ́n fi máa bí Noé, José ti ka ìwé náà fún un láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin. Bákan náà ló sì ṣe fún Neftalí, ọmọ wọn kejì.

Nígbà tó yá, José di ọ̀gá àgbà níbi iṣẹ́ okòwò kan, owó tí wọ́n ń san fún un níbẹ̀ sì jẹ́ ìlọ́po mẹ́wàá èyí tó ń gbà tẹ́lẹ̀. Àmọ́ lọ́dún 2008, nígbà táwọn ọmọ rẹ̀ pé ọmọ ọdún mẹ́wàá àti mẹ́tàlá, ó fi iṣẹ́ náà sílẹ̀, ó sì pa dà sẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ rẹ̀ sì dara pọ̀ mọ́ ọn. Torí pé owó tó ń wọlé fún wọn ti wá dín kù gan-an báyìí, ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ ní láti pawọ́ pọ̀ kí wọ́n lè dín ìnáwó wọn kù. Nǹkan bí ọgbọ̀n [30] èèyàn làwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóṣooṣù. Jésù fi dá wa lójú pé Jèhófà máa bù kún wa tá a bá fi Ìjọba rẹ̀ sípò àkọ́kọ́. (Mát. 6:33) José àti ìdílé rẹ̀ gbọ́kàn lé ìlérí yẹn wọ́n sì ti fi ojú ará wọn rí i pé Jèhófà máa ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.