Bá A Ṣe Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ìwàásù

Lọ́jọ́ Sunday, April 1, ọdún 1945, Arákùnrin àti Arábìnrin Lennart àti Virginia Johnson dé sí olú ìlú Orílẹ̀-èdè Dominican, ìyẹn ìlú Ciudad Trujillo (tí wọ́n ń pè ní Santo Domingo báyìí). Wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Àwọn ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó máa kọ́kọ́ wá sí orílẹ̀-èdè yìí, ó sì ti pẹ́ tí ìjà àti rògbòdìyàn ti gbalẹ̀ kan níbẹ̀. * Ìwé Ọdọọdún 1946 [Gẹ̀ẹ́sì] sọ pé: “Ìpínlẹ̀ ìwàásù tó dáa fún iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lèyí, àmọ́ àwọn tó ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì dé yìí ló máa bẹ̀rẹ̀ gbogbo ohun tó yẹ ní ṣíṣe níbẹ̀.” Fojú inú wò ó ná: Kò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, kò sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, kò sì sí ìjọ kankan. Àwọn míṣọ́nnárì náà ò mọ ẹnikẹ́ni lórílẹ̀-èdè náà, tá-tà-tá ni wọ́n gbọ́ nínú èdè Sípáníìṣì, wọn ò nílé, wọn ò sì ní àga tàbí ibùsùn kankan. Kí ni wọ́n máa ṣe báyìí?

Arákùnrin Johnson sọ pé: “Òtẹ́ẹ̀lì kan tí wọ́n ń pè ní Victoria la gbalé sí. Dọ́là márùn-ún (ìyẹn nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ náírà) là ń san lójúmọ́ fún owó ilé àti owó oúnjẹ tá à ń jẹ níbẹ̀. Ọ̀sán ọjọ́ yẹn la bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé wọn. Bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ rèé: Àwọn obìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Dominican tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tá a wà ní Brooklyn fún wa lórúkọ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn àtàwọn kan tí wọ́n mọ̀ lórílẹ̀-èdè náà. Ọ̀kan lára wọn ni Dókítà tó ń jẹ́ Green. Nígbà tá a wá a lọ, a tún rí aládùúgbò rẹ̀ kan tó ń jẹ́ Moses Rollins. Lẹ́yìn tá a sọ bá a ṣe mọ orúkọ àti àdírẹ́sì wọn, wọ́n fara balẹ̀ gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì gbà pé ká máa wá kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni Ọ̀gbẹ́ni Moses di akéde Ìjọba Ọlọ́run àkọ́kọ́ lórílẹ̀-èdè náà.”

 Àwọn míṣọ́nnárì mẹ́rin míì dé níbẹ̀rẹ̀ oṣù June ọdún 1945. Kò pẹ́ rárá tí wọ́n fi fi ìwé rẹpẹtẹ sóde, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í darí ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó fi máa di oṣù October, wọ́n rí i kedere pé wọ́n nílò ilé tí wọ́n á ti máa ṣèpàdé. Torí náà, àwọn míṣọ́nnárì yìí ṣe àtúntò pálọ̀ àti yàrá ìjẹun wọn, kó lè ṣeé lò gẹ́gẹ́ bíi Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ó tó ogójì [40] èèyàn tó máa ń ṣèpàdé níbẹ̀.

Ọ̀gbẹ́ni Pablo Bruzaud náà wà lára àwọn tó kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Palé ni ọ̀pọ̀ èèyàn mọ ọkùnrin náà sí, ó sì máa ń wa ọkọ̀ èrò tó ń ná ìlú Santiago sí Ciudad Trujillo. Torí náà, ó máa ń lọ sí olú ìlú orílẹ̀-èdè náà léraléra. Lọ́jọ́ kan tí Palé wà nílùú Ciudad Trujillo, ó rí àwọn ará wa kan, ó bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì gba ìwé “Otitọ Yio Sọ Nyin Di Ominira.” Bó ṣe gbà kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójoojúmọ́ nìyẹn. Kò pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé àwọn míṣọ́nnárì yẹn lọ sóde ẹ̀rí, ó sì máa ń fi ọkọ̀ rẹ̀ gbé wọn. Nígbà tó yá, ó bá Lennart Johnson pàdé, àwọn méjèèjì sì jọ ti ìlú Ciudad Trujillo lọ sí ìlú Santiago. Wọ́n tún jọ gba orí àwọn òkè lọ sí ìlú Puerto Plata tó wà ní etíkun láti lọ wo àwọn olùfìfẹ́hàn kan tí wọ́n kọ̀wé sí oríléeṣẹ́ wa nílùú Brooklyn, New York pé àwọn fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Arákùnrin Knorr àti Franz Bẹ̀ Wá Wò

Ní oṣù March ọdún 1946, Arákùnrin Nathan Knorr àti Frederick Franz láti oríléeṣẹ́ wa ṣèbẹ̀wò sí Orílẹ̀-èdè Dominican. Ojú wa ti wà lọ́nà gan-an fún ìbẹ̀wò yẹn, èèyàn márùndínlọ́gọ́rin [75] tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ló sì dara pọ̀ mọ́ àwọn ará wa láti gbọ́ àsọyé Arákùnrin Knorr. Nígbà ìbẹ̀wò yẹn, Arákùnrin Knorr ṣètò bá a ṣe máa ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Orílẹ̀-èdè Dominican.

Arákùnrin Knorr àti Franz rèé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àkọ́kọ́ lórílẹ̀-èdè náà, nílùú Ciudad Trujillo

Ọ̀pọ̀ míṣọ́nnárì tún dé sí orílẹ̀-èdè náà, nígbà tí ọdún iṣẹ́ ìsìn 1946 sì máa fi parí, akéde méjìdínlọ́gbọ̀n [28] ló ti wà lórílẹ̀-èdè náà. Torí pé a ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere  níbẹ̀ ni, àwọn míṣọ́nnárì sábà máa ń jókòó nírọ̀lẹ́ láti fara balẹ̀ yàwòrán ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn kí wọ́n lè rí i dájú pé iṣẹ́ náà ń lọ létòlétò, kí wọ́n sì lè ṣe é kúnnákúnná.

Iṣẹ́ Ìwàásù Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Gbòòrò

Ní ọdún 1947, iye akéde tó ń wàásù lórílẹ̀-èdè náà ti lé ní mọ́kàndínlọ́gọ́ta [59]. Ọdún yẹn náà ni ètò Ọlọ́run rán àwọn míṣọ́nnárì kan tó ti sìn lórílẹ̀-èdè Cuba wá sí Orílẹ̀-èdè Dominican. Arákùnrin àti Arábìnrin Roy àti Juanita Brandt wà lára wọn. Wọ́n yan Arákùnrin Brandt sípò ìránṣẹ́ ẹ̀ka, ó sì ṣiṣẹ́ náà fún ọdún mẹ́wàá.

Nígbà tí ọdún iṣẹ́ ìsìn 1948 fi máa parí, nǹkan bí àádọ́fà [110] akéde ló ti dara pọ̀ mọ́ àwọn míṣọ́nnárì tó ń ṣiṣẹ́ kára yìí láti máa wàásù ìhìn rere. Àmọ́ àwọn ará tó ń fìtara wàásù yìí ò mọ̀ rárá pé nǹkan máa tó le koko bí ojú ẹja.

^ ìpínrọ̀ 1 Òótọ́ ni pé ọdún 1932 ni wọ́n ti pín ìwé wa fáwọn èèyàn ní Orílẹ̀-èdè Dominican, àmọ́ ìgbà tí Arákùnrin àti Arábìnrin Johnson dé lọ́dún 1945 ni iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó bẹ̀rẹ̀.